Israel àti Hamas ti fẹnukò ní ìpele àkọ́kọ́ láti dáwọ́ ògun dúró -Trump

Aarẹ ilẹ America; Donald Trump n sọrọ ninu aworan yii. Ẹrọ gbohun-gbohun kan wa niwaju rẹ. Trump wọ aṣọ dudu, o wọ itẹnu alawọ funfun sinu, o si fi tai alawọ pupa le e.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Aarẹ ilẹ America; Donald Trump
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Aarẹ orilẹede America, Donald Trump, ti kede pe ikọ ologun Israel ati Hamas to n koju ara wọn ti fẹnuko ni ipele akọkọ lati dawọ ogun duro, ati pe ija yoo dopin, ogun yoo si ṣẹ.

Ninu ọrọ kan ti Trump fi si oju opo ayelujara lo ti ni itumọ eyi ni pe gbogbo awon to wa nigbekun yoo gba itusilẹ, ikọ ologun Israeli yoo si ko awọn ologun rẹ lọ.

Trump sọ pe igbesẹ akọkọ ree lati ri i pe ija pari. "Gbogbo igun to kan ni yoo ri idajọ ododo gba"

Trump lo sọ bẹẹ.

Bakan naa ni ikọ Hamas naa ti fidi ẹ mulẹ, pe awọn ti tọwọ bọwe adehun lati ṣiwọ ogun ni Gaza, lẹyin ti awọn ṣagbeyẹwo awọn ohun ti Donald Trump la kalẹ lati pari ogun naa.

Hamas ṣalaye pe lara adehun naa ni pe awọn Israeli yoo kuro ni agbegbe naa, wọn yoo si tu awọn to wa nigbekun silẹ.

Lori ọrọ yii, Olootu ijọba ilẹ Israeli; Benjamin Netanyahu, sọ pe oun yoo lewaju ipade kan, nibi ti awọn yoo ti fẹnuko lorii bi wọn yoo ṣe da awọn to wa nigbekun silẹ.

"Ọjọ nla lọjọ oni fun Israel." Netanyahu lo sọ bẹẹ nigba to n dupẹ lọwọ Aarẹ Trump.

Aarẹ Donald Trump funra ẹ sọ pe ọjọ nla ni ọjọ adehun yii jẹ fun awọn Arab ati awọn orilẹede Islam. O ni bakan naa lo ri fun Israel, ati ilẹ America.

O dupẹ lọwọ Qatar, Egypt ati Turkey fun bi wọn ṣe da si ọrọ Hamas ati Israeli pẹlu awọn to ṣoju America.

Trump sọ pe o ṣee ṣe koun ṣabẹwo si ẹkun Middle East naa lopin ọsẹ yii, ni Egypt ti wọn ti n sọrọ naa.

Ọjọ kẹta ipade ajọsọ Israel ati Hamas naa da lori bi wọn yoo ṣe fi awọn ẹlẹwọn Palestine silẹ, ti wọn yoo fi gba awọn ti Hamas fi si igbekun.

Ẹ o ranti pe ọjọ keje, oṣu Kẹwaa ọdun 2023 ni ogun a n muni sigbekun yii bẹrẹ ni Gaza, o si ti pe ọdun meji bayii.

Ṣé ogun ọ̀hún yóò parí lóòótọ́?

Awọn ọmọde yii yika abọ kan ti ko jọ pe ounjẹ wa ninu rẹ ni Gaza, o jọ pe wọn kan n ṣere ni tiwọn ni

Oríṣun àwòrán, Anadolu via Getty Images

Àkọlé àwòrán, Awọn ọmọde yii yika abọ kan ti ko jọ pe ounjẹ wa ninu rẹ ni Gaza
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Adehun laaarin Israel ati Hamas yii waye lẹyin ifikunlukun ati ajọsọ to waye ni Egypt, o si jẹ ohun ti ọpọ eeyan ti n reti tipẹ lati pari ogun ọlọdun meji to n lọ ni Gaza.

Ṣugbọn pẹlu asọye naa, iwoye ọpọ eeyan ni pe ko si idaniloju pe ogun yoo pari.

Ohun kan to yatọ ninu ọrọ naa bayii ni pe Aarẹ Donald Trump funra rẹ da si i, o si ti pẹ to ti n sọ pe ki Hamas ati Israel jẹ ki ogun – o-mí.

Asẹyọri nla lo maa jẹ fun Trump to ti n wa ki wọn sọ pe oun loun pari ogun naa tẹlẹ.

Osẹ to kọja ni Trump kede igbesẹ alaafia akọkọ yii si etigbọ Benjamin Netayanhu, Olootu ilẹ Israeli, ẹni ti ẹnu n kun pe ko fẹ ki ogun naa wa sopin.

Ṣugbọn lọsẹ yii, a gbọ pe Trump ko fẹ idaduro kankan mọ lori ọrọ naa, ati pe bi Netanyahu ṣe fọwọ yẹpẹrẹ mu un ko tẹ Aarẹ America yii lọrun.

Eyi lo ṣe agbara America lati paṣẹ fun Israel, o loun yoo jẹ ibẹ run bi wọn ko ba jẹ ki ogun pari, ti ko si sohun ti Netanyahu le ṣe ju ko gba fun ọga rẹ lọ.

Awọn Hamas naa ko ri ọgbọn miran da, ilẹ Arab ati awọn orilẹede Musulumi lagbaaye naa gba ọrọ Trump wọle, Egypt, Qatar ati Turkey naa si da si ajọsọ yii pẹlu.

Igbesẹ yii ṣe pataki loootọ lati pari ogun, ṣugbọn ko si idaniloju pe alaafia yoo jọba ni Gaza, pẹlu awọn nnkan to ṣi yẹ lati mojuto.

Lara wọn ni ohun to Israeli n beere fun, pe Hamas gbọdọ tu ikọ ologun rẹ ka.

Nnkan miran ni pe bawo ni Israeli yoo ṣe jẹ ki wahala naa dopin, ati ta ni yoo dari Gaza.

Inu awọn eeyan Gaza to fẹẹ pada sile naa n dun looootọ, ṣugbọn ibanujẹ awọn ẹbi wọn to ti ku tun wa lapa kan to n ba ayọ wọn jẹ bi wọn ṣe wi.