Bánkì àpapọ̀ Nàìjíríà, CBN kéde ìlànà tuntun fáwọn olókòwò POS, wo àwọn ìlànà náà àti bó ṣe kàn ọ́

Owo naira aganran ati ẹrọ POS

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Àkọlé àwòrán, CBN tun sọ ninu ilana tuntun naa wi pe N100,00 ni onibaara kan le gba lojumọ, N500,000 lọsẹ ati apapọ owo ti onibaara le gba si jẹ N1.2m lọwọ olokowo POS kan.
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Banki apapọ orilẹede Naijiria, CBN, tun ti kede ilana tuntun fawọn olokowo POS wi pe banki kan ṣoṣo ni wọn yoo lanfaani si lati maa lo fi ṣiṣẹ wọn bayii.

Eyi yatọ si bi awọn olokowo POS ṣe ni oriṣiiriṣii ẹrọ POS awọn banki ori ayelujara bii Opay, PalmPay, Kuda ati bẹẹ bẹẹ lọwọ tẹlẹ, ti wọn si maa n lo gbogbo rẹ papọ.

Banki CBN ni igbesẹ yii wa lati dena awọn to n fi okowo POS lu araalu ni jibiti.

Gẹgẹ bi ajọ NIBSS to n ri si ibaṣepọ lawọn awọn ile ifowopamọ ni Naijiria ṣe ṣalaye, o le ni miliọnu mẹjọ ati ẹgbẹrun mẹrindinlogoji (8.36m) ẹrọ POS tawọn to fi n ṣowọ n lo ni Naijiria.

Ilana tuntun yii yoo bẹrẹ lọjọ kinni oṣu Kérin ọdun 2026 to n bọ.

Wọnyi ni koko to wa ninu ilana tuntun ti CBN kede fawọn olokowo POS:

  • Ni bayii, gbogbo owo ti onibaara ba fẹ gba tabi san fun olokowo POS gbọdọ wọ inu akaunti ẹni to n ṣe okowo POS, bi bẹẹ kọọ, ijọba le gbẹsẹ le akaunti olokowo POS to ba kọ lati ṣe bẹẹ.
  • CBN tun sọ ninu ilana tuntun naa wi pe N100,00 ni onibaara kan le gba lojumọ, N500,000 lọsẹ ati apapọ owo ti onibaara le gba si jẹ N1.2m lọwọ olokowo POS kan.
  • Iye yii kan naa tun ni onibaara kan le lo akaunti POS lati san owo sinu akaunti rẹ tabi akaunti mii to ba wu u.
  • Ẹnikẹni ti ọjọ ori rẹ ko ba to ọdun mejidinlogun ti o si jẹ gbese ẹyawo ti ko san, tabi to ni akọsilẹ iwa ọdaran ko le di olokowo POS mọ.
  • Ni bayii, olokowo POS gbọdọ ni ẹri to daju wi pe o forukọ ileeṣẹ rẹ silẹ pẹlu ijọba, o si n san owo ori ati pe o gbọdọ ni owo to to lati ṣowo.
  • Gbogbo owo ti olokowo POS ba n san fawọn onibaara tabi ti o ba n gba ni akọsilẹ ibi to ti n ṣe eleyii gbọdọ wa lori ẹrọ kọmputa.
  • Ni bayii, awọn olokowo POS gbọdọ maa lọ fun idanilẹkọọ lori mimọ ihuwasi awọn onibaara lati le dena jibiti lilu. Eleyii si pọn dandan fun gbogbo olokowo POS.
  • Olokowo POS gbọdọ fun onibaara ni risiiti owo ti wọn ba gba tabi san, orukọ onibaara, owo ti wọn ba tabi san ati nọmba foonu wọn si gbọdọ wa lori risiiti naa.
  • Awọn banki ori ayelujara gbọdọ ri pe wọn fi akọsilẹ gbogbo owo tawọn olokowo POS ba an fun onibaara tabi gba lọwọ wọn ati iye to ku ninu akaunti wọn ranṣẹ si ajọ NIBSS ki wọn si tun fi ẹda rẹ ranṣẹ si CBN.
  • Olokowo POS kankan ko gbọdọ fi ibi to ti n ṣiṣẹ silẹ lọ si ibomiran lai gbaṣẹ lọwọ banki to gbe ẹrọ POS fun un.
  • Olokowo POS to ba fẹ kuro nibi to wa lọ si ibomiran ti gbọdọ sọ fun banki rẹ ni bii oṣu kan sigba to fẹ kuro nibi to wa.
  • Ijiya fun ẹni to ba tapa si ilana tuntun yii bẹrẹ lati miliọnu meji naira (N2m) si ogun milíọnu (N20m).
  • CBN le da ẹni to ba n tapa si ilana tuntun yii ni gbogbo igba duro, tabi ki o gba iwe iforukọsilẹ rẹ gẹgẹ olokowo POS.