Wo ohun tí Ilé ẹjọ́ tó ga jù ní Nàìjíríà sọ nípa àsìkò àti bí ìdájọ́ lórí owó àwọn ìjọba ìbílẹ̀ nìpínlẹ̀ Osun yóò ṣe lọ

Oríṣun àwòrán, Others
Ile ẹjọ to ga ju lorilẹede Naijiria ni awọn yoo kede ọjọ ti wọn yoo gbe idajọ sita lori ẹjọ ti ijọba ipinlẹ Osun pe lati da agbẹjọro agba fun ijọba apapọ lọwọ duro lori sisan owo ijọba ibilẹ fun awọn alaga kansu ti wọn dibo yan labẹ asia ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC), ti ile ẹjọ giga si ti wọgile eto idibo to gbe wọn wọle.
Igbimọ onidajọ meje ti adajọ Uwani Aba'aji ni awọn ti tẹti si gbogbo atotonu agbẹjọro ijọba apapọ, Akin Olujimi (SAN) ati ti ipinlẹ Osun, Musbau Adetumbi (SAN).
Ni ọjọ Ẹti, ọjọ Kẹrindinlọgbọn, oṣu Kẹsan-an, ọdun 2025 ni ijọba ipinlẹ Osun gba ile ẹjọ lọ lẹyìn ti ìroyìn gbode pe ijọba apapọ ti san owo oṣu mẹfa awọn ibilẹ ẹyí tí wọn ti gbẹsẹ le lati inu oṣu Keji ọdun yii.
Nigba to n sọrọ fun ijọba ipinlẹ Osun, Adetumbi rọ ile ẹjọ pe ko tẹwọ gba ẹbẹ rẹ, to si gba ipe rẹ nitori eto idibo to gbe awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC wọle sipo Alaga ati Kanselọ ni ile ẹjọ giga ati ile ẹjọ kotẹmilọrun niluu Abuja lorilẹede Naijiria ti wọgile.
Nigba to n tako ẹbẹ Adetumbi, Olujimi ni ki ile ẹjọ wọgile ẹjọ ti ijọba ipinlẹ Osun gbe wa nitori ko fẹ mulẹ rara, nitori ẹjọ laaarin ẹgbẹ oṣelu meji ni.
Agbẹjọro agba naa nis aa awọn alaga ti wọn yọ kuro nipo si wa titi wọ ọjọ Kejilelogun oṣu Kẹwaa ọdun 2025 ati ohun to tọ lasiko yii ni pe ki wọn gba diẹ lara owo naa fi ma tukọ awọn ijọba ipinlẹ.
Kí ló dé tí ìjọba ìpínlẹ̀ Osun fi gba ilé ẹjọ́ lọ láti dènà fífún àwọn alága lówó?
Ifanfa to n waye laaarin ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC ati Peoples Democratic Party, PDP nipinlẹ Osun lorí ọrọ ijọba ibilẹ ti tun gba ọna mii yọ.
Eyi ko ṣẹyìn bi ẹgbẹ oṣẹlu PDP ṣe n fẹsin kan pe apo awọn aladani ni ijọba apapọ san owo oṣu mẹfa to jẹ owo awọn ijọba ibilẹ naa si.
Bo tilẹ jẹ pe ẹgbẹ oṣelu APC ni ipinlẹ Osun ti fìdí rẹ mulẹ pe loootọ ni ijọba apapọ ti san owo naa, wọn jiyan pe kii ṣe akoto owọ awọn alaga ìjọba ibilẹ ti wọ́n dìbo yan labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC ní ọdún 2022 ni ìjọba apapọ sanwo naa sí.
APC Osun ni apo akoto owo awọn ijọba ibilẹ ni ijọba apapọ san owo naa si.
Amọ, ẹgbẹ oṣelu PDP to jẹe ẹgbẹ to n ṣe ìjọba nipínlẹ Osun sọ pe awọn ko mọ nnkankan nípa owo naa, ti wọn si n sọ fun ẹgbẹ oṣelu APC lati kede akoto ti ijọba apapọ san owo ọhún si.
PDP ni o jẹ ohun iyalẹnu pe ijọba apapọ maa san owo sí akoto ti oluṣiro agba agba ìpínlẹ naa ati oluyẹwe owo wo fun ijọba ìbílẹ ati ileeṣẹ to n ri si ọrọ ijọba ibílẹ kọ mọ nnkankan nipa rẹ.















