‎ Àwọn afurasí agbénipa rọ̀jò ìbọn lé Ọ̀gá Amotekun lórí l'Osun, àmọ́, orí kó o yọ

Ọga Amotekun, Isaac Omoyele mu ẹrọ gbohun-gbohun lọwọ, o wọ aṣọ iṣẹ rẹ
Àkọlé àwòrán, ‎Isẹlẹ naa lo waye ni deede agogo mẹwaa kọja isẹju marun-un ni alẹ ọjọ Aje, lẹyin akoko diẹ ti Oloye Omoyele kuro ni ọfiisi rẹ to wa ni agbegbe Power line niluu Osogbo.
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ori ko ọga ẹsọ Amotekun nipinlẹ Osun, Oloye Adekunle isasc Omoyele, yọ lọwọ iku ojiji lẹyin tawọn afurasi agbenipa rọjo ibọn sori ọkọ rẹ lalẹ ọjọ Aje ọjọ kẹfa oṣu Kewaa yii.

‎Ninu atẹjade ti Idowu Yusuf to jẹ agbẹnusọ fun ẹṣọ Amọtẹkun ẹka ti ipinlẹ Osun fi lede lo ti fi idi isẹlẹ yii mulẹ.

‎Isẹlẹ naa lo waye ni deede agogo mẹwaa kọja isẹju marun-un ni alẹ ọjọ Aje, lẹyin akoko diẹ ti Oloye Omoyele kuro ni ọfiisi rẹ to wa ni agbegbe Power line niluu Osogbo.

Gege bi ọkan lara iṣọmọgbe ọga Amọtẹkun naa se sọ nigba to wa ni Ile iwosan, isẹlẹ ọhun waye ni oju opopona Osogbo si ilu Ikirun nipinlẹ lagbegbe Kọbọ lẹgbẹ Ile itura charity, nigba ti o n wa ọkọ rẹ lọsi Ile.

‎Agbẹnusọ Amotekun sọ pe Oloye Omoyele ni saa deede ni awọn ọkọ kan dabu oun lọna ti wọn si bẹrẹ sii yin ibọn lakọlakọ si ara ọkọ oun.

O ni gbogbo awọn to n yinbọn ọhun ni wọn fi aṣọ boju wọn.

Ọgbẹni Yusuf fikun ọrọ rẹ pe pẹlu gbogbo bi wọn ṣe n yinbọn naa, oun si sa gbogbo ipa oun lati maa wa ọkọ lọ sugbọn ibọn ba oun ti oun si gbiyanju ati na papa bora.

‎Ohun to ya ni lẹnu ni pe awọn agbenipa ọhun tun lọ si ile ọga Amọtẹkun naa.

Gẹgẹ bi ẹnikan to jẹri si isẹlẹ naa ṣe sọ, awọn agbebọn mẹẹdogun miran lo tun lọ sile Oloye Omoyele pẹlu ọkọ Hilux ati ọkọ Toyota Highlander ti wọn si tun boju wọn.

‎Yusuf ni ọrọ naa ti de ọdọ awọn ọlọọpa, ti iwadi si ti n lọ lọwọ lori isẹlẹ naa.

Amọ, titi di akoko yi wọn ko ti mọ awọn to se ikọlu naa.

Ọlọpaa ti bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ naa

Agbẹnusọ Amotekun ni ''o jẹ ohun to bani lọkan jẹ pupọ pe iru isẹlẹ bayi le sẹlẹ si ọga Amọtẹkun ni ipinlẹ Osun.

Eyi kii se ikọlu lasan si eeyan kan, bi ko ṣe si gbogbo ẹsọ alaabo.''

‎Yusuf wa rọ gbogbo awọn olugbe ipinlẹ Osun lati wa ni oju lalakan n fi ṣọri ki wọn si ri daju pe awọn fi to awọn ọlọọpa leti ti wọn ba ri ohun ajoji kan.

‎Ni ọsẹ to kọja ni awọn agbebọn kan kọja ija si ẹṣọ Amọtẹkun ẹka ti ipinlẹ Osun ni ilu kan ti wọn n pe ni Akinlalu ni ijọba ibilẹ iwọ-orun ilu Ife ti eeyan mẹrin ti ọmọ iya meji si wa nibẹ si ku lasiko tawọn agbebọn naa fija pẹta pẹlu awọn ẹṣọ Amotekun.

‎BBC news Yoruba kan si ileesẹ ọlọọpa ipinlẹ Osun lori ikọlu ọga awọn Amọtẹkun.

‎Agbẹnusọ fun awọn ọlọọpa ipinlẹ ọṣun Abiodun Ojẹlabi sọ pe, awọn ti gbọ si isẹlẹ naa, ṣugbọn iwadii n lọ lọwọ lori rẹ.