Ààrẹ Tinubu pàṣẹ kí àjọ alálàájì wá ọ̀nà láti dín owó Hajj ọdún 2026 kù láàrin ọjọ́ méjì

Aworan ilẹ Mimọ

Oríṣun àwòrán, AFP via Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Aarẹ Bola Tinubu ti paṣẹ pe ki ajọ alalaaji lorilẹede Naijiria, NAHCOM tun owo irinajo lọ si ilẹ mimọ Hajji gbe yẹwo ni kiakia.

Aarẹ fi aṣẹ yii ransẹ si alalaaji lorilẹede Naijiria, NAHCON pe ki wọn gbe igbesẹ lori ọwọ irinajo tuntun laaarin ọjọ meji.

Igbakeji aarẹ, Kashim Shettima, kede ọrọ yii pẹlu aṣẹ aarẹ Bola Tinubu lasiko to n ṣe ipade pẹlu awọn aṣoju ajọ NAHCON ni ile aarẹ niluu Abuja.

O pe fun irẹpọ laarin awọn olori ajọ naa ni ni ẹka kọọkan, to fi mọ ajọsepọ nla pẹlu awọn Gomina lati le forikun lori iye owo ọkọ lọ si ilu Mecca.

Nigba to n dahun ibeere awọn akọroyin lẹyin ipade pẹlu igbakeji aare, Sẹnetọ Ibrahim Hadeijia ni ipade ti wọn ṣe lo waye ni igbaradi fun irinajo Hajj ti ọdun 2026, paapa lati sọrọ lori iye owo ti yoo na ẹnikẹni to ba fẹ lọ si orilẹeede Saudi Arabia fun iṣẹ Hajj.

O ṣalaye pe erongba wọn ni din iye owo Hajj ku si iye ti ko ni mu inira ba awọn eeyan to ba fẹ lọ nitori bii kudiẹkudiẹ se bao wo naira lọwọ yii ni ọja agbaye.

He said, "Owo naira ti n gberi diẹdiẹ latari atunṣe ijọba to wa lode yii, igbakeji aarẹ ni ti awọn arin irinajo ba san ₦8.5 million si ₦8.6 million lọdun yii, o yẹ ki adinku ba pẹlu bii owo naira se tun ti gbe pẹli n ọja agbaye."

Nigba to n sọrọ, akọwe agba fun ajọ NAHCON, Dr. Mustapha Mohammad ni igbesẹ aarẹ yoo mu ki alekun ba awọn eeyan fẹ lọ si Hajj fun ọdun to n bọ.

"Aṣeyọri nla ni eyi pe ki a mu adikun ba iye owo Hajj lati mu aye rọrun fun awọn Musulumi lati ṣe Hajj.

"Gẹgẹ bii igbakeji aarẹ ṣe palaṣẹ, a o bẹrẹ iṣẹ ni kiakia laarin oni ati ọla lati mọ bi a se ma din owo naa ku si eyi ti ko ni mu inira ba araalu, ti gbogbo Musulumi yoo si ni anfani lati le san owo naa lati ọkan ninu opo marun un ẹṣin Islam."

.