'Ìlú tó ti tú lágbègbè tí a wà ní ìpínlẹ̀ Kwara yìí tí lé ní 23, a pé ìjọba, wọn ò dá wa lóhùn'
Awọn eeyan ilu Gbẹdẹ ni ipinlẹ Kwara ti ke gbajara si ijọba lorigbọnmọgbọnmọ ijinigbe ati ikọlu awọn agbebọn lagbegbe naa eyi ti wọn sọ pe o ti tu ọpọlọpọ ilu lagbegbe ọhun.
Nigba ti a pe ijọba, ijọba kuna lati da wa lohun lo mu ki a gbe igbesẹ funra wa, eyi lo si mu ki awọn eeyan di alaisi lọsan gangan.
Laipẹ yii ni okiki iroyin kan kaakiri nipa bi awọn agbebọn ajinigbe ṣe n ṣọṣẹ lawọn agbegbe kan ni ipinlẹ Kwara, lẹkun aringbungbun ariwa orilẹede Naijiria.
Bi wọn ṣe n ji awọn eeyan gbe, ti wọn n jẹ ilu run lagbegbe ti mu ki awọn olugbe agbegbe naa maa ko ẹru wọn sa kuro nibẹ fun ẹmi wọn.
A ko gbọ pin nipa oun ti wọn n sọ - ileeṣẹ ọlọpaa
Nigba ti BBC kan si alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Kwara, o ṣalaye pe awọn ko tii gbọ pin lori awọn ifisun tawọn eeyan agbegbe naa n sọ.
Amọṣa o rọ wọn lati fọkan balẹ nitori pe awọn ileeṣẹ ọlọpaa ati ologun ti wa nikalẹ fun abo lawọn agbegbe ti wahala agbebọn ati ijinigbe ti n gogo nibẹ.



