Olóòtú ìjọba France fipò sílẹ̀ lẹ̀yín ọjọ́ mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n péré tó dórí ipò

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Sébastien Lecornu, Olootu ijọba ilẹ France, ti fi ipo naa silẹ lẹyin ọjọ mẹrindinlọgbọn (26) to debẹ.
Ọjọ Aje oni, ọjọ kẹfa, oṣu Kẹwaa ọdun 2025 ni Lecornu fi ipo rẹ silẹ pẹlu alaye pe nnkan ko rọgbọ nipo naa.
O ni awọn ẹgbẹ oṣelu to yẹ ko jẹ alabaṣepọ oun ko ṣetan lati fẹnuko pẹlu oun.
Ikede ifipo silẹ naa lo waye lati aafin Elysée, kete ti olootu ijọba tẹlẹ naa ṣepade pẹlu Aarẹ Emmanuel Macron, laaarọ ọjọ Aje.
Ẹ o ranti pe François Bayrou lo kuro nipo yii ti wọn fi yan Lecornu .
Ṣugbọn awọn ọmọ ile igbimọ ati ẹgbẹ oṣelu wọn ko yee koro oju si ijọba Lecornu ati awọn to ko mọra.
Ehonu awọn igbimọ naa ni pe ikọ to ba Bayrou ṣiṣẹ ni Lecornu naa tun n lo, wọn si bẹrẹ si i halẹ pe awọn yoo fi ibo le e jade.
Bakan naa ni ọpọ ẹgbẹ oṣelu n pe fun idibo lati waye kia, awọn kan si n sọ pe Aarẹ Macron gan-an lo gbọdọ fi ipo silẹ.
Bo tilẹ jẹ pe Macron ti sọ lọpọ igba pe oun ko ni i kuro nipo bi saa oun ko ba ti i pe, iyẹn si di 2027.
" Ohun kan to ku fun un lati fi ọgbọn ṣe bayii naa ni lati ṣeto ibo kia, o ti su awọn eeyan ilẹ Faranse. Macron ti fi ilu yii si aaye to nira gan-an. "
Marine Le Pen ti ẹgbẹ National Rally (RN) lo sọ bẹẹ.
Bi iṣakoso yoo ṣe tẹsiwaju lasiko yii wa lọwọ Aarẹ Macro. Ninu ko yan olootu ijọba miran, tabi ko tu ile igbimọ apapọ ka, tabi ki oun funra rẹ kọwe fipo silẹ.
Ohun to foju han ni pe Macron ko ni i fẹẹ fipo silẹ, ṣugbọn idaamu to wa fun un bayii ni pe ta ni yoo yan lati ba a ṣejọba?
Lecornu to tun fipo yii silẹ naa lo gbọkan le tẹlẹ, ki iyẹn naa too kuro nipo lai lo oṣu kan.
Kí ló ń ṣẹlẹ̀ ní France?
Lecornu to fipo silẹ yii ni olootu ijọba karun-un ti wọn yan ni France lai ti i pe ọdun meji.
Eto oṣelu France ti n koju iṣoro lati oṣu Keje ọdun 2024, nigba ti Macron pe fun idibo ile igbimọ lẹyẹ-o-sọka, lati le ko awọn ọmọ ẹgbẹ to padanu jọ pada ninu ibo ile igbimọ Europe.
Ṣugbọn odikeji ero ọkan rẹ ni idibo naa mu wa, niṣe lo pin awọn eeyan naa si igun ọtọọtọ, ede wọn ko si ye ara wọn mọ.
Eyi lo jẹ ko maa ṣoro fun awọn olootu ijọba rẹ lati duro nipo, nitori ko si ọmọ igbimọ to pọ to, ti won yoo fi le da aba, tabi sọ aba di ofin.
Oṣu Kẹsan-an ọdun to kọja ni wọn yan Michel Barnier sipo olootu ijọba naa, ṣugbọn ko lo oṣu mẹta ti wọn fi yọ ọ nipo.
Bakan naa lo ri fun François Bayrou to gba ipo naa lẹyin rẹ, oṣu mẹsan-an loun naa lo ti wọn fi le e danu.
Eyi waye lẹyin ti awọn igbimọ kọ lati ṣatilẹyin fun eto iṣuna to gbe kalẹ, to ti ni oun yoo ge owo ti ijọba n na ku pẹlu €44bn ($51bn; £38bn).
Ni 2024, owo to yẹ ki France naa lori eto rẹ din pẹlu 5.8%, wọn si jẹ gbese114% .
Gbese yii ni wọn lo wa nipo kẹta lẹyin Greece ati Italy.
Lọjọ Aje ti Lecornu fiṣẹ silẹ yii, ipin idokowo ja walẹ gidi ni Paris lẹyin ikede ifiṣẹsilẹ naa.














