''Ìdí tí a fi ń bẹ ìjọba láti gbà wá láyè kí á máa gbé ìbọn fún ra wa"

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ikọlu awọn agbebọn, ajinigbe ati apanilẹkun jaye gbogbo to n waye lemọ lẹmọ nipinlẹ Sokoto ti mu ki awọn eeyan ijọba ibilẹ Kebbe, sọ fun ijọba Naijiria bayii, pe ki wọn jẹ ki awọn maa lo ibọn lati da aabo bo ara awọn.
Awọn eeyan naa sọ pe bi awọn agbebọn ṣe n fi gbogbo igba kọlu awọn, pa eeyan, ti wọn yoo tun gbe awọn mi-in sa lọ ti to gẹẹ.
Wọn ni ninu ilu mẹtadinlogun (17) to wa nijọba ibilẹ Kebbe, mọkanla (11) ninu wọn ni awon eeyan ibẹ ti sa kuro, latari ikọlu gbogbo igba awọn agbebọn.
Ọkan lara awọn olori agbegbe naa, Tukur Muhammad Fakum, ṣalaye fun BBC pe ina ti jo dorii koko bayii, ibọn lo ku tawọn n beere aṣẹ rẹ lọwọ ijọba.
"Kí ìjọba dá ààbò bò wá, bí wọn kò bá lè ṣe bẹ́ẹ̀, kí wọ́n jẹ́ ká kó ìbọn fún àwọn ọ̀dọ́ ìlú wa láti da ààbò bò wa''
Ninu ọrọ Fakum, o ni "awa ree bayii, o ti doju ẹ. Ẹni to ba ni ile kekere, ko baa si jẹ oko kekere naa ni, ẹ jẹ ka ta a, ka fi owo rẹ ra ibọn.
"Bi a ba ra ibọn tan, a maa da a jọ fun awọn ọdọ ilu lati fi koju wọn bi wọn ba tun de.
"Ki ijọba da aabo bo wa la beere, bi wọn ko ba si le ṣe bẹẹ, ki wọn jẹ ka ra ibọn funra wa."
Nigba to n ṣalaye ipa buruku ti ikọlu awọn agbebọn naa n ni lori awọn ilu wọnyi, Fakum sọ pe:
"Ko si ounjẹ, onile-ọlọna ko rile sun mọ, ẹni ti ko sun sinu mọṣalaṣi ri di ẹni to n sun sibẹ, kaluku di alarinkiri ki wọn too le ribi sun sin. Iṣẹlẹ to buru gbaa ni."
Ọrọ aje paapaa ti dẹnukọlẹ tan bi ọkunrin naa ṣe ṣalaye, o ni ko si karakata irọrun mọ rara.
Igbiyanju BBC lati ba ijọba ipinlẹ Sokoto sọrọ lori idaamu yii ko kẹsẹjari.
Ipinlẹ Sokoto jẹ ọkan lara awọn ibi ti ọkan wọn ko ti balẹ rara lapa Oke Ọya.
Awọn agbegbe bii Isa, Sabon Birni ati Kebbe yii lo si n fi ara ko idaamu naa ju.
Yatọ si ikọ agbesunmọmi to n tẹle ọkunrin kan, Bello Turji, awọn ikọ apaniyan kan tun wa ti a mọ si Lakurawa, ti wọn n ṣoro gan-an nipinlẹ Sokoto.
Ikọ Lakurawa yii ni awọn awoye sọ pe wọn le pada buru jai lapa Ariwa-Iwọ-Oorun .
Ni ipinlẹ Kebbi, eyi to paala pẹlu Sokoto, awọn agbebọn kan kọlu awọn ologun Naijiria ni ilu Dirin Daji, eyi to wa ni ijọba ibilẹ Sakaba.
Araalu naa kan ṣalaye ikọlu naa pe:
"Wọn lọ sibi ipagọ awọn ọlọpaa ati ṣọja, wọn yinbọn pa ẹṣọ to wa loju ọna, ẹsẹkẹsẹ ni ẹṣọ naa ku."
Iṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ tan ki wọn too fi awọn ẹṣọ alaabo ranṣẹ sibẹ, wọn si gbe oku naa lọ."














