Ìdí tí mo tún ṣe fẹ́ dupò Gómìnà ìpínlẹ̀ Osun rèé - Omisore

Sẹnẹtọ Iyiola Omisore n sọrọ pẹlu ẹrọ gbohun-gbohun lọwọ rẹ

Oríṣun àwòrán, Dr Iyiola Omisore/X

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Agba ninu ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, Sẹnetọ Iyiola Omisore, ti kede erongba rẹ lati dupo gomina ipinlẹ Osun ni odun 2026 labẹ asia ẹgbẹ oṣelu naa.

Omisore, ẹni to fi gba kan jẹ igbakeji gomina, kede eyi loju opo X rẹ lọjọ Ṣatide, to si ni oun yoo jẹ ki ikede oun di mimọ ni ọfiisi ẹgbẹ oṣelu APC lọjọ Isẹgun, ọjọ Keje, oṣu kẹwaa ọdun 2025.

Omisore sọ loju opo X rẹ pe "ẹyin eeyan mi nipinlẹ Osun, lẹyin ọpọ ijiroro ati ifọrọwanilẹnu wo, mo ti pinnu lati kede erongba mi lati jade dupo Gomina ipinlẹ Osun ni ọdun 2025 labẹ asia ẹgbẹ oṣelu wa, APC.''

O fikun ọrọ rẹ pe ipolongo ibo oun yoo da lori dida ireti awọn eeyan pada, mimu atunṣe ba iṣejọba ati pipese ọjọ ọla rere fun awọn eeyan nipinlẹ naa.

Omisore ni ''ẹyi ki n ṣe iṣẹ mi nikan, ajọsepọ wa ni, mo n pe iyin pe ki ẹ wa fọwo sowọ pọ pẹlu mi lati gbe ipinlẹ Osun siwaju.''

Nnkan to yẹ ki o mọ nipa Omisore to fẹ dupọ gomina Osun

Omisore dupo gomina ni ọdun 2014 labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP ko to di pe o darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu APC.

Igbagbọ wa pe o wa lara awọn oludije to ṣee ṣe ki wọn gba tikẹẹti lati soju ẹgbẹ APC ninu eto idibo to n bọ.

Omisore, jẹ igbakeji gomina laaarin ọdun 1999 si 2003 labẹ ẹgbẹ oṣelu Alliance for Democracy (AD), to si tun di sẹnetọ to soju ipinlẹ Osun laaarin 2003 si 2011.

Sẹnẹtọ Omisore fidirẹmi ninu ibo gomina lọdun 2014, nigba ti Rauf Aregbesola wọle eto idibo naa.

Bakan naa lo tun ti wa ninu ẹgbẹ oṣelu Social Democratic Party (SDP) nigba kan ri.

Omisore tun dupo gomina lọdun 2018, ko to di pe o darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu APC ni ọdun 2021.

Lara awọn ipo ti Omisore ti dimu ri ipo akọwe agba ẹgbẹ oṣelu APC.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post