'Lóòótọ́ mi ò ní ọwọ́, ẹsẹ̀ ni mo fi ń kọ ìwé nítorí àti mú àlá rere mi láti di olùkọ́ ṣẹ'

Àkọlé fídíò, 'Lóòótọ́ mi ò ní ọwọ́, ẹsẹ̀ ni mo fi ń kọ ìwé nítorí àti mú àlá rere mi láti di olùkọ́ ṣẹ'
'Lóòótọ́ mi ò ní ọwọ́, ẹsẹ̀ ni mo fi ń kọ ìwé nítorí àti mú àlá rere mi láti di olùkọ́ ṣẹ'

Gulshan Lohar ko ni ọwọ nigba ti wọn bii nitori awọn aiṣedede to waye lasiko iloyun rẹ.

Pẹlu iranlọwọ awọn obi ati ẹbi rẹ, o wa ọna lati mọ iwe kikọ ati lati mu ala rẹ lati di olukọ imọ iṣiro ṣẹ.

Bayii, Gushan Lohar ti wa di iwuri ati koriya fun awọn akẹkọọ atawọn olukọmiran ni agbegbe rẹ.

Nigba ti wọn bii tan ti awọn obi rẹ rii pe ko lọwọ ni wọn wa n gbero pe ta ni yoo tọju rẹ pẹlu ipenija rẹ yii.

Lẹyin-o-rẹyin iya rẹ kọ ọ bi a ti n fa ila nipa fifi ika ẹsẹ rẹ di ẹfun ikọwe mu; oun pẹlu bẹrẹ si nii kọwe nipa didi ohun elo ikọwe mu dipo ẹfun ikọwe ṣọọki mu.

O ni inu oun dun pupọ pe oun di iwuri fun awọn ọmọde atawọn to yi oun ka.