Teachers retirement age and years of service: Ìrírí àwọn àgbà olùkọ́ ṣì wúlò fún àwa ọ̀dọ́
Ewo ni ẹyin fi ara mọ lọdọ ti yin?
Ijọba Orilẹ-ede Naijiria lo kede pe won fi kun ọdun ti awọn olukọ yoo fi maa lo lẹni iṣẹ lati ọdun marundinlogoji si ogoji ọdun.

Bakan naa ni wọn fi kun iye ọdun ti won yoo lo lati maa ṣiṣẹ lati ọgọta ọdun sí ọdun marundinlaadọrin.
Ijọba ni eyi yoo jẹ ki wọn ṣi ni oore ọfẹ lati fi imọ kun imọ fun awọn akẹkọọ.
Ero àwọn ọmọ Naijiria ṣọtọọtọ lori ipinnu ijọba lati fi kun ọdun ọjọ ori ifẹyinti awọn Olukọ lati 60 si 65 ati ọdun iṣẹ wọn lati 35 si 40.

Bi awọn kan ṣe n sọ pe iriri awọn agba ọjẹ Olukọ yii wulo fun awọn ọdọ to ṣẹṣẹ n gba iṣẹ bẹẹ naa ni awọn miran n sọ pe bẹẹkọ.
- Ìpínlẹ̀ Èkìtì ṣetán láti gbà àlejò ìwọ́de ìlànà Ọmọ Odua
- Ìjọba Buhari ti gbẹ́rù tó kọjá orí, bàtá tó bá ń ró lákọ fẹ́ ya ni!- Tunde Bakare
- À ń ṣe ara wa ni Bí a bá kọ̀ láti máa lo egbòogi igbó ní Naijiria - Akeredolu
- Wo ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa bí 'twitter' tíjọba dá dúró ní Nàijíríà yóò ṣe kan ọ
- Makinde ṣàfikún owó oṣù àwọn àgùnbánirọ̀ ìpinlẹ Ọyọ láti ẹgbẹ̀rún márùn ún sí ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀dógún náírà
- Wo ìdí tí àgbẹ̀ kan, Muhammad fi da májèlé sínú kànga mẹ́sàn án tí àwọn èèyàn ń mu

Awọn miran ni o yẹ ki awọn agba maa lọ ki wọn si maa fi aaye silẹ fun awọn ọdọ lati ri iṣẹ ṣe lasiko yii.
Opọ ni erongba ijọba dara nitori pe awọn olukọ yii ṣi ni okun ati agbara lati fi ṣiṣẹ sii ju ki wọn kan maa joko sile lọ.

Awọn miran ni pe Ohun to ṣe pataki julọ ni pe ki ijọba fun wọn ni owo oṣu lasiko ki wọn si san awọn ajẹmọnu Olukọ nigab ti o yẹ ki wọn ma baa banujẹ lọjọ alẹ.



