Ọba alayé, olorì àti ọmọ wọn tí wọ́n ní wọ́n lù, já sí ìhòhò l'Ondo, ohun tí a mọ̀ rèé

Oríṣun àwòrán, Dayo Afolabi
Lọjọ Ẹti, ọjọ kẹta oṣu Kẹwaa ọdun 2025 yii ni ariwo sọ niluu Idogun, ijọba ibilẹ Ose, nipinlẹ Ondo, pe awọn ọdọ ilu kan lu Kabiyesi ibẹ, iyawo ati ọmọ rẹ, koda, wọn ni wọn ja won si ihooho ọmọluabi.
Nibi ọdun Ijẹṣu ti Kabiyesi, Oba Ekundayo Olorunninbe Bakare, gbe kalẹ ni iroyin sọ pe rogbodiyan naa ti bẹ silẹ, ti wọn lu Kabiyesi, olori ati ọmọ wọn ti wọn pe orukọ ẹ ni Victor.
Bo tilẹ jẹ pe ẹru n ba awọn araalu kan lati ṣalaye ohun to ṣẹlẹ ti ogidi iya fi tọ si Oriade ati idile rẹ, BBC News Yoruba ba o ṣoju mi koro kan sọrọ, pẹlu Kabiyesi funra ẹ ati Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Ondo.
Kí ló ṣẹlẹ̀ gan-an?
Gẹgẹ bi alaye ti obinrin kan, Agbede Bosede Juliet to jẹ ọmọ ilu Idogun to si ṣọju awọn ọdọ ibẹ ṣe fun BBC News Yoruba lori ikọlu naa, o ni:
"Lati ibẹrẹ pẹpẹ ni araalu Idogun ko ti nifẹ si Ọba Ekundayo lati gun ori itẹ, idi si ni pe oun kọ ni ipo naa tọ si, awọn iwa janduku to dẹ n hu naa ko jẹ ki awọn eeyan fẹran ẹ.
"Orò ọba to yẹ ko ṣe, o kọ lati ṣe e, wọn ni to ba ṣe e, ọrun maa wọ ọ, nigba ti ko dẹ ti ṣe oro yẹn lo ṣe n huwa janduku niluu.
"O ti ta gbogbo ilẹ agbegbe wa tan fun awọn Oka, Ibira ati Tiv. Ko si idagbasoke tabi ilọsiwaju kankan niluu wa.
"Awọn nnkan yii lo jẹ ki araalu maa sọrọ, wọn ni ko kuro lagbegbe yii, ko maa lọ si Aafin to wa ni Ugbe. Ṣugbọn ko le lọ nigba ti ko ṣe oro ọba to yẹ ko ṣe.
"Iṣẹlẹ to ṣẹlẹ yii naa, ko si araalu kankan to lu u tabi ja a sihoho. Ọmọ ẹ, Victor Olorunninbe, lo pade ọmọbinrin kan to si ba a ja.
"O ja ọmọbinrin yẹn sihooho, iyẹn naa dẹ ja si ihooho pada.
"Ohun to ṣẹlẹ niyẹn, ko sẹni to lu Kabiyesi tabi olori rẹ. Awọn ni wọn tun lọ ko ọlọpaa wa, ti kaluku fi sa wọle lalẹ naa.
"Ọdun Ijẹṣu to loun n ṣe yii gan-an, a ti ṣe ọdun tiwa ko too maa da tiẹ ṣe.
"Nibi to buru de, asiko kan wa ti awọn bọisi ẹ to maa n ran niṣẹ sọ pe ọmọbinrin kan, Ranti, ra ẹja to yẹ ki Olorì ọba ra lọja.
Wọn ni ko lọọ gbe ikoko ọbẹ ẹ wa, wọn dẹ da ọbẹ yẹn nu.
"Eyi to ṣẹṣẹ ṣẹlẹ yii naa, awọn bọis Ekundayo wọ aarin ọja, wọn n ju igo, won gbe ada dani ati ibọn, wọn ri i pe wọn tu ọja yẹn.
" Awọn obinrin lo n dẹ n naja, ṣugbọn o ya wa lẹnu pe niṣe ni awọn ọlọpaa tun n gbe lẹyin awọn janduku ọmọ ẹyin Ekundayo.
"Ẹyin wọn bayii ni awọn ọlọpaa duro si, wọn si bẹrẹ si i yin tajutaju sinu ọja.
"Awọn bọisi to maa n lo ni Rotimi Balogun, oun lo gbe aake dani, Lekan Ojuru, (ghost), Abudu, Emeka ati Iku-n- ba ọmọ-rin. Gbogbo wọn ni wọn gbe nnkan ija jade lọjọ ija yii.
Wọn ba ṣọọbu ọmọbinrin kan to n ṣe telọ jẹ, wọn tun ba ọkada ẹni kan to n sanwo ẹ diẹdiẹ (Instalment) jẹ.
O ti su wa o, ẹ gba wa niluu Idogun o, to ba jẹ pe o fẹ ko gbogbo wa lẹru ni ko jẹ ka mọ o."
Bẹẹ ni aṣoju ọdọ Idogun ṣalaye.
Àlàyé Kabiyesi Ekundayo
Nigba ti BBC News Yoruba pe Kabiyesi Ekudayo Olorunninbe lori foonu nipa iṣẹlẹ yii, ọba naa sọ pe ibi ti oun ti n gba itọju lorii lilu ti wọn lu oun loun wa.
"Mi o le ṣe alai gbe ipe yin lo jẹ ki n gbe e, mi o ro pe mo le sọ ohunkohun bayii, ibi ti wọn ti n tọju mi ni mo wa.
"Wọn ṣe mi leṣe gan-an pẹlu ọmọ mi, ko si bi mo ṣe le ba yin sọrọ bayii.
" Ti ẹ ba fẹ, mo le fi awọn aworan ranṣẹ si yin, kẹ ẹ ri nnkan ti mo n sọ''
Bẹẹ ni Kabiyesi naa wi.
Ṣugbọn titi ti a fi pari akojọpọ iroyin yii, ọba naa ko ti i fi fọto kankan ranṣẹ si wa.
Lóòótọ́ ni wọ́n lu ọmọ Kábíyèsí, ṣùgbọ́n mi ò mọ̀ nípa pé wọ́n já ọba sí ìhòhò-Alukoro ọlọpaa Ondo
Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Ondo, DSP Olayinka Ayanlade, ṣalaye pe awọn kan kọlu Victor, ọmọ ọba Ekundato loootọ lọjọ Ẹti naa.
O ni ṣugbọn oun ko mọ ibi ti iroyin to ni wọn ja ọba ati iyawo rẹ si ihoho ti wa.
"Iwadii ọlọpaa lori iṣẹlẹ yii, da lori awọn to lu ọmọ ọba ati ohun to fa rogbodiyan.
"Ẹnikẹni to ba n sọ pe ọlọpaa n gbe lẹyin ọba naa ko ni ifẹ ilu yẹn lọkan rara.
"Loootọ ni pe awọn kan kọlu ọmọ ọba, ti ọlọpaa ko si gba ki wọn fi ofin si ọwọ ara wọn, ṣugbọn ti pe wọn ja ọba sihooho yẹn, emi o mọ ibi to ti wa.
"Ọrọ ilu yii ti wa nilẹ tipẹ, ko ṣẹṣẹ maa ṣẹlẹ. Tẹ ẹ ba ranti, ni nnkan bii oṣu Keji ọdun ni ọkunrin kan jade, to n pe ara ẹ ni ọba ibẹ.
"Ọlọpaa gbe e nigba naa, o si de kootu, wọn ti i mọle. Kaluku araalu yii lo ni igun ti wọn n ṣe atilẹyin fun.
"Ṣugbọn ọlọpaa ko ni i gba ki wọn fi jagidijagan yanju ọrọ, bi yoo ṣe yanju lọna ofin la n mojuto.''
Lakootan, iwadi ṣi n tẹsiwaju lori iṣẹlẹ yii, gẹgẹ bi DSP Ayanlade, Alukoro ọlọpaa Ondo ṣe sọ.














