Gani Adams, Aláàfin Oyo, Afẹnifẹre korò ojú sí ìpànìyàn ní Kwara, dábàá ààbò fún ilẹ̀ Yorùbá

Aworan yii ṣafihan Iba Gani Adams,Aarẹ Ọna Kakanfo ilẹ Yoruba ati Alaafin Oyo, Oba Abimbola Owoade. Awọn mejeeji wọ aṣọ funfun, wọn de fila. Iba n fi ẹrọ gbohun-gbohun sọrọ.

Oríṣun àwòrán, Oodua Graphics/BBC

Àkọlé àwòrán, Iba Gani Adams ti i ṣe Aarẹ Ọna Kakanfo ilẹ Yoruba lapa osi, Alaafin Oyo, Oba Abimbola Owoade lapa ọtun
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Bi ikọlu awọn agbebọn ṣe gbilẹ lawọn apa kan nipinlẹ Kwara lẹnu ọjọ mẹta yii, Aarẹ Ọna Kakanfo Ilẹ Yoruba, Iba Gani Adams, Aláàfin Owoade ati ẹgbẹ Afẹnifẹre naa ti sọrọ nipa rẹ.

Ninu ọrọ ti Iba Gani Adams sọ l'Ọjọbọ lo ti ni eto aabo to nipọn gidi lo yẹ fun ilẹ Yoruba lapapọ bayii, ati ipinlẹ Kogi naa.

O ṣapejuwe ipaniyan ọhun bii iku to n pa ojugba ẹni, to jẹ owe lo n pa fun ni.

Gani Adams so pe bi eto aabo ba fẹsẹ mulẹ si i nikan ni ikọlu lẹmọlẹmọ yii le mọwọ duro ni Kwara ati gbogbo ilẹ Naijiria.

Bẹẹ lo fi kun un pe iṣẹlẹ to waye kẹyin l'Oke-Ode, ipinlẹ Kwara, ba ni lọkan jẹ pupọ.

Olori ogun ilẹ Yoruba naa sọ pe o ti le lọdun kan toun ti n ke tantan lori eto aabo ti ko duro deede.

O ka awọn agbegbe bii Babanla, Bororo, Osi, Oro nipinlẹ Kwara bii awọn ibi ti ọpọ ẹmi ti sọnu.

Iba darukọ Ejiba, Egbe, Okoloke, Okunran, Odo-Ape ati Ole-bunu bii ibi ti awọn agbebọn ti ṣọṣẹ ni Kogi.

Iba Gani Adams rọ gbogbo ọmọ Yoruba lati maa foju ṣọri, ki wọn si mọ pe ohun to delẹ yii ki i ṣe iṣẹ ẹnikan, ajọṣe ni.

Aláàfin Oyo ṣèlérí ìrànwọ́ ààbò fún Kwara

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Alaafin ti ilu Oyo, Oba Akeem Owoade, ti ṣeleri lati ṣiṣẹ pọ pẹlu ijọba Gomina ipinlẹ Kwara, Abdulraman Abdulrazak, lori ikọlu awọn agbebọn niluu naa.

Atẹjade ti Akọwe iroyin Alaafin, Bode Durojaiye, fi sita l'Ọjọbọ, ṣalaye pe Kabiyesi ti kan si Gomina Abdulrazaq lori ọna to dara ju lati tan iṣoro yii.

Ati pe gomina paapaa ti fi da Alaafin loju pe ikọ ologun pupọ ni wọn ti fi ranṣẹ si Kwara lati koju ikọlu naa.

Nigba to n koro oju si ipaniyan ọhun, Alaafin Owoade ṣapejuwe awọn agbebọn naa bii mujẹmujẹ ati ọta ilu.

O rọ ijọba apapọ lati ri i daju pe ọwọ ba gbogbo awọn to lọwọ si itajẹsilẹ Kwara ati awọn ibomiran lorilẹde yii.

"Ko yẹ ki awọn olori wa fọwọ yẹpẹrẹ mu ọrọ aabo, ṣugbọn ki wọn ri i daju pe wọn gbe igbesẹ kiakia ti yoo so okun aabo le ju bayii lọ, fun alaafia ati idagbasoke orilẹede wa.''

Alaafin Owoade lo sọ bẹẹ.

Bakan naa ni ikọ Amọtẹkun nipinlẹ Oyo, eyi ti Ajagunfẹyinti Olayinka Olayanju n lewaju rẹ, fi da awọn eeyan Kwara loju pe awọn ẹṣọ alaabo ti yi wọn ka.

Àwọn tí inú ijọba ń bi ló wà nídìí agbebọn to wọ Kwara, Kogi- Afẹnifẹre

Ni itẹsiwaju, ẹgbẹ Afẹnifẹre to n ri si ọrọ iran Yoruba naa ti kede, pe awọn ti inu wọn ko dun si ijọba to wa lode yii ati awọn to fẹ gba agbegbe ti ki i ṣe tiwọn lo wa nidii ikọlu to waye ni Kwara ati Kogi.

Afẹnifẹre sọ eyi di mimọ ninu atẹjade ti Akọwe ipolongo apapọ wọn; Comrade Jare Ajayi, fi ṣọwọ si BBC lọjọ Ẹti oni, ọjọ kẹta, oṣu Kẹwaa odun 2025.

Atẹjade naa ṣalaye pe awọn ikọlu to n waye ni Kwara ati apa kan aarin rẹ yii, to nnkan ibẹru fun ilẹ Yoruba ati awọn apa ibomiran lorilẹede yii.

Afẹnifẹre ṣalaye pe ilana ti awọn to pa eeyan pupọ ni Kwara lo, fi han pe wọn ki i ṣe ajinigbe gbowo lasan, wọn si yatọ si awọn darandaran.

"Iru nnkan ija ti wọn lo ati ọna ti wọn gbe ikọlu naa gba fi han pe wọn ni awọn alagbara kan nigbẹjọ to n ti wọn lẹyin nilẹ yii ati loke okun.

"Eeyan le fura si awọn ti wọn n pe ni awakusa lọna aitọ bayii.

"Ipinlẹ Kwara ti a mọ si ilu Alaafia wa di ibi ti ọpọ ẹmi ti n sọnu.

Ṣugbọn ki awọn to n ran awọn oniṣẹ ibi yii niṣẹ lọ mọ pe yoo kan awọn naa bi orilẹede yii ba da oju de''

Bẹẹ ni apa kan atẹjade ẹgbẹ Afẹnifere naa ka.

Afẹnifẹre kilọ, pe ohun to n ṣẹlẹ ni Afghanistan ati Libya latigba ti wọn ti pa Muarmar Ghadaffi gbọdọ jẹ arikọgbọn fun orilẹede Naijiria.

Wọn ni Libya ko sinmi latigba ti wọn ti pa Muarmar Ghadaffi, Afghanistan naa ko si ni alaafia latigba ti awọn Taliban ti gbajọba loṣu Kẹjọ ọdun 2021.

Ọna abayọ ti ẹgbẹ Afẹnifẹre la kalẹ ni pe itọpinpin ohun to n ṣẹlẹ yii ṣe koko. Wọn ni ki ijọba Kwara fura si awọn ti wọn n wa kusa lọna aitọ nibẹ.

Ki wọn wadii awọn araalu kan ti ẹnu n kun pe wọn mọ nipa awọn agbebọn to n wọlu.

Ki ijọba Kwara si ri i pe aijade bo ṣe wu araalu ti wọn ṣe ofin rẹ ko lọ titi, bo tilẹ jẹ pe o wulo lasiko yii.

Wọn fi kun un pe ki won mu ọlọpaa ipinlẹ ni koko bayii. Ati bẹẹ bẹẹ lọ.