Wo èèyàn mẹ́wàá tó lówó jùlọ ní àgbáyé bí Elon Musk ṣé léwájú pẹ̀lú $500bn

Oríṣun àwòrán, Reuters
Apọju owo ko si laye yii, owo pupọ ki i ṣe ohun ti eeyan yoo sọ pe ọrun n wọ oun si, afi ko maa pọ si ni olowo fi n gbayi lawujọ eeyan nibi yoowu lorilẹ aye.
Ni bayii, ajọ Forbes to n maa n kede awọn olowo aye, ti jẹ ko di mimọ, pe Elon Musk, olowo ilẹ America ni owo rẹ tun pọju lagbaaye bayii. $500 billion ni owo naa wọ l'Ọjọru, ọjọ kin-in-ni oṣu Kẹwaa ọdun 2025.
Gbajumọ ni Elon Musk lagbaaye, paapaa nipasẹ ileeṣẹ mọto to da silẹ ti a mọ si Tesla, bakan naa lo si tun jẹ alẹnulọrọ lorilẹede America.
Obitibiti owo to sọ Musk di olowo agbaye yii ko gba a ju ọdun kan lọ, nigba ti owo rẹ yi kuro ni $400 billion to wa tẹlẹ, ti ẹnikẹni ko si le ba a ninu awọn olowo asiko yii.
Gẹgẹ bi alaye ajọ Forbes to n kede awọn olowo biliọnu yii, Ọjọru ana ni iyanu nla ṣẹlẹ si owo Musk.
$499.1 billion lo ṣi wa ni nnkan bii aago marun-un irọlẹ ọjọ naa.
Ta a ni Elon Musk, báwo ló ṣe ko ọrọ̀ rẹ̀ jọ?
Pretoria, lorilẹede South Africa ni wọn ti bi Elon Reeve Musk, lọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹfa ọdun 1971.
Asiko ti ija ẹlẹyamẹya ti a mọ si Apartheid gbilẹ ni South Africa ni wọn tọ Musk dagba, ṣugbọn idile olowo lo ti wa.
Ọdun1989 lo kuro ni South Africa lọ si Canada lati kawe si i, o si ṣiṣẹ ọlọkan-o-jọkan.
O pada di ọmọ oniluu ni Canada ati America naa.
Oniṣowo agbaye ni Elon Musk, bẹẹ lo si tun jẹ olori nileeṣẹ bii
Tesla to n ṣe mọto, SpaceX, X, AI ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Lati ọdun 2021 ni Musk ti n jẹ ẹni to lowo ju lagbaaye, ṣugbọn o padanu rẹ fun asiko diẹ loṣu Kẹsan-an, nigba Larry Ellison, ọkan lara awọn to da ileeṣẹ onimọ ẹrọ Oracle gba a lọwọ rẹ.
Bakan naa ni Musk ti jabọ nipo naa ri lasiko kan ni 2022.
Nibi owo to n ko le Tesla yii ni èrè nla ti n wọle pada bi akọsilẹ ọna ti Musk n gba ri owo ṣe wi.
Ileeṣẹ rẹ yii lo gba oriyin ju ninu awọn to n ṣe mọto lagbaaye. Wọn ti ṣe mọto to n lo ina mọnamọna pẹlu.
Loṣu to kọja yii ni Musk kede pe oun ti ra ipin idokowo to to biliọnu kan dọla( $1 billion) nileeṣẹ Tesla.
Eyi tun mu ifọkantan ba ileeṣẹ naa, to tun ti di ile agbara AI ati ti awọn ẹrọ oyinbo ti a mọ si robot.
Wo àwọn mẹ́wàá tó lówó jù láyé (lóṣù Kẹwàá ọdún 2025)

Oríṣun àwòrán, Instagram
Ni ilẹ toni to mọ ninu oṣu Kẹwaa ọdun 2025 yii, wọnyi ni eeyan mẹwaa ti ajọ Forbes kede pe awọn ni wọn lowo julọ lagbaaye.
- Elon Musk: Gẹgẹ bi a ṣe wi, ko si ẹni to n ba Elon Musk du ipo akọkọ ninu awọn olowo aye bayii. Oun ni ẹni ti owo rẹ pọ ju lọ, ẹni ọdun mẹrinlelaadọta (54) ni.
- Larry Ellison:$341.8 billion
Ọna ọla: Oracle.
Ẹni ọdun 81 ni baba naa. Ọmọ orilẹede America ni, Woodside, California lo fi ṣe ibugbe.
- Mark Zuckerberg: $251.5 billion
Ọna ọlà: Meta (Facebook).
Ẹni ọdun mọkanlelogoji ni oludasilẹ oju opo Facebook naa.
Ọmọ orilẹede America ni, Palo Alto, California lo n gbe.
Ileeṣẹ rẹ naa lo ni oju opo Instagram ati WhatsApp.
- Jeff Bezo: $232.5 billion
Ọna ọla: Amazon.
Ẹni ọdun mọkanlelọgọta ( 61) ni. Miami, Florida lo n gbe, niluu America, ọmọ ilu naa ni Jeff Bezo n ṣe.
- Larry Page: $202.2 billion
Ọna ọla: Google.
Ẹni ọdun mejilelaadọta ( 52) ni.
Ọmọ orilẹede America si ni pẹlu. Palo Alto, California lo n gbe.

Oríṣun àwòrán, Screenshot
- Sergey Brin: $187.6 billion
Ọna ọla: Google, ẹni ọdun mọkanlelaadọta (51) ni.
Los Altos, California lorilẹede America loun naa n gbe, ọmọ America si ni.
Jensen Huang: $162 billion
Ọna ọla: Semiconductors.
Ẹni ọdun mejilelọgọta ( 62) ni. Los Altos, California lo n gbe, ọmọ ilẹ America ni, bo tilẹ jẹ pe Taiwan ni wọn ti bi i.
- Bernard Arnault: $159.4 billion
Ọna ọla: LVMH/ awọn ọja afẹ ati faari.
Ẹni ọdun mẹrindinlaadọrin (76) ni baba naa.
Paris lo n gbe, ọmọ orilẹede France ni.
Baba to bi Bernard Arnault pa ọpọlọpọ miliọnu nilana ile kikọ to yan laayo ni tiẹ, ṣugbọn Benard gbe tiẹ gba ibi ẹṣọ ara, o si di gbajumọ fun awọn orukọ bii Louis Vuitton, Christian Dior, Moet & Chandon, Sephora and jeweler Tiffany & Co.
- Steve Ballmer: $156 billion
Ọna ọla: Microsoft, LA Clippers, investments.
Ẹni ọdun mọkandinlaadọrin (69) ni. Hunts Point, Washington lorilẹede America lo n gbe, ọmọ orilẹede naa si ni pẹlu.
- Warren Buffett: $150.2 billion
Ọna ọla: Berkshire Hathaway.
Ẹni ọdun marundinlọgọrun-un ( 95) ni Warren Buffet.
Omaha, Nebraska l'America lo fi ṣe ibugbe.
Baba agba naa ni awọn eeyan mọ si "Oracle of Omaha," ọkan lara awọn to maa n ko owo nla le okoowo lati ọdun pipẹ ni, ọmọ odun mọkanla pere lo si wa to fi ra ipin idokowo rẹ akọkọ.
Ọgbọnjọ oṣu Kẹjọ ọdun 2025 yii ni Bufeet pe 95, ṣaaju lo si ti kede pe oun yoo fẹyinti nipari ọdun 2025 yii.

Oríṣun àwòrán, Facebook
Alice Walton ni obinrin to wa lara awọn eeyan to lowo julọ ni agbaye

Oríṣun àwòrán, Facebook
Bo tilẹ jẹ pe ọkunrin ni gbogbo awọn olowo aye wọnyi, obinrin kan naa wa ti owo rẹ pọ ju lagbaaye, orukọ rẹ ni Alice Walton.
Baba to bi Alice Walton ni Sam Walton, to da ileeṣẹ Walmart silẹ.
Lọjọ kin-in-ni oṣu Kẹwaa odun 2025, owo Alice Walton jẹ $111.9 billion.














