Ìdí rèé tí Sunday Igboho fi ṣàbẹ̀wò sí Ọba Ladoja àti ohun tó fẹ́

Olubadan ilẹ Ibadan, Ọba Rashidi Ladoja ati Oloye Sunday Igboho lasiko ti Igboho ṣabẹwo si kabiyesi ni aafin rẹ

Oríṣun àwòrán, Koiki Media/Facebook

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Olubadan ti ilẹ Ibadan, Ọba Rashidi Ladoja, ti ṣeleri lati ṣe iranwọ fun ajafẹtọọ ọmọniyan to tun jẹ ọkan gboogi lara awọn to n polongo fun idasilẹ orilẹede Yoruba, Oloye Sunday Adeyemo, ti ọpọ mọ si Sunday Igboho, lori apo ikowosi rẹ ti ijọba apapọ gbẹsẹ le.

Ọba Ladoja sọrọ yii lasiko ti Igboho ṣabẹwo si i ni aafin rẹ niluu Ibadan laarin ọsẹ yii.

Lasiko abẹwo naa ni Ọba Ladoja ṣe ipade idakọnkọ pẹlu Igboho ti wọn si jọ sọrọ lori fakaaja to wa laarin rẹ ati ijọba apapọ.

Igboho ṣeleri lati ṣiṣẹ pọ pẹlu ijọba apapọ, ki eto abo le fẹsẹ mulẹ si i lẹkun iwọ oorun guusu Naijiria

Iroyin kan fidi rẹ mulẹ pe Ọba Ladoja ṣeleri lati dasi ọrọ Igboho papaa julọ lori ati yọ ọ kuro lara awọn ọdaran tawọn ẹṣọ eleto aabo kede wi pe awọn n wa ati lati ri pe ijọba apapọ gbẹsẹ kuro lori apo ikowosi rẹ to ti pa.

Ti ẹ o ba gbagbe, ijọba Aarẹ Muhammadu Buhari, lo kede Igboho gẹgẹ bi ọdaran ti ijọba n wa ti o si tun gbẹsẹ le apo ikowosi rẹ lori ẹsun pe o n ko nnkan ija oloro pamọ sile rẹ.

Lọjo kinni oṣu Keje ọdun 2021 ni ajọ DSS pẹlu atilẹyin awọn sọja ya bo ile Igboho to wa lagbegbe Soka niluu Ibadan nibi tawọn ọmọlẹyin rẹ meji ti ku, ti ajọ DSS si mu eeyan mẹtala mii nile Igboho lọ silu Abuja.

Ninu ọrọ rẹ, Igboho ṣapujuwe Ọba Ladoja gẹgẹ bii olori ti araalu fẹran nilẹ Ibadan ati kaakiri ilẹ Yoruba lapapọ.

Igboho ṣeleri lati ṣiṣẹ pọ pẹlu ijọba apapọ lati jẹ ki eto abo fẹsẹ mulẹ si i lẹkun iwọ oorun guusu orilẹede Naijiria.

Ajijagbara fun idasilẹ Yoruba Nation sọ pe Ọba Ladoja yoo ri pe alaafia, iṣọkan ati idagbasoke wa nilẹ Ibadan ati kaakiri ilẹ Yoruba lasiko rẹ gẹgẹ bii Olubadan ti ilẹ Ibadan.

Igboho ke pe Ọba Ladoja fun iranwọ lori apo ikowosi rẹ ti ijọba gbẹsẹ le lawọn banki

Ṣaaju ni Igboho ṣabẹwo si Olubadan ni aafin rẹ ti o si fi oriṣiiriiṣi fọto to ya pẹlu Ọba Ladoja sori itakun ayelujara.

Lasiko abẹwo rẹ yii naa ni o ti sọ pe ''baba ni Ọba Ladoja jẹ fun mi lati igba ti o ti wa ni ipo gomina ipinlẹ Oyo.

Kabiyesi ni awọn amuyẹ olori bii ẹmi irẹlẹ atawọn amuyẹ mii ti olori nilo lati ṣe aṣeyọri.''

Lasiko to ṣabẹwo si Olubadan naa ni o ti bẹ ori ade naa lati ran oun lọwọ lori apo ikowosi rẹ ti ijọba apapọ gbẹsẹ le lawọn banki.

Laipẹ yii ni Igboho ṣabẹwo si Olugbon ti Orile Igbon, Ọba Francis Olusola Alao, naa ti o si rọ kabiyesi lati boun bẹ ijọba wi pe ki o yọ orukọ oun kuro lara awọn ọdaran ti ijọba n wa.

Bakan naa ni Igboho tun ṣe abẹwo si Ooni Ile Ife, Ọba Adeyeye Ogunwusi, Ọjaja Kẹta ni aafin rẹ lati ṣe iranwọ fun un lori ọrọ yii kan naa.

Ta ni Sunday Igboho, ki lo de ti ijọba gbẹsẹ le apo asunwọn owo rẹ?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Sunday Adeyemo, ti ọpọ mọ si Sunday Igboho, jẹ gbajumọ ajafẹtọ ẹni to n pe fun idaduro ilẹ Yoruba, Yoruba Nation.

Ẹjọ Kẹ́waa, osu Kẹwaa ọdun

Lasiko to bẹrẹ ipe fun idaduro ilẹ Yoruba, ni oru mọjumọ ọjọ kini, oṣu keje, ọdun 2021 ni awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ, DSS lọ kọlu ile Sunday Igboho.

Wọn pa awọn eeyan meji, ti wọn si ko awọn mẹtala lọ siluu Abuja amọ ori ko Igboho yọ, to si salọ si orilẹede Benin.

Ẹsun ti DSS fi kan Igboho ni pe o n ko ibọn ati awọn ohun ija oloro pamọ lati da ogun silẹ laarin ilu, ti wọn si gbẹsẹle awọn apo asunwọn owo rẹ to wa ni Naijiria.

Ọjọ Aje, ọjọ kọkandinlogun, oṣu keje, ọdun 2021 ni ileeṣẹ eleto aabo Interpol mu Sunday Igboho ni papakọ ofurufu Cadjèhoun to wa ni Cotonou ti ilẹ olominira Benin.

Alẹ ọjọ naa la gbọ pe Igboho n gbiyanju lati ri irin ajo lọ si orileede Germany pẹlu iyawo rẹ Rọpo Adeyẹmọ.

Ọjọ kẹtalelogun, oṣu keje, ọdun 2021 ni Igboho foju ba ile-ẹjọ Cour D'Appel De Cotonou lori ẹsun wi pe o wọ orileede naa lọna aitọ ati nini ayederu iwe irinna orileede naa.

Oṣu mẹsan gbako ni Igboho lo ni ahamọ inu ile ni ilẹ olominira Benin, ko to di pe o gba ominira.

Kete si lo morile ilẹ Germany nibi to n gbe amọ laipẹ yii lo pada wa sile, to si n beere fun ominira pipe ati idapada apo asunwọn owo rẹ tijọba gbẹsẹ le.