Ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì sọ àwọ̀ ara èèyàn di ọmọ pẹ̀lú DNA fún ìwúlò tọkọtaya tí kò le ṣe IVF láti bímọ torí àrùn tàbí ọjọ́ ogbó

Oríṣun àwòrán, OHSU/Christine Torres Hicks
- Author, James Gallagher
- Role, Health and science correspondent
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6
Fun igba akọkọ, awọn onimọ ijinlẹ Sayẹnsi lati US ti ṣe ẹ̀dá ọlẹ̀ inu obinrin nipa lilo awọ ara awọn eeyan pẹlu ami idanimọ DNA wọn, eyi ti wọn da pọ mọ atọ ọkunrin.
Ilana yii ni wọn ni o le ṣẹgun airi ọmọ bi to ba waye nipasẹ ọjọ ogbo tabi arun.
Koda, o tun le jẹ ki awọn eeyan to n ni ibalopọ akọ-si- akọ, abo-si-abo naa di ọlọmọ pẹlu bi wọn ṣe sọ.
Ohun ti wọn ni ilana oyun nini yii nilo pe wọn gbọdọ ṣiṣẹ lorii rẹ daadaa fun bii ọdun mẹwaa si i, ko too di ohun ti awọn ileewosan to n ri si oyun nini yoo le maa lo.
Awọn akọṣẹmọṣẹ sọ pe aṣeyọri to wuni lori jọjọ ni, ṣugbọn o yẹ ki asọye gidi waye nipa rẹ fun awọn eeyan lati mọ ohun ti Sayẹnsi fẹẹ fayọ gan-an.
Wọ́n yí ìlànà àtọ̀ àti ẹyin tó ń di ọmọ pada
Lati ayebaye wa, atọ ọkunrin ati ẹyin obinrin lo n di ọmọ. Mejeeji ni yoo parapọ ti yoo di ọlẹ sinu obinrin, to ba si di lẹyin oṣu mẹsan-an, ọmọ tuntun a waye.
Ṣugbọn ni bayii, awọn onimọ ijinlẹ Sayẹnsi ti n yi ilana atayebaye naa pada, eyi to si gbode bayii ni bi wọn ṣe n sọ awọ ara eeyan di ọmọ.
Iwadii ti 'The Oregon Health and Science University'', ṣe ni wọn fi gbe kinni kan kalẹ ti wọn gbe ọlẹ naa si- eyi ti wọn fi awọ ara pilẹ rẹ.
Lẹyin eyi ni wọn yoo gbe e sinu ẹyin obinrin ti wọn ti gba, lai fi ti ẹni to ni ẹyin naa ṣe.
Nibi ti wọn ba a de bayii, ilana yii fẹẹ da bii iru eyi ti wọn fi ṣe 'Dolly the Sheep' – iyẹn ẹranko akọkọ ti wọn ṣe ni 1996 lai si pe ẹranko meji ba ara wọn laṣepọ.

Oríṣun àwòrán, OHSU
Ṣugbọn ṣaa, ẹyin ti a n wo yii ko ti i ṣetan ti yoo di ọmọ nipasẹ atọ, nitori o ti ni awọn nnkan ayipada ti a mọ si chromosomes ninu.
Mẹtalelogun ( 23) iru awọn nnkan yii ni ọmọ maa n mu lara iya ati baba rẹ ninu DNA wọn nikọọkan. Apapọ rẹ yoo si jẹ marundinlaadọta (46), eyi to ti wa lara ẹyin atọwọda yii ni tiẹ.
Fun idi eyi, ipele to kan ni lati rọ ẹyin naa pe ko ja idaji ninu awọn chromosomes yii kuro, eyi ni awọn oniwadii n pe ni "mitomeiosis" (itumọ ọrọ naa ni idapọ mitosis ati meiosis, iyẹn ọna meji ti sẹẹli ara pin si).

Iwadii ti wọn gbe jade ninu Journal Nature Communications, fi han pe ẹyin 82 to ṣiṣẹ daadaa ni wọn pese. Atọ ni won fi pese wọn, awọn kan si di ọlẹ, ṣugbọn ko si eyi to kọja ọjọ mẹfa ninu wọn.
"Ohun ti wọn ro pe ko lẹ ṣee ṣe ni awa ṣe yii." Ọjọgbọn Shoukhrat Mitalipov, Adari Oregon Health and Science University's centre for embryonic cell and gene therapy, lo sọ bẹẹ.
Ilan yii yatọ gedegbe, pẹlu bi ẹyin yoo ṣe funra ẹ pinnu eroja chromosome ti ko ba fẹ. O gbọdọ wa pẹlu ọkọọkan awọn ẹya 23 yẹn lati dena arun, ṣugbọn meji lo maa n pada mu lara awọn kan, o si le maa mu nnkan kan lara awọn chromosome yoku.
Bakan naa ni wọn ti ri aṣeyọri ti wọn le pe ni ida mẹsan-an (around 9%) ti awọn chromosomes ko mu abala pataki kan to yẹ ki wọn mu, to si pada di pe wọn n ṣe atunto DNA, eyi ti wọn n pe ni 'crossing over.'
"Ọjọgbọn Mitalipov, onimọ to gbajumọ nipa eto yii kari aye, sọ fun mi pe a gbọdọ yanju rẹ ka si ṣe e debi to peregede."
"Nigbẹyin, ero mi ni pe ilana ti wọn yoo maa tọ lọjọ iwaju ree, nitori awọn eeyan ti ko le bimọ pọ gan-an."

Oríṣun àwòrán, OHSU/Christine Torres Hicks
''Èròǹgbà ìlànà yìí ni lati ran àwọn tọkọ-taya tí kò lè ṣe IVF lọ́wọ́''
Erongba ilana igbalode yii ni lati jẹ ki atọ ọkunrin ati ẹyin obinrin maa ṣiṣẹ ìbí lai duro lara ẹda eeyan, eyi ni a mọ si 'Vitro gametogenesis''.
Ipele aṣẹṣẹbẹrẹ lo ṣi wa bayii, ko ti i ṣee lo fun awọn ileewosan to n ri si iṣoro airọmọbi. Ṣugbọn afojusun rẹ ni lati ran awọn tọkọtaya ti ko le 'se IVF (in vitro fertilisation) lọwọ, nitori wọn ko ni atọ ati ẹyin ti wọn le lo.
Bakan naa lo le ran awọn obinrin ti wọn ti dagba lọwọ, awọn ti ẹyin wọn ko lagbara lati di ọmọ mọ. O si tun wulo fun awọn ọkunrin ti atọ wọn ko to, ati awọn ti itọju arun jẹjẹrẹ ti pa atọ ara wọn ku patapata.
Alaye miran to tun wa lori ilana yii ni pe o n jẹ ko ye wa pe dandan kọ ni ka ri obinrin ki ọmọ too waye - Eyi lo fi wulo fun awọn ọkunrin to n ba ọkunrin ẹgbẹ wọn ṣe, ati awọn obinrin to n ba obinrin bii ti wọn ṣe lati bimọ ti yoo jẹ tiwọn.
Wọn le lo awọ ara ọkunrin kan lati ṣiṣẹ atọ, wọn yoo si so awọ ara ọkunrin keji di ẹyin ti yoo sọ ọ di ọmọ.
''Àwọn èèyàn yóò ní ìgbàgbọ́ nínú ìlànà yìí''
Roger Sturmey, Ọjọgbọn onimọ nipa ọmọ bibi lati University of Hull, sọ pe ilana yii ṣe pataki o si wuni lori.
O fi kun un pe, "Bakan naa, iru iwadii yii maa n fi aaye gba asọye laaarin awujọ, ti wọn yoo pada tẹwọ gba a , wọn yoo mọ nipa itẹsiwaju to ti ba ọmọ bibi.
"Aṣeyọri bi eyi wu wa lori gan-an,yoo ran akoyawọ lọwọ, yoo si fi aaye igbagbọ silẹ lawujọ."
Ọjọgbọn Richard Anderson, Igbakeji adari ni 'MRC Centre for reproductive health', ni University of Edinburgh, ṣalaye pe pipese ẹyin tuntun yoo di ohun to ti gunke agba gan-an.
O ni: " Loootọ ni ibẹru le maa wa nipa aabo to wa fun ilana yii, ṣugbọn koko ibẹ ni pe ilana naa wa fun riran ọpọ obinrin lọwọ lati bi ọmọ tiwọn ti yoo ni DNA wọn gan-an lara."












