Ìjọba Oyo ń fi ìyà jẹ wá, oúnjẹ wa kò ṣe fojú rí - Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó ní ìpèníjà ojú ṣe ìwọ́de

Awọn ọmọ ile-ẹkọ Omoyeni to wa ni agbegbe Orita Aperi, niluu Ibadan ti ṣe iwọde lati fi aidunnu wọn han si bi awọn ọga ile ẹkọ naa ati ijọba ipinlẹ Oyo ko ṣe mu igbaye-gbadun wọn ni ọkunkundun.
Awọn ọmọ ile ẹkọ naa to jẹ awọn akẹkọọ to ni ipenija oju ṣalaye pe, opopona to wọ awọn yara ilegbe ati ile ẹkọ wọn ko daa rara papa julọ pẹlu iru ipenija ti awọn ni.
Wọn tẹsiwaju pe niṣe ni awọn ounjẹ ti wọn n fun awọn ko bojumu nitori ogi, ẹba, ati spaghetti nikan lawọn n jẹ lojojumọ, lọpọ igba si ni ounjẹ naa ko to awọn.
"Ọpọ lẹ́tà la ti kọ ransẹ ṣaaju ifẹhonuhan lai ri esi kankan gba"
Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ie ẹ̀kọ́ Omoyeni tẹsiwaju pé, awọn yara ilegbe to wa ninu ọgba ile ẹkọ naa ko bojumu, ti ayika ile ẹkọ ọhun si buru jọjọ.
Awọn ọmọ ile ẹkọ naa lo bẹrẹ iwọde ọhun ni nnlkan bii aago mẹsan aabọ aarọ ọjọ Ìṣẹ́gun, ni wọn gbe ifẹhonuhan naa lọ sagbegbe Orita Aperin niluu Ibadan.
Ọkan lara awọn ọmọ to ni ipenija oju naa, Muheez ni ijọba ipinlẹ oyo n fi ẹtọ awọn dun wọn nitori wọn faye gba ki awọn akẹkọọ to ṣẹṣẹ wọ ipele kinni, JSS1 maa gbe ninu ọgba ile ẹkọ lọna ati le awọn to ti wa nibẹ tẹlẹ kuro.

"Oludamọran si gomina Seyi Makinde fún ọ̀rọ̀ awọn akanda ẹda ko ṣiṣẹ rẹ bíi isẹ"
Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó ní ìpèníjà ojú nile ẹ̀kọ́ Omoyeni wa naka aleebu si amofin Ayodele Adekanbi ti ijọba ipinlẹ Oyo yan lati ri si igbayegbadun awọn akanda ẹda nipinlẹ náà.
Wọn ní Adekanmbi ko ṣe iṣẹ́ rẹ bo ṣe yẹ nitori ọpọ lẹ́tà ni awọn ti kọ ransẹ ṣaaju ifẹhonuhan ti wọn gunle lai ri esi kankan gba.
Wọn wa ṣeleri lati tẹsiwaju ninu ifẹhonuhan ọhun titi di igba ti ijọba ipinlẹ Oyo yoo fi ṣe ohun to yẹ.
Nigba to ń fèsì lori ifẹhonuhan àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà àti àwọn ẹ̀sùn tí wọn fi kan an, Adekanmbi ni ootọ ni pe ounjẹ wọn ko dara amọ ìjọba maa sa ipa wa lati mu inu wọn dun.
Amofin Ayodele Adekanbi rọ awọn olufẹhonuhan naa lati pada si yara ikawe wọn.

"Maa gbe igbesẹ lati gba awọn ti yoo maa dana aladun fun awọn akẹkọọ ọhun, ikankan wọn kò sì ní fi yara to ń gbé nile ẹ̀kọ́ náà silẹ"
Nigba to n ba baa akọroyin BBC News Yoruba sọrọ, Adekanbi ni ijọba ipinlẹ Oyo yoo ṣe abojuto ipese ounjẹ to dara fun awọn ọmọ ile-ẹkọ Omoyeni ati pe awọn ọmọ ile ẹkọ naa kankan ko ni fi yara ilegbe wọn silẹ.
O tẹsiwaju pe ko tii ju ọdun meji ti oun de ipo amọ awọn ti ri si idagbasoke awọn eeyan to ni ipenija oju pẹlu ipese ìṣẹ ìjọba fun wọn.
O ni lootọ ni pe ounjẹ wọn ko dara to bo ṣe yẹ, ṣugbọn oun yoo gbe igbesẹ lati gba awọn ti yoo maa dana aladun to si dara fun awọn akẹkọọ ọhun.















