Ìdí rèé tí nǹkan fi ń le sí lẹ́ka ọrọ̀ ajé Naijiria lẹ́yìn ọdún 65 tó gba òmìnira

Ọwọ kan ko owo naira dani, igba ati ẹgbẹrun kan naira ni iru owo to ko dani naa

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, Owo naira ti ẹnikan ko dani
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 8

Bi peregun ṣe n maa n mu awọ tutu waye lọdọọdun ni Naijiria naa n ṣajọdun ominira rẹ to ti gba lati ọdun marundinlaadọrin (65) sẹyin.Ti ọdun yii naa ti kò báyìí.

Ṣugbọn bii ẹni to n fi ọdun yin ọdun ni ọrọ orilẹede naa n ri, pẹlu bi nnkan ko ṣe fararọ bi a ba fi we bo ṣe wa lasiko ti oyinbo n dari Naijiria.

Ọpọ eeyan ni ọrọ iu yii ti su, to bẹẹ ti wọn ti gba oko ibo mi-in lọ, wọn japa lọ silẹ okeere.

Awọn ti ko japa paapaa ko duro nilẹ yii nitori ifẹ Naijiria, pupọ wọn lo jẹ pe bi wọn ba rọna lọ, wọn ko ni ro o lẹẹmeji ti wọn yoo fi sa lọ.

Bẹẹ, o ni ohun to ṣẹlẹ ti Naijiria fi di nnkan mi-in lẹyin ominira rẹ.

Ko too di pe Boko Haram de ti wọn n paayan bii ẹran ni iṣoro ọro aje ti wa nilẹ.

Ijinigbe tun jẹ iṣoro miran ti ko gbẹyin ninu idaamu Naijiria. Ebi buruku tun pọ nilẹẹ wa pẹlu, ko sowo, ko siṣẹ, ko sina, ko somi, ko si oju ọna to ṣee rin, bẹẹ ni ko si ifọkanbalẹ to le mu ẹmi pẹ laye.

Paripari rẹ ni ti owo Naira to jẹ ọba owo lagbaaye tẹlẹ, to ti wa di ohun to yẹpẹrẹ ninu owo agbaye bayii, nigba ti Naijiria wa lominira.

Eredi ayipada buruku yii ni BBC News Yoruba, beere lọwọ Onimọ nipa ọrọ aje, Bisi Iyaniwura, ṣe aṣiṣe ni gbigba ominira jẹ fun Naijiria ni, ọkunrin naa dahun pe:

"Irù òfin àti òṣèlú tí wọ́n bá ń ṣe lórílẹ̀èdè kan ni yóò sọ bí ọrọ̀ ajé wọn yóò ṣe rí''

Aworan Aarẹ Bola Tinubu to n kawe. Aarẹ wọṣọ alawọ aro, o de fila o si fi awò soju. Ẹrọ gbohun-gbohun kan wa lẹgbẹẹ rẹ, o si gbe irinṣẹ igbọrọ seti.

Oríṣun àwòrán, @ASIWAJU BOLA TINUBU

"A ko le sọ pe ki ọrọ aje Naijiria ṣiwaaju ati lẹyin to gba Ominira ri bakan naa, nitori ko si ọrọ aje to maa n duro loju kan bii omi adagun, yoo maa yipada naa ni.

"Ṣugbọn ti a ba ni ka wo bi owo Naira ṣe ti bajẹ to bayii, to si jinna si awọn owo ilẹ okeere to ku, ẹ o ri i pe o buru pupọ, ko si ri bẹẹ nigba kan.

"Lasiko kan ni Naijiria yii, owo Naira lagbara ju dọla lọ. Lonii, Naira ti takiti, o si n pe fun igbedide.

"Ọpọ eeyan ni ko waa mọ pe iru ofin ti wọn ba n ṣe niluu kan, ati iru oṣelu ti wọn n danwo nibẹ, maa n ni ipa lara owo ati ọrọ aje wọn.

Orilẹede kan le pinnu lati jẹ ki iye ti wọn yoo maa ṣẹ owo rẹ si ti ilẹ okeere kere si awọn owo yooku lagbaaye, wọn le ṣe bẹẹ nitori oṣelu ati ki nnkan le daa fun wọn lẹka ọrọ aje.

Awọn orilẹede bii Japan ati China, mọ-ọn-mọ jẹ ki owo wọn ma niye lori ju bẹẹ lọ, ki owo ti wọn yoo maa san lori ọja ti wọn ba n ko jade maa baa wọ́n, ko si le rọ wọn lọrun.

Báwo ni wọ́n ṣe rí i ṣe?

Aworan yii ṣafihan awọn gendekunrin to n ru apo iyẹfun lati inu ọkọ nla kan jade. Awọn kan n gbe e ru wọn, awọn kan si i n fi ori ru u lọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Awọn gendekunrin n ru apo iyẹfun
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

"Ohun to jẹ ko ṣee ṣe fun wọn ni pe awọn ni wọn n ṣe awọn nnkan ti wọn nilo funra wọn ( Producing economy). Ohun ti wọn n ṣe ni wọn n ra ti wọn si n lo, ọrọ aje wọn si n dagba nitori owo wọn to n gbe orilẹede wọn.

"Ki i ṣe nnkan yẹpẹrẹ ni wọn n ṣe o, gbogbo ọja ati nnkan eelo tawọn ilu miran wa n ko lati ọdọ wọn ni wọn n ṣe funra wọn.

"Bi wọn ṣe n lo o funra wọn ni wọn n ta a si oke okun kiri.

"Ṣugbọn Naijiria ni tiẹ ki i ṣe orilẹede to n ta ohun ti a ba ṣe funra wa si orilẹede miran.

"Awọn nnkan eelo (Raw material) ti wọn le fi ṣe ohun ti awọn orilẹede miran nilo ni awa fi n ranṣẹ soke okun.

"Itumọ eyi ni pe bi a ba n ko iru nnkan wọnyi jade lọ silẹ okeere, owo nla-nla la o maa fi ra awọn ohun ti wọn fi tiwa ṣe pada, yoo si maa pa ọrọ aje wa lara.

"Si iyalẹnu ṣaa lẹnu ọjọ mẹta yii, ijọba wa n gbe awọn onka apanilẹrin kan jade.

"Wọn n sọ pe iye Naira to le ra dọla kan ti n dinku, o ti n wọ bii 1,400 naira si dọla kan, ati pe owo ilẹ okeere ti Naijiria ni nipamọ (Foreign reserve) ti gunke daadaa, wọn lo ti wọ 42 biliọnu owo dọla.

"Eyi pani lẹrin gan-an nitori onka nla ti wọn n kede yii ko han lara ọrọ aje Naijiria, bẹẹ ni ko han lara araalu paapaa.

"Owó ọjà tó yẹ kó dínkù ń gun òkè sí i, ọrọ̀ ajè ń burú sí i"

Ohun jijẹ: Epo, ẹwa, irẹsi, panla ati bẹẹ bẹẹ lọ lo han ninu aworan yii. Ko ṣee ma ni ni wọn

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ohun jijẹ: Epo, ẹwa, irẹsi, panla ati bẹẹ bẹẹ lọ

Ni itẹsiwaju alaye yii, Onimọ nipa ọrọ aje, Bisi Iyaniwura sọ pe:

"Niṣe ni owo ọja to yẹ ko wa silẹ n gunke si i, bẹẹ to ba jẹ pe owo Naijiria ti n ṣe daadaa bi ijọba ṣe wi ni, ti a si ni 42b dọla owo ilẹ okeere nipamọ, o yẹ ki ọrọ aje wa rugọgọ si i ni, ki araalu paapaa mọ pe iyatọ ti wa.

"Ṣugbọn kaka bẹẹ, niṣe ni gbogbo nnkan n wọ́n gogo si i. Eyi fi ye wa pe nnkan ko ri bo ṣe yẹ ko ri, o si han kedere pe awọn kan wa nibi kan ti wọn ko sọ ododo fun wa.

Awọn onileeṣẹ n sọ pe awọn ko ta, ọja o ya, ọpọ ọja lo kun ile iko-ọja si awọn.

Itumọ eyi ni pe agbara lati mu owo lọọ ra nnkan ti araalu nilo ko si fun wọn mọ, awọn eeyan ko le ra nnkan to tiẹ jẹ ko ṣee ma ni ninu ile mọ, ka ma tii sọ awọn nnkan to jẹ faaji lasan ni wọn.

"Owó àwọn irè oko kan tó ń wálẹ̀ lásìkò yìí kò ṣẹ̀yìn ọgbọ́n tíjọba dá, ṣùgbọ́n ọgbọ́n tó léwu ni''

"Ẹ o ṣakiyesi pe awọn ọja oko kan dinwo, paapaa ni awọn ọja igberiko.

"A le sọ pe owo awọn nnkan jijẹ kan to n wa lati oko n dinku diẹ si i ju ti tẹlẹ lọ. Ṣugbọn ṣe a le sọ pe aṣeyọri kan leyi bi?

Bẹẹ ni, bẹẹ si tun kọ.

"To ba jẹ pe ọna to yẹ kijọba gbe e gba ni wọn gbe adinku yii gba, a le sọ pe wọn ṣe daadaa.

"Ṣugbọn ohun ti a ri ni pe ijọba n fi aaye gba kiko awọn nnkan jijẹ kan wọlu lati oke okun.

"Idi keji ti awọn ire oko yii tun fi rọju diẹ lasiko yii ni pe asiko ikore la wa yii, ere oko n jade daadaa.

" Awọn agbẹ ko ri ọgbọn kankan da si i ju ki wọn ta a sita naa lọ, bo ṣe n pọ naa ni owo rẹ yoo si ṣe maa ja walẹ.

"Bi ijọba Naijiria ṣe n fi aaye gba kiko ọja wọle lati oke okun yii ko le ṣe anfaani fun awọn agbẹ ilẹ wa ati ọrọ aje Naijiria. Yoo wulẹ maa ko o ba a ni.

"Awọn ilu ti a n ra nnkan oko lọwọ wọn yii n jẹ anfaani owo iranwọ (subsidy intervention) lori ọja tiwọn lorilẹede wọn, ko ri bẹẹ fun awa ti a n kowo lọ ra a lati ọhun wa sibi.

"Awọn agbẹ Naijiria ko ri anfaani owo iranwọ, bawo la ṣe le fi wọn we ara wọn.

Ọnà àbáyọ

"Iṣẹ pọ lọwọ ijọba Naijiria bi wọn ba fẹ ki ọrọ aje ilu yii ṣe daadaa pada bii tigba kan.

"Awọn nnkan wọnyi ti a ti sọ kalẹ ti wọn ko bojuto lo n fa iṣoro fun owo ati ọrọ aje Naijiria, eyi ko si kan boya a wa lominira tabi bẹẹ kọ.

"Orilẹede to ba fẹẹ ni ọrọ aje to duro deede, to fẹ ki owo rẹ niyi ko si tẹ̀wọ̀n lọja agbaye, gbọdọ ri i daju pe oun n pese ohun ti oun nilo funra oun.

"O gbọdọ ri i pe o fi owo nla ran ohun ti wọn nilo lati oke okun lọwọ.

"Bakan naa ni awọn ẹka ti araalu ba ti nilo iranwọ, ki ijọba ma ṣe fi dun wọn.

"Paripari ẹ ni pe ki wọn jẹ olootọ, ki wọn si fi akoyawo sin orilẹede wọn ati awọn eeyan ibẹ."

Bẹẹ ni Bisi Iyaniwura wi.