Adigunjalè pa gbajúmọ̀ agbóhùnsáfẹ́fẹ́ mọ́ ilé rẹ̀ ní Abuja, aráàlú gbarata

Somtochukwu Maduagu wọ aṣọ dúdù pẹ̀lú aṣọ funfun lábẹ́, tó sì ń rẹ́rìn-ín

Oríṣun àwòrán, ARISE TV/X

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Níṣe ni àwọn èèyàn lójú òpó ìkànnì ayélujára ti ń kọminú lórí ètò ààbò Nàìjíríà lẹ́yìn tí ìròyìn ikú Agbóhùnsáfẹ́fẹ́ iléeṣẹ́ Arise Television, Somtochukwu Maduagwu gbòde lọ́jọ́ Ajé, ọjọ́ Kọkàndínlọ́gbọ̀n, oṣù Kẹsàn-án, 2025.

Ìròyìn ní àwọn adigunjalè ló lọ ṣekúpa Somtochukwu mọ́ ilé rẹ̀ tó wà ní agbègbè Katampe ní ìlú Abuja.

Àtẹ̀jáde kan tí iléeṣẹ́ ìròyìn Arise fi sójú òpó X lọ́jọ́ Ajé sọ pé ní òwúrọ̀ kùtùkùtù ọjọ́ Ajé ni àwọn adigunjalè náà yawọ ilé Somtochukwu, tí wọ́n sì ṣekúpa á àti pé àwọn ti fi ìṣẹ̀lẹ̀ náà tó àwọn ọlọ́pàá létí.

Iléeṣẹ́ Arise nínú àtẹ̀jáde náà sọ pé pẹ̀lú ọkàn tó gbọgbẹ́ ni àwọn fi kéde ikú akọ̀ròyìn náà.

Wọ́n júwèé Somtochukwu, ẹni ọdún mọ́kàndínlọ́gbọ̀n (29) tó jẹ́ agbẹjọ́rò àti agbóhùnsáfẹ́fẹ́ tó mọ iṣẹ́ rẹ̀ níṣẹ́ àti pé àwọn ń fẹ́ ìwádìí tó gbòòrò lórí ikú rẹ̀.

Àwọn aláṣẹ iléeṣẹ́ náà rọ àwọn ọlọ́pàá láti ri dájú pé wọ́n fojú àwọn tó ṣiṣẹ́ ibi náà winá òfin.

Bákan náà ni wọ́n bá àwọn òbí, ẹbí àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ kẹ́dùn lórí àdánù náà, tí wọ́n sì ní wọn gbàgbọ́ pé ipa rẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ tó gbé dání kò ní parẹ́ láé.

Ikú rẹ̀ yìí ti wá ń fa awuyewuye lórí ayélujára, tí àwọn èèyàn sì ń bu ẹnu àtẹ́ lu bí ètò ààbò Nàìjíríà ṣe ti mẹ́hẹ tó.

Àwọn èèyàn kọminú lórí ayélujára

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

@Favour_Surge sọ pé ohun tó báni lọ́kàn jẹ́ jùlọ ni pé tí orílẹ̀ èdè yìí kó bá dára si, nǹkan ṣẹ̀ṣẹ̀ sí ní bàjẹ́ ni. Ìdigunjalè àti ìjínigbé yóò túnbọ̀ le si jù báyìí lọ. Bẹ́ẹ̀ si ni àwọn olórí wa kò bìkítà! Àwọn ọmọ wọn kò gbé ibí…, wọ́n sì ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò tó ń ṣọ́ wọn.

@sapaverdeadly ní tirẹ̀ kọ pé nígbà tí a bá ń bèèrè fún ìṣèjọba tó dára, èyí rí bẹ́ẹ̀ nítorí à ń fẹ́ orílẹ̀ èdè tó máa ṣiṣẹ́ fún àwọn olówó àti tálákà. Àmọ́ nǹkan tí ìṣèjọba ìmọtara ẹni nìkan ló ń fà rèé. Tí kò bá sí ààbò ní olú ìlú orílẹ̀ èdè, níbo w ani ààbò fẹ́ wà? Agbẹjọ́rò tó dáńtọ́ míì tún ti lọ kíákíá. Ó ṣe.

@Smartek2050 Àwọn ọlọ́pàá ń ṣe ìwádìí nígbà tí ẹbí ń ṣe ìdárò – èyí ni ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ ní Nàìjíríà. Ta ni a máa pè nígbà tí orílẹ̀ èdè gangan bá ṣubú?

@Shadowwwalker1 Àdánù ńlá lèyìí… ẹ̀mí ọ̀dọ́ ni wọ́n tún gé kúrú nítorí àìsí ètò ààbò tó péye. Olú ìlú orílẹ̀ èdè tí kò sí ààbò fún àwọn èèyàn. Kí Ọlọ́run rọ àwọn ẹbí rẹ̀, Arise TV lójú.

Ìdigunjalè ní ìlú Abuja

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìlú Abuja ti fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ ikú obìnrin náà múlẹ̀, tí wọ́n sì ní ìwádìí ti bẹ̀rẹ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

Agbẹnusọ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Abuja, Josephine Adeh sọ pé àwọn ti gbọ́ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ náà àti pé ìwádìí ti ń lọ.

Ìṣẹ̀lẹ̀ ìdigunjalè ní ìlú Abuja ti di ohun tó ń fi peléke si lẹ́nu ọjọ́ díẹ̀ sẹ́yìn báyìí.

Ní ọjọ́rú, ọ̀sẹ̀ tó kọjá ni iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Abuja nawọ́ gán àwọn mẹ́rin kan fẹ́sùn ìdigunjalè àti pé wọ́n lọ́wọ́ nínú ikú ọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Bashir Dauda.

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní ọwọ́ tẹ àwọn èèyàn náà láàárín ọjọ́ Kẹta sí ọjọ́ Kọkàndínlógún oṣù Kẹsàn-án.

Bákan náà ni àwọn afurasí kan adigunjalè kan ṣe ìkọlù sí ilé ìgbé Efab Global Estate ní agbègbè Idu Industrial Area ní Abuja níbi tí àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò márùn-ún ti farapa, tí wọ́n sì ja ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilé lólè.