Ìjọba àpapọ̀ sanwó àwọn Káńsù sí àpò àwọn alága ẹgbẹ́ APC, ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ àti ìjọba Osun fárígá

Oríṣun àwòrán, PDP/APC/Ademola Adeleke/X
Ilé ẹjọ́ gíga ìpínlẹ̀ Oyo ti pàṣẹ pé kí ilé ìfowópamọ́ United Bank of Africa, UBA kò gbọdọ̀ san owó àwọn ìjọba ìbílẹ̀ tí wọ́n fẹ̀sùn kàn pé ìjọba àpapọ̀ san sí akoto owó àwọn alága ìjọba ìbílẹ̀ tí wọ́n dìbò yàn lábẹ́ ìṣèjọb ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress ní ìpínlẹ̀ náà lọ́dún 2022.
Ní ọjọ́ Ẹtì, ọjọ́ Kẹrìndínlọ́gbọ̀n, oṣù Kẹsàn-án, ọdún 2025 ni ìjọba ìpínlẹ̀ Osun gba ilé ẹjọ́ lọ lẹ́yìn tí ìròyìn gbòde pé ìjọba àpapọ̀ tis an owó oṣù mẹ́fà àwọn ìbílẹ̀ èyí tí wọ́n ti gbẹ́sẹ̀ lé láti inú oṣù Kejì ọdún yìí.
Agbẹjọ́rò àgbà ìpínlẹ̀ Osun àti iléeṣẹ́ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ àwọn ìjọba ìbílẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Osun ló pe ẹjọ́ náà nígbà tí wọ́n ń gbọ́ pé ìjọba àpapọ̀ yóò san owó náà láti ri pé wọ́n kò rí owó náà gbà jáde lẹ́yìn tí ìjọba san owó ọ̀hún.
Ìjọba ìpínlẹ̀ Osun nínú ẹjọ́ náà rọ ilé ẹjọ́ láti pàṣẹ fún ilé ìfowópamọ́ UBA láti má jẹ̀ ẹ́ kí àwọn alága lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú UBA rí owó náà gbà jáde títí ti ìgbẹ́jọ́ tó ń lọ nílé ẹjọ́ fi máa parí.
Adájọ́ A. L. Akintola tó gbọ́ ẹjọ́ náà bu àṣẹ lù ú pé kí ilé ìfowópamọ́ má fùn-ún àwọn alága náà ní owó títí tí ìgbẹ́jọ́ fi máa wá sópin.
Kí ló dé tí ìjọba ìpínlẹ̀ Osun fi gba ilé ẹjọ́ lọ láti dènà fífún àwọn alága lówó?
Níṣe ni ìfaǹfà tó ń wáyé láàárín ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress, APC àti Peoples Democratic Party, PDP ní ìpínlẹ̀ Osun lórí ọ̀rọ̀ ìjọba ìbílẹ̀ ti tún gba ọ̀nà míì yọ.
Èyí kò ṣẹ̀yìn bí ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ṣe ń fẹ̀sùn kàn pé àpò àwọn aládàni ni ìjọba àpapọ̀ san owó oṣù mẹ́fà tó jẹ́ owó àwọn ìjọba ìbílẹ̀ náà sí.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹgbẹ́ òṣèlú APC ní ìpínlẹ̀ Osun ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé lóòótọ́ ni ìjọba àpapọ̀ ti san owó náà, wọ́n jiyàn pé kìí ṣe akoto owó àwọn alága ìjọba ìbílẹ̀ tí wọ́n dìbò yàn lábẹ́ àsíá ẹgbẹ́ òṣèlú APC ní ọdún 2022 ni ìjọba àpapọ̀ sanwó náà sí.
APC Osun ní àpò akoto owó àwọn ìjọba ìbílẹ̀ ni ìjọba àpapọ̀ san owó náà sí.
Àmọ́, ẹgbẹ́ òṣèlú PDP tó jẹ́ ẹgbk tó ń ṣe ìjọba ní ìpínlẹ̀ Osun sọ pé àwọn kò mọ nǹkankan nípa owó náà, tí wọ́n sì ń sọ fún ẹgbẹ́ òṣèlú APC láti kéde akoto tí ìjọba àpapọ̀ san owó ọ̀hún sí.
PDP ní ó jẹ́ ohun ìyàlẹ́nu pé ìjọba àpapọ̀ máa san owó sí akoto tí olùṣirò àgbà àgbà ìpínlẹ̀ náà àti olùyẹ̀wé owó wò fún ìjọba ìbílẹ̀ àti iléeṣẹ́ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ ìjọba ìbílẹ̀ kò mọ nǹkankan nípa rẹ̀.
Alága ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ní ìpínlẹ̀ Osun, Sunday Bisi sọ fún BBC News Yorùbá ní òwúrọ̀ ọjọ́ Ajé, ọjọ́ Kọkàndínlọ́gbọ̀n, oṣù Kẹsàn-án pé, láti ọjọ́ mélòó kan sẹ́yìn ni àwọn ti ń gbọ́ pé ààrẹ Nàìjíríà, Bola Tinubu ti pàṣẹ pé kí wọ́n san owó àwọn ìjọba ìbílẹ̀ tí ìjọba ti gbẹ́sẹ̀ lé láti oṣù Kejì ọdún.
Bisi ní àwọn gbọ́ pé wọ́n fún alága tó jẹ́ ti ẹgbẹ́ òṣèlú APC láti lọ ṣí akoto owó míì dípò ti akoto owó tó ti wà nílẹ̀ tẹ́lẹ̀.
Ó ní Ọjọ́bọ̀ ni àwọn ti ń gbọ́ pé wọ́n fẹ san owó náà, tí wọ́n sì ti san-án fún wọn èyí tó mú kí àwọn gba ilé ẹjọ́ lọ láti lè ṣe ìdádúró àwọn alága náà láti dènà wọn láti máa ná owó aráàlú.
Ó wòye pé àwọn tí kò tọ̀nà ni owó náà bọ́ sí lọ́wọ́ nítorí abẹ́ ìjọba ìpínlẹ̀ ni gbogbo àwọn tó ń ṣe àkóso ìjọba ìbílẹ̀ wà èyí tó wà lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP.
"Àpò ìjọba ìpínlẹ̀ ni wọ́n máa ń san owó ìjọba ìbílẹ̀ sí káàkiri Nàìjíríà, kò sí ibi tí wọ́n ti máa ń san-án sí àpò ìjọba ìbílẹ̀ tààrà, èyí ni àkọ́kọ́.
"Àwọn alága ìjọba ìbílẹ̀ tí ìjọba àpapọ̀ san owó fún ni wọ́n kò tọ̀nà lábẹ́ òfin nítorí ilé ẹjọ́ gíga ní ìlú Osogbo àti ilé ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn ní Akure, ìpínlẹ̀ Ondo ti lé wọn kúrò nípò."
Alága náà ní títí di àsìkò yìí, àwọn alága ọ̀hún kò pe ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn lọ sí ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ èyí tó túmọ̀ sí pé wọn kò sí ní ìjọba lábẹ́ òfin.
Sísan owó ìjọba ìbílẹ̀ sí àpò akoto owó aládàni àti àpò àwọn olóṣèlú jẹ́ ìwà ọ̀daràn sáwọn èèyàn ìpínlẹ̀ Osun - NULGE
Ìfaǹfà yìí ló ń wáyé lẹ́yìn tí ẹgbẹ́ àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba ìbílẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Osun ìyẹn National Union of Local Government Employees, NULGE tẹ̀ka ìpínlẹ̀ Osun fẹ̀sùn kan ìjọba àpapọ̀ pé wọ́n san owó ìjọba ìbílẹ̀ sí àpò ẹgbẹ́ òṣèlú APC.
Alága NULGE, Dókítà Nathaniel Ogungbangbe sọ pé àwọn rí àrídájú rẹ̀ pé ìjọba àpapọ̀ san owó ìjọba ìbílẹ̀ láti oṣù Kẹta sí oṣù Kẹjọ sí akoto owó táwọn alága àti káhúnsílọ̀ ìjọba ìbílẹ̀ ẹgbẹ́ òṣèlú APC ṣí lọ́nà àìtọ́ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹjọ́ náà wà nílé ẹjọ́.
Ogungbangbe fẹ̀sùn kan Mínísítà fún ètò ìsúná, Wale Edun, Olùṣirò àgbà Nàìjíríà, Babatunde Ogunjimi àti Agbẹjọ́rò àgbà Nàìjíríà, Lateef Fagbemi, pé wọ́n ń ṣi ọ́fíìsì wọn lò nípa sísan owó náà.
Ó ní ìgbésẹ̀ náà jẹ́ ohun tó báni lẹ́rù, tó sì nílò kí àwọn pariwo rẹ̀ fún aráyé.
"Sísan owó ìjọba ìbílẹ̀ sí àpò akoto owó aládàni àti àpò àwọn olóṣèlú jẹ́ ohun tó yani lẹ́nu gidi, ohun tí kò ṣẹlẹ̀ rí nínú ìtàn ìṣèjọba Nàìjíríà."
Ó sọ pé ilé ẹjọ́ gíga kan ti ṣáájú dájọ́ lọ́jọ́ Kẹẹ̀dógún, oṣù Karùn-ún, ọdún 2025 pé kí gbogbo nǹkan ṣì wà bó ṣe wà ná tí wọ́n fi máa parí ìgbẹ́jọ́ nílé ẹjọ́ èyí tí wọ́n ní ó ṣokùnfà ìdí tí ilé ìfowópamọ́ àgbà Nàìjíríà kò ṣe san owó ọ̀hún láti oṣù Kẹta.
Ó wòye pé Agbẹjọ́rò àgbà Nàìjíríà kò lè máa ṣe iṣẹ́ ilé ẹjọ́ tó ga jù lọ nípa gbígbé ìdájọ́ ilé ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn tì.
Bákan náà ló fẹ̀sùn kan ẹgbẹ́ òṣèlú APC pé wọ́n fẹ́ da omo àlááfíà ìlú náà rú.
"Ohun tí wọ́n ń gbìyànjú láti ṣe ni láti da omi àlááfíà ìlú rú, kí ààrẹ Nàìjíríà le kéde ìlú ò fararọ ní ìpínlẹ̀ Osun, kí wọ́n ba à le kó owó ìlú jẹ."
Ó fi kun pé àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba ìílẹ̀ kò ní padà sí ẹnu iṣẹ́ àyàfi tí wọ́n bá parí gbogbo aáwọ̀ tó wà nílẹ̀ náà.
APC àti PDP sọ òkò ọ̀rọ̀ lu ara wọn
Ẹgbẹ́ òṣèlú APC ti wá jiyàn gbogbo àwọn ẹ̀sùn yìí, bí wọ́n ṣe ni irọ́ tó jìnà sí òótọ́ ni àti pé alága NULGE ń sọ àwọn ọ̀rọ̀ náà láti tàbùkù àwọn, àti láti pọ́n ìjọba tó wà lórí ipò lé ni.
Àtẹ̀jáde kan tí agbẹnusọ ẹgbẹ́ APC, Kola Olabisi fi síta sọ pé irọ́ ni ìròyìn pé koto owó àwọn aládàni ni ìjọba àpapọ̀ san owó sí.
Ó ní àpò owó ìjọba ìbílẹ̀ ni wọ́n san owó náà sí.
Olabisi fẹ̀sùn kan NULGE pé ìmọ̀tara ẹni nìkan ni wọ́n ń bá kiri ló jẹ́ kí wọ́n sọ ara wọn di agbẹnusọ fún Gómìnà Ademola Adeleke.
Ó wá rọ àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò láti wà ní ojúlalákàn fi ń ṣọ́rí nítorí tí wọ́n bá fẹ́ dá wàhálà sílẹ̀.
Ẹ̀wẹ̀, ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ní nígbà tí APC ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé owó ti wà ní àkàtà àwọn, APC gbọdọ̀ ṣàfihàn àwọn akoto tí ìjọba san owọ náà sí àtàwọn tí wọ́n le gba owó náà jáde.
Àtẹ̀jáde tí alága ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ní ìpínlẹ̀ Osun, Sunday Bisi fi léde lọ́jọ́ Àìkú sọ pé sísan owó náà fáwọn alága tí ilé ẹjọ́ ti lé kúrò lórí ipò dàbí híhu ìwà ọ̀daràn sáwọn èèyàn ìpínlẹ̀ Osun.
Ó ní dípò tí wọ́n ṣe ń bu ẹnu àtẹ́ lu ẹgbẹ́ NULGE, ó yẹ kí wọ́n wẹ ara wọn mọ́ nípa sísọ akoto ti owó náà wà àti iye tó wà níbẹ̀ ni.
"À ń fẹ́ kí wọ́n sọ ibi tí owó náà wà nítorí gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ tó yẹ kó mọ̀ nípa owó àwọn ìjọba ìbílẹ̀ ọgbọ̀n tó wà ní ìpínlẹ̀ Osun ni wọn kò nǹkankan nípa owó náà. Àwọn òṣìṣẹ́ yìí ló ń ṣe àmójútó gbogbo àwọn akoto owó ìjọba ìbílẹ̀.
"Kò sí ẹnikẹ́ni nínú àwọn olùṣirò àgbà fún ìpínlẹ̀ Osun, ìjọba ìbílẹ̀ àti iléeṣẹ́ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ ìjọba ìbílẹ̀ tó mo nǹkankan nípa bí owó náà ṣe rìn."
Kí ló fa aáwọ̀ ìjọba ìbílẹ̀ ní Osun?
Gómìnà àná ní ìpínlẹ̀ Osun lábẹ́ àsíá ẹgbẹ́ òṣèlú APC, Gboyega Oyetola ló ṣètò ìdìbò sáwọn ìjọba ìbílẹ̀ nígbà tó kù díẹ̀ kí sáà rẹ̀ kógbá wọlé lọ́dún 2022.
Ẹgbẹ́ òṣèlú PDP gba ilé ẹjọ́ lọ nígbà náà láti tako ìgbésẹ̀ náà bí Gómìnà Ademola Adeleke ṣe gba ipò lọ́wọ́ Oyetola, tó sì júwe ilé fún àwọn alága ọ̀hún ni kété tí wọ́n búra wọlé fún un tán.
Bákan náà ni ilé ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn gbé ìdájọ́ kalẹ̀ lórí ẹjọ́ tí ẹgbẹ́ òṣèlú PDP pè tako àwọn alága ìjọba ìbílẹ̀ tí Oyetola ṣètò ìdìbò náà fún.
Ilé ejọ́ Kòtẹ́milọ́rùn náà ní ìgbésẹ̀ láti dpibò yan àwọn alága káńsù ọ̀hún kò tọ̀nà lábẹ́ òfin.
Gómìnà Ademola Adeleke ṣètò ìdìbò míì láti yan àwọn alága tuntun míì ṣùgbọ́n ẹgbẹ́ òṣèlú APC gba ilé ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn míì lọ tí ìdájọ́ sì wáyé lọ́jọ́ Kẹwàá , oṣù Keji, ọdún 2025.
Ìdájọ́ ilé ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn náà sì ló dá àwọn alága ìjọba ìbílẹ̀ tí gómìnà Oyetola ṣe ètò ìdìbò wọn padà sípò.
Láti ìgbà náà ni wàhálà àti rògbòdìyàn ti bá ẹgbẹ́ ]oṣèlú APC àti PDP ní ìpínlẹ̀ Osun èyí tó ṣokùnfà ikú èèyàn méje.
Èyí ló fà á tí wọ́n fi gbé àwọn ilẹ̀kùn àwọn káńsù náà tì pa.
Àwọn òṣìṣẹ́ láwọn ìjọba ìbílẹ̀ kò lè lọ síbi iṣẹ́, tí ìjọba àpapọ̀ náà sì gbé ẹsẹ̀ lé àwọn àwọn owó oṣooṣù tó tọ̀ sí àwọn káńsù náà.















