Mọ̀ nípa àǹfààní márùn-ún tó wà lára ọsàn wẹ́wẹ́

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Bi ọsan wẹwẹ ko tilẹ ṣee mu bii ọsan gidi, sibẹ gbajumọ loun naa lawujọ awọn ọsan yoku, nitori anfaani ilera to si ni, ni.
Gẹgẹ bi a ṣe mọ, ọsan wẹwẹ naa ni awọn mi-in n pe ni orombo tabi ọsan wẹẹrẹ. Loootọ lo kere loju, amọ awọn onimọ nipa rẹ fi ye wa pe eso kan to kun fun anfaani ilera pupọ ni.
Eroja ti a mọ si Calory ko fi bẹẹ pọ ninu ọsan wẹwẹ, ṣugbọn eyi ti a mọ si Vitamin C, pọ ninu rẹ gidi.
Ọsan orombo kun fun eroja Fiber pẹlu, ati awọn eroja meji kan ti a mọ si flavonoids ati limonene.
Ida 88% ninu Vitamin C ti eeyan nilo lojumọ lo wa ninu ọsan wẹwẹ bi awọn dokita ṣe fidi ẹ mulẹ.
Koda, ti a ba gbe e le ori iwọn, iye odiwọn Vitamin C to wa ninu
ọsan gidi lo fẹrẹ wa ninu ọsan wẹwẹ naa.
Dokita onimọ nipa ounjẹ lati ilu Kano, Aisha Bala Ahmad, ṣalaye fun BBC pe awọn ọsan orombo kan wa ti wọn n ṣiṣẹ ale (ti ara wọn yoo maa dide) fun ọkunrin.
"O maa n ran agbara ibalopọ lọwọ nipa mimu idọti kuro ninu ara."
Dokita Aisha Bala lo ṣalaye bẹẹ.
"Ọsàn wẹ́wẹ́ ń ran bí ẹ̀jẹ̀ ṣe ń rìn lára èèyàn lọ́wọ́''
*Gẹgẹ bi alaye ti Dokita Aisha Bala ṣe, eroja Vitamin C to pọ ninu ọsan wẹwẹ maa n ran bi ẹjẹ ṣe n rin kari ara eeyan lọwọ.
O ni o maa n din ko maa rẹ eeyan ku.
Ọsan wẹwẹ maa n ran awọn ṣọja ara lọwọ: Vitamin C to pọ ninu ọsan wẹwẹ maa n ran awọn ṣọja aronilagbara lara eeyan lọwọ, o si tun maa n koju otutu ati kokoro àyà.
Ara to jọlọ to si n dan: Bi Dokita ṣe wi, Vitamin C yii kan naa lo n pese eroja collagen to n mu ara dan, eyi yoo maa din bi ara eeyan ṣe n hunjọ ku.
Bakan naa lo wulo fun ki àpá kuro lara, ati ki awọ ara mọlẹ kedere.
Ọsan wẹwẹ n ran bi ounjẹ ṣe n da ninu wa lọwọ:
Bi o ba mu omi ọsan wẹwẹ to lọ wọọrọ, o le mu ki inu rẹ to kun lọ silẹ, o si le jẹ ki o ṣe igbọnsẹ wọọrọ lẹyin airi igbọnsẹ ṣe.
O n dena ki eeyan ni aisan kindinrin: Oriṣi aisan kan to maa n da kindinrin eeyan laamu ni a mọ si Kidney stone.
Bi eeyan ba n mu omi ọsan wẹwẹ, eroja citric acid to wa ninu rẹ yoo dara pọ mọ calcium, wọn yoo si jọ gbogun ti okuta kindinrin to ba fẹẹ ṣẹyọ .
*O maa n ran ounjẹ lọwọ lati dapọ mọ ẹjẹ, yoo jẹ ki eroja Iron wọle sara, eyi yoo si dena aito ẹjẹ. (Anemia).
Àtúpalẹ̀ ọsàn wẹ́wẹ́ onigiraamu ọgọrun-un(100g) tí wọn kò tí ì bó èèpo ara rẹ̀
Calories: ~29 kcal
Water: ~89%
Carbohydrates: ~9.3 g
Sugars: ~2.5 g
Fiber: ~2.8 g
Protein: ~1.1 g
Fat: ~0.3 g
Vitamin C: ~53 mg (89% RDA)
Vitamin B6: ~0.08 mg
Potassium: ~138 mg
Folate (B9): ~11 g
Citric acid: ~5–8% (main acid)
Ìkìlọ̀
Awọn onimọ sọ pe eroja asiidi pọ ninu ọsan wẹwẹ, o si le fa iṣoro fun eyin ẹnu eeyan.
Fun idi eyi, awọn to ba n mu ọsan wẹwẹ deede gbọdọ ri i pe wọn n da aabo bo eyin wọn daadaa.
Wọn fi kun un pe mimu ọsan wẹwẹ gba ọgbọn, eeyan ko gbọdọ deede sọ ọ di omi ti yoo maa mu bo ṣe wu u.
Awọn dokita sọ pe kawọn eeyan ri i daju pe ilana ti anfaani ọsan naa ko fi ni i di wahala si wọn lọrun ni wọn n lo lati fi mu un fun ilera pipe.














