Wo orílẹ̀èdè méjì nílẹ̀ Africa tí kò faramọ́ ìdádúro Palestine gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀èdè

Oríṣun àwòrán, Getty Images
- Author, Marina Daras
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4
Lẹ́yìn tí àwọn orílẹ̀ èdè UK, Canada àti Australia kéde láìpẹ́ yìí pé àwọn gba Palestine gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀ èdè, ìrètí wà pé ọ̀pọ̀ orílẹ̀ èdè náà ni yóò ṣe bẹ́ẹ̀.
Àmọ́ báwo ni àwọn orílẹ̀ èdè Afric ṣe ń rí Palestine?
Ọ̀pọ̀ orílẹ̀ èdè ní ẹkùn Africa ni ó rí Palestine ní orílẹ̀ èdè lọ́dún 1980 lẹ́yìn tí olórí orílẹ̀ náà Yasser Arafat kéde òmìnira ní Algiers.
Kódà àwọn olórí orílẹ̀ èdè kan ní Africa bíi Thomas Sankara àti Nelson Mandela ṣe àfiwé ìjà òmìnira Palestine sí ti ilẹ̀ Africa.
Àmọ́ àwọn orílẹ̀ èdè méjì kan – Cameroon àti Eritrea – dá yàtọ̀.
A ṣe àgbéyẹ̀wò ìdí tí èyí fi rí bẹ́ẹ̀.
Cameroon

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Cameroon, tó jẹ́ orílẹ̀ èdè lẹ́kùn ìwọ̀ oòrùn Africa ní àjọṣepọ̀ tó lágbára pẹ̀lú Israel.
David Otto, Adarí ẹ̀ka ààbò ní Geneva Centre for African Security and Strategic Studies sọ pé Israel rí Cameroon bíi ọ̀kan lára àwọn orílẹ̀ èdè tó ní àjọṣepọ̀ tó lòòrìn pẹ̀lú ní Africa.
"Cameroon kò lè ṣe ohunkóhun láti bá àjọṣepọ̀ tó ni pẹ̀lú Israel jẹ́," Otto sọ.
Ó ní àjọṣepọ̀ to wà láàárín àwọn orílẹ̀ èdè jẹ́ èyí tó níiṣe pẹ̀lú ètò ààbò.
"Israel ti ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀, tó sì tún ń tẹ̀síwájú láti máa dá ààbò bo ìṣèjọba Cameroon."
Israel máa ń ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ fáwọn ẹ̀ṣọ́ iléeṣẹ́ ológun àtàwọn ẹ̀ka kan èyí tó máa ń rí sí ààbò ààrẹ Cameroon.
"Ìbáṣepọ̀ tí Cameroon ti ní pẹ̀lú Israel ti ṣe atọ́nà fún Cameroon láti ní ìbáṣepọ̀ àti àtìlẹyìn orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà èyí tó jẹ́ ọ̀rẹ́ pẹ̀lú Israel."
Ipò Cameroon lórí Palestine tún le jẹ́ lára ìrírí èyí tí orílẹ̀ èdè náà ní pẹ̀lú ẹkùn tí wọ́n ti ń sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì ní orílẹ̀ èdè náà.
"Gbígba Palsetine gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀ èdè le mú kí àwọn èèyàn ní Cameroon pè fún pé kí àwọn náà fi ààyè gba àwọn tó fẹ́ yapa kúrò ní orílẹ̀ èdè náà. Ìjọba Cameroon sì ti máa ń sọ pé ọ̀kan ni orílẹ̀ èdè Cameroon, tí kò sì sí ààyè fún ìpínyà rárá," Otto sọ.
Níṣe ni Cameroon kìí sọ ohunkóhun lórí ọ̀rọ̀ Palestine.
Eritrea ní tirẹ̀ ní ìtàn tó yàtọ̀ sí ti Cameroon pátápátá.
Eritrea

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ní ọdún 1988, nígbà tí Yasser Arafat kéde Palestine gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀ èdè tó ti dá dúró, ó nílò àtìlẹyìn àwọn orílẹ̀ èdè Africa.
Ọ̀kan lára wọn ni Ethiopia.
"Ethiopia ní Addis Ababa ni oríkò àjọ ilẹ̀ Africa nígbà náà," gẹ́gẹ́ bí onímọ̀ nípa òṣèlú Abdurahman Sayed ṣe sọ.
"Ìjọba ológun tó wà ní Ethiopia nígbà náà jẹ́ èyí tó faramọ́ Soviet, tó sì ń ṣe àtìlẹyìn fún ẹ̀tọ́ àti ìjà tí Palestine ń jà."
Àmọ́ Eritrea nígbà náà ń jà fún òmìnira tirẹ̀ kúrò lọ́wọ́ Ethiopia.
"Ohun tó fojú hà nígbà náà ni pé Ethiopia ń jẹ gàba lé Ethiopia tí àwọn Eritrea sì ń bá Ethiopia jagun.
"Kí Palestine tó lè ní ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú Ethiopia, wọ́n nílò láti sún fún Eritrea, tó sì jk ohun tí Yasser Arafat ṣe èyí tí kò dùn mọ́ àwọn Eritrea nínú rárá tó fi mọ́ ààrẹ tó wà lórí ipò báyìí.
Síbẹ̀, Ààrẹ Eritrea, Isaias Afwerki ti fi ojú àánú hàn sí ìjà Palestine bó ṣe dìbò fún-un níbi ètò àjọ ìṣọ̀kan àgbáyé kan lọ́dún 2012.
Àmọ́, ó tún da ìpè fún àlááfíà ti Oslo ọdún 1993 npu bí ó ṣe júwe ìfẹnukò náà bí èyí tí kò dára tó máa fún Palestine ní agbára láti máa ṣe àkóso lára ẹkùn West Bank àti Gaza gẹ́gẹ́ bí atọ́nà sí ṣíṣe àkóso ìjọba ara rẹ̀.
Ààrẹ Afwerki ní òun kò faramọ́ ìjọba olójú méjì.
Ṣùgbọ́ ó ṣeéṣe kó rí àwọn ìfàsẹ́yìn kan láti orílẹ̀ èdè rẹ̀ nítorí ìdá 55% àwọn èèyàn rẹ̀ ló jẹ́ Mùsùlùmí.
"Eritrea wáyé látara bí ó ṣe jà fúnra rẹ̀. Fún ẹni tó ṣáájú ogun láti jà fún òmìnira rẹ̀ láti má ṣe àtìlẹyìn fún òmìnira àwọn míì rí bákan," Sayed sọ.
BBC kàn sí àwọn ìjọba méjéèjì láti sọ ti wọn àmọ́ wọn kò dáhùn.














