Àdínkù bá owó Hajj, wo iye tí Alálàájì kan yóò san lọ sí Mecca ní 2026

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ajọ NAHCON to n ṣakoso eto awọn eeyan to n rinrin ajo lọ silẹ mimọ niluu Mecca lati orilẹede Naijiria, ti kede iye owo tawọn alalaaji yoo san fun iṣẹ Hajj lọdun 2026.
Owo Hajj ọdun 2026 yii din diẹ si iye tawọn to rinrin ajo lọ si Mecca lọdun yii san.
Alaga ajọ naa, Ọjọgbọn Abdullahi Salleh Usman, to fidi ọrọ yii mulẹ fun BBC lati ilu Mecca sọ pe ajọ NAHCON kede owo tawọn alalaaji yoo san fun irinajo lọ si Mecca lọdun to n bọ, lẹyin ti ijọba apapọ buwọlu iye owo naa.
Ọjọgbọn Usman sọ pe ẹkun ti eeyan ba ti wá, lo maa sọ iye ti yoo san fun owo Hajj ọdun 2026.
Ọjọgbọn Usman ni awọn to ba fẹ lọ fun Hajj lati ẹkun Maiduguri/Yola, ti ipinlẹ Yobe, Borno, Adamawa ati Taraba wa labẹ rẹ, yoo san miliọnu mẹ́jọ Naira ó le díẹ̀ (₦8,118,333.67) fun Hajj ọdun to n bọ dipo ₦8,327,125.57 naira ti wọn san lọdun 2025.
Adinku ₦208,791.92 lo ba iye tawọn eeyan yoo san lati ẹkun naa fun iṣẹ Hajj ọdun 2026.
Alaga ajọ igbimọ NAHCON fikun ọrọ rẹ wi pe, awọn alalaaji lati awọn ipinlẹ mii lẹkun ariwa Naijiria ti wọn san 8,457,685.59 miliọnu Naira ni èsín, yoo san 8,244,813.67 bayii.
Adinku 212,871.92 naira ni yoo ba iye owo ti wọn san fun iṣẹ Hajj ti ọdun yii si ti ọdun to n bọ.
Bakan naa ni alaga ajọ NAHCON tun kede wi pe awọn alalaaji lati ẹkun guusu Naijiria, ti wọn san 8,784,085.59 milionu naira lọdun yii yoo san 8,561,013.67 lọdun to n bọ.
Eyi tumọ si pe adinku 223,071.92 ni yoo ba owo ti wọn maa san.
"Ìdí rèé tí adinku fi bá owó Hajj ni 2026"
Ọjọgbọn Usman ni idi meji ni adinku fi ba owo awọn alalaaji fọdun 2026.
''Idi akọkọ ni pe a ko fẹ kawọn arinrinajo si Hajj lati Naijiria ni inira rara.
A ti ri ẹdinwo diẹ gba sii lati Misha'r, 4,770 riyal ni a maa n san tẹlẹ.
A gbiyanju lọdun to lọ lati ri i pe adinku 720 riyal ba owo ti alalaaja kọọkan san fun iṣẹ Hajj.
A tun ti ri ẹdinwo 150 riyal gba sii lọdun yii, 3,900 riyal lawọn alalaaji wa yoo san bayii dipo 4,770 riyal ti a maa n san tẹlẹ.
Idi keji ni pe ₦1,600 ni pasipaarọ owo Naira si dọla kan lọdun to lọ, ṣugbọn ₦1,550 ni Naira si dọla kan bayii,'' Ọjọgbọn Usman ṣalaye.
Nigba wo ni opin yoo de ba sisan owo Hajj fọdun 2026?
Nigba to n sọrọ lori igba tawọn eeyan ko ni lanfaani mọ lati sanwo fun irinajo Hajj fọdun 2026, Ọjọgbọn Usman sọ pe o ṣe pataki fawọn to ba fẹ lọ Hajj lati mọ pe wọn ni lati tete san owo Hajj wọn.
Alaga ajọ NAHCON ni ọjọ kọkanlelọgbọn oṣu Kejila ọdun yii ni ajọ naa ko ni gba owo Hajj ọdun 2026 mọ.
O ni igbesẹ yii waye lẹyin ti ijọba orilẹede Saudi Arabia kede awọn alakalẹ tuntun lori titete sanwo Hajj.















