Ìdí tí ìjọba Eko ṣe fún àwọn oníṣòwò Computer Village ní ọdún kan àbọ̀ láti fi ọjà náà sílẹ̀

Ẹnu ọna abawọle ọja Computer Village ni Ikeja, nipinlẹ Eko

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ijọba ipinlẹ Eko ti fun awọn oniṣowo to wa ni Computer Village ni Ikeja ni ọdun kan kan abọ lati fi agbegbe naa silẹ lọ si Katangowa, to wa ni ijọba ibilẹ Agbado/Oke-Odo.

Akọwe ileesẹ to n ri si ọrọ aato ilu ati idagbasoke awujọ nipinlẹ naa, Gbolahan Oki, lo sọ ọrọ ọhun di mimọ nibi ipade kan to sẹ pẹlu awọn onṣowo naa atawọn adari wọn.

O sọ fun wọn pe "Ijọba n fẹ ifọwọsowọpọ yin lati ri daju pe a ṣe aṣeyọri ninu igbiyanju wa lato gbe ọja yii lọ ibi ti ijọba ti pese silẹ.

"Akoko ti to lati gbe igbesẹ yii, oṣu mejidinlogun pere si ni o wa fun wa lati ṣe eyii."

Oki sọ pe ijọba ti ṣe gbogbo ohun to yẹ lati ri pe ibi ti ijọba n ko awọn eeyan naa lọ rọrun fun wọn lati ṣowo.

Idi ti ijọba fẹ fi gbe ọja naa kuro nibi to wa

O ṣalaye pe ile gbigbe ni agbegbe Computer Village ti wọn wa bayii wa fun ṣaaju amọ awọn eeyan ti sọ agbegbe naa di ile itaja lati ọpọ ọdun sẹyin lai gba aṣẹ lọwọ ijọba.

Ninu alaye rẹ, o ni lati ọdun 2006 ni ijọba ti bẹrẹ igbesẹ lati ko ọja ọhun kuro ni Ikeja amọ ko ṣeeṣe latari bi iṣẹ naa ṣe falẹ.

Gẹgẹ bii ohun to sọ, ipade oun pẹlu awọn oniṣọwo ọhun wa wa fun lati jẹ ki wọn lọwọ ninu eto kiko ọja naa lọ ibomii lai ṣe ohunkohun lẹyin wọn.

O sọ siwaju si pe "Gomina ko fi ọrọ idagbasoke ilu ṣere, o si fẹ ki gbogbo yin mọ nipa iṣipopada yii.

"Katangowa jẹ ibi ti ijọba yan latari pe yoo wulo fun ọja yii.

"Eeka ilẹ marundinlogun ni ilẹ naa, o si sunmọ gbogbo nnkan ti ẹ maa nilo fun owo yin lati tẹsiwaju owo yin."

Alakoso iṣipopada naa, Olayinka Bello, sọ pe ibi ti wọn n ko ọja naa lọ yoo ni awọn nnkan bii agọ ọlọpaa ati ile itura, yoo tun sunmọ agbegbe ti awọn oniṣowo yo ti maa wọ ọkọ BRT.

Ki lawọn oniṣowo Computer Village n sọ?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Nigba ti BBC Yoruba kan si olori awọn oniṣọwo ninu ọja naa to jẹ Baba Ọja Computer Village, Adeniyi Olasoji, o ni ọpọ iṣẹ lo wa nilẹ lati ṣe.

O sọ pe awọn kan faramọ igbesẹ naa, bẹẹ lawọn mii ko faramọ, eredi ree ti awọn fi gbe igbimọ dide lati ṣe oniruru ipade pẹlu awọn ti yoo kọ ọja tuntun naa fun lilo.

O ni "A maa wo bi ibomii ti wọn fun wa ṣe ri, ka wo eto abo to wa nibẹ... ki a wo boya ibi to ṣee lo fun wa ni tabi bẹẹ kọ, eredi ree ti mi o tii fi le fun awọn eeyan ni esi lọ titi.

"A ti wa lẹnu rẹ o ti pẹ, agbaṣeṣe ti wọn gbe ọja tuntun naa fun kẹyin ko le ṣe iṣẹ naa nitori banki kọ jalẹ lati fun lowo."

"A maa ṣe iwadii tiwa lori ibi ti a n lọ ki a to mọ igbeṣe ti a maa gbe.

"Ibi ti wọn n sọ yii wọn ko tii kọ nnkankan sibẹ, ko tii si nnkankan nibẹ.

"A ni lati kojo daadaa ki a gbe ọrọ naa yẹwo, to ba jẹ pe nnkan to ṣeeṣe ni tabi eyii ti ko ṣeeṣe, a maa jẹ ki awọn eeyan wa gbọ."

Lẹyin naa lo gba awọn oniṣowo ọja ọhun niyanju ki wọn lọ fọkan balẹ, ki wọn si ṣe suuru titi ti iwadii awọn lori ibi ti ijọba fun wọn yoo fi pari.