Owó tó tó ₦400m ni Ooni Ile Ife ń ná fọ́dún Ọlọ́jọ́ lọ́dọọdún! Ààfin Ooni fèsì sáwọn ọlọ́jà tó láwọn aṣojú Ooni ń fipá gbówó lọ́wọ́ àwọn

Ooni Ile Ife Ọba Adeyeye Ogunwusi ninu aṣọ funfun pẹlu awọ ẹkun lara aṣọ naa

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ninu atẹjade kan ti adari ati akọwe ẹgbẹ APTAN ẹka ti Ile Ife, Kọmureedi Saidi Adegoke ati Monsur Jimoh buwọlu, fi sita ni ẹgbẹ naa ti sọ pe awọn aṣoju aafin Ooni ọhun tun ji ọja awọn ọmọ ẹgbẹ awọn kan ko lọ.
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Awọn ontaja ati oniṣẹ ọwọ labẹ asia ẹgbẹ APTAN ni ilu Ile Ife ti ke gbajare pe awọn eeyan kan ti wọn lawọn wa lati aafin Ooni Ile Ife, Ọba Adeyeye Ogunwusi, n fipa gbowo lọwọ awọn fun ọdun Olojo.

Ninu atẹjade kan ti adari ati akọwe ẹgbẹ APTAN ẹka ti Ile Ife, Kọmureedi Saidi Adegoke ati Monsur Jimoh buwọlu, fi sita ni ẹgbẹ naa ti sọ pe awọn aṣoju aafin Ooni ọhun tun ji ọja awọn ọmọ ẹgbẹ awọn kan ko lọ.

Wọn wa ke pe ijọba apapọ ati ileeṣẹ ọlọpaa lati dasi ọrọ naa.

Ẹgbẹ APTAN ṣalaye ninu atẹjade ọhun pe ''lọjọ Iṣẹgun ọsẹ to kọja ni iṣẹlẹ ọhun waye ni Ọjatuntun Otisese niluu Ile Ife.

Ṣadeedee lawọn ọkunrin kan ti wọn sọ pe aafin Ooni lawọn ti wa yabo ọja wa, ti wọn si fi ipa ko ọja awọn ọmọ ẹgbẹ wa lọ.

Nigba tawọn ọmọ ẹgbẹ wa kọ lati san owo ti wọn n beere fun lawọn ọkunrin naa fi ipa ko ọja wọn lọ.

Fun bi ọdun marun un bayii lawọn eeyan yii ti n dunkoko mawọn ọmọ ẹgbẹ wa, ti wọn si n fi ipa ji ọja wọn ko lọ.

Koda, wọn ko da awọn ọja wa ti wọn ji ko lọ sẹyin pada, o si ti di ọdọọdun bayii ti iṣẹlẹ yii ti n waye.''

Ẹgbẹ APTAN ni ẹlẹsin musulumi lọpọ ọmọ ẹgbẹ awọn, eyi to tumọ si pe wọn o le maa dawo fun ajọdun ọdun ibilẹ to jẹ ẹsin abalaye.

Amọ, ẹgbẹ naa ko ṣai fidi rẹ mulẹ pe o ṣee ṣe ki Kabiyesi Ooni ma mọ nnkankan nipa awọn eeyan to n wa ji ọja awọn ọmọ ẹgbẹ APTAN ko lọdọọdun.

''Ooni ko mọ nnkankan nipa awọn to n beere owo lọwọ awọn ontaja fun ọdun Olojo''

Ẹwẹ, adari eto iroyin ni aafin Ooni Ile Ife, Oloye Moses Olafare, ti sọ fun BBC Yoruba wi pe Kabiyesi Ogunwusi ko ran ẹnikẹni lati lọ maa gbowo lọwọ awọn ontaja fun ọdun Olojo.

Oloye Olafare ni Kabiyesi n na owo to to ọdunrun un si irinwo miliọnu naira (N300m-N400m) lọdọọdun lori ọdun Olojo.

''Gbogbo owo tawọn ọmọ ẹgbẹ APTAN fẹ da ko le to miliọnu kan naira, eyi ti ko too fun eto iroyin lasan an gan an fun ọdun Olojo.

Nigba ti wọn lawọn mọ awọn eeyan yii, ni ṣe lo yẹ ki wọn fi ọlọpaa mu wọn.

Igbesẹ to yẹ ki wọn gbe niyẹn dipo awọn oniroyin ti wọn n sọrọ naa fun un,'' Oloye Olafare lo sọ bẹẹ.