Wo àwọn ọ̀nà tí yóò wà ní tìtì pa n'Ibadan lásìkò ìwúyè Ọba Rashidi Ladoja gẹ́gẹ́ bí Olubadan tuntun

Ọba Rashidi Ladoja ninu aṣọ ofin pẹlu fila abeti-aja

Oríṣun àwòrán, Other

Àkọlé àwòrán, Lanaa ọjọ Iṣẹgun ni igbimọ to n ri si eto aabo fun iwuye Ọba Ladoja fi atẹjade kan sita ninu eyi to ti kede awọn ọna kan ti yoo wa ni titi pa atawọn ọna mii tawọn onimọtọ le gba lọjọ Ẹti.
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Gbogbo eto lo ti to bayii fun iwuye Ọba Rashidi Adewolu Ladoja, gẹgẹ bi Olubadan ẹlẹẹkẹrinlelogoji lọjọ Ẹti ọsẹ yii ti i ṣe ọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu Kẹsan an.

Lanaa ọjọ Iṣẹgun ni igbimọ to n ri si eto aabo fun iwuye Ọba Ladoja fi atẹjade kan sita ninu eyi to ti kede awọn ọna kan ti yoo wa ni titi pa atawọn ọna mii tawọn onimọtọ le gba lọjọ Ẹti.

Ajọ naa ti aarẹ ẹgbẹ CCII tẹlẹ, Oloye Bayo Oyero, jẹ alaga rẹ sọ pe titi awọn ọna kan ṣe pataki tori Aarẹ Bola Tinubu n bọ wa sibi eto iwuye naa.

Awọn eto ti yoo waye ṣaaju iwuye Ọba Ladoja

Isin apapọ nilana ẹsin Kristẹni (Interdenominational service) ni wọn fi ṣide ayẹyẹ igbade naa lọjọ Aje ọsẹ yii, ọjọ kejilelogun, oṣu Kẹsan-an.

Aafin Olubadan to wa ni Oke Aremo, niluu Ibadan eto ọhun ti waye, ẹgbẹ CCII lo ṣagbatẹru rẹ.

Ọjọ Aṣa lo waye lọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kẹsan-an, eyi ti wọn gbe kalẹ pẹlu ajọṣepọ ileeṣẹ ijọba to n ri si Aṣa ati Irinajo afẹ nipinlẹ Oyo.

Lẹyin eyi ni wọn ṣe idanilẹkọọ lori igbade Olubadan. Agba onpitan, Ọjọgbọn Toyin Falola, lo ṣe idanilẹkọọ ọhun.

Ọjọbọ ni wọn ya sọtọ fun isin agbayanu, eyi ti yoo waye ni Civic Centre, Idi Ape, Ibadan.

Ọjọ Ẹti, ọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu Kẹsan-an gan-an ni Olubadan tuntun yoo gba ade ni Gbọngan Mapo bi wọn ṣe la a kalẹ.

Gẹgẹ bi Kọmiṣanna eto iroyin nipinlẹ Oyo ṣe wi nipa awọn aṣoju igbimọ Olubadan to wa nibi ipade ti wọn ti la eto yii kalẹ, o ni awọn alẹnulọrọ nipinlẹ naa ni.

Lara wọn ni: Awọn aṣoju Olubadan, Aṣipa Olubadan ti wọn yan sipo, Oba Hamidu Ajibade; Oloye Nureni Adisa ati Oloye Adeola Oloko to jẹ Akọwe iroyin fun Olubadan.

Awọn mi-in ni: Kọmiṣanna Aṣa ati Irinajo afẹ, ati ti eto awọn obinrin.

Awọn alaga ijọba ibilẹ Egbeda ati Guusu-Ila-Oorun Ibadan, awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin lati Guusu-Ila-Oorun Ibadan ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Gẹgẹ bii igbimọ naa ṣe ṣalaye, lati ago meje aarọ ọjọ Ẹti lawọn ọna naa yoo ti di titi pa.

Wọnyi ni awọn ọna ti yoo wa ni titi pa tori iwuye Ọba Ladoja gẹgẹ bi Olubadan tuntun lọjọ Ẹti:

  • Ọna akọkọ ti yoo wa ni titi pa ni orita Beere si gbọngan Mapo ti iwuye naa yoo ti waye.
  • Orita Born Photo si Oja'ba naa yoo wa ni titi pa.
  • Ọna miran ti yoo di titi pa lọjọ Ẹti ni orita Idi-Arere si Oja'ba.
  • Omii tun ni orita Itamerin si gbọngan Mapo.
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ẹwẹ, igbimọ to n ri si eto aabo fun eto iwuye naa ti ṣeto fun awọn ibikan tawọn alejo yoo gbe ọkọ si ki lilọ bibọ ọkọ le rọrun.

Ibi akọkọ tawọn alejo yoo lanfaani lati gbe ọkọ wọn si lọjọ Ẹti ni aye igbọkọsi ijọba ibilẹ Ariwa Ibadan lagbegbe Agodi.

Ibomiran ti wọn ya sọtọ fawọn alejo lati gbọkọ si ni papa iṣere to wa lẹgbẹẹ agọ ọlọpaa Yemetu.

Papa iṣere Liberty Stadium lagbegbe Oke Ado ni ibomiran ti wọn ti ya sọtọ fun ibi tawọn alejo yoo ri gbe ọkọ si lọjọ Ẹti.

Igbimọ naa tun sọ pe awọn ti pese awọn ọkọ ti yoo maa gbe awọn alejo to ni iwe ti wọn fi pe wọn dani lati ibi ti wọn gbe ọkọ wọn si lọ si gbọngan Mapo ti iwuye naa yoo ti waye.

Igbimọ naa wa rọ awọn olounjẹ atawọn ontaja mii lati de si gbọngan Mapo laarin ago mẹfa aarọ ọjọ Ẹti si ago meje ku Iṣẹju mẹẹdogun ki awọn ọna to di titi pa.

Igbimọ to n ri si eto abo fun eto iwuye Ọba Ladoja gẹgẹ bi Olubadan fikun ọrọ rẹ pe awọn ọkọ to ba tẹle Aarẹ Tinubu nikan ni yoo lanfaani lati gba awọn ọna ti yoo wa ni titi pa.