Iléeṣẹ̀ United Capital fojú àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ tó kú nínú ìjámbá ìná nílé gogoro Afriland hàn

Aworan awọn oloogbe ti padanu ẹmi wọn ninu iṣẹlẹ ijamba ina

Oríṣun àwòrán, X/Afriland

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ileeṣẹ United Capital ti kede iku awọn oṣiṣẹ rẹ mẹfa ti wọn padanu ẹmi wọn lasiko iṣẹlẹ ijamba ina ti waye ni Afriland Towers niluu Eko.

Iṣẹlẹ ijamba ina to gba ẹmi awọn eeyan yii waye ni Ọjọ Kẹrindinlogun, Oṣu Kẹsan-an ọdun 2025.

Ninu atẹjade ti wọn fi lede loju opo X, wọn kede orukọ awọn oloogbe naa; Jesutoni Shodipo, Kehinde Adeoye, Ndidi Osaemedike-Okeke, Olumide Oyefodunrin, Opeyemi Oloyede, ati Rebecca Adenuga.

Awọn alaṣẹ ileeṣẹ United Capital ṣapejuwe iṣẹlẹ naa gẹgẹ bii eyi to ba ni lọkan jẹ pupọ nitori ipa ribiribi ti awọn oloogbe ọhun n ko ninu idagbasoke ileeṣẹ naa.

"Pẹlu ibanujẹ ọkan ni a fi n kede ipapoda awọn oṣiṣẹ wa yii ti wọn padanu ẹmi wọn lasiko iṣẹlẹ ijamba ina to waye ni Afriland Towers.

"Iṣẹlẹ yii fi ọgba ọkan ti a ko le gbagbe si wa lọkan."

Bakan naa ni ileeṣẹ naa tun ransẹ ibanikẹdun si awọn mọlẹbi, ọrẹ ati eeyan awọn oloogbe naa, ti wọn si ṣe ileri lati tẹsiwaju ninu ṣiṣe iranlọwọ funwọn lasiko yii.

Wọn fikun pe awọn ti bẹrẹ igbaradi eto isinku awọn oloogbe ti yoo waye lati fi ranti ipa ti awọn oloogbe naa ko fun ileeṣẹ naa nigba ti wọn wa laye.

"Ki ọrun tẹ wọn si afẹfẹ rere, " Ileeṣẹ naa sọ.

Ki lo ṣẹlẹ ṣaaju?

Latari ina to jo nile alaja mẹjọ kan to wa lopopona Broad, Erekuṣu Eko, lọjọ Iṣẹgun ọsẹ yii, iroyin sọ pe ko din ni eeyan mẹwaa to ba iṣẹlẹ naa lọ.

Awọn to di oloogbe ninu ina to ṣẹyọ ni aja kẹta ati ikẹrin ile ti a mọ si Afriland Towers naa jẹ oṣiṣẹ ileeṣẹ United Capital to n ri si idokowo, ati ti ajọ Federal Inland Revenue Service (FIRS).

Iroyin sọ pe eeyan mẹfa ti wọn jẹ oṣiṣẹ ileeṣẹ United Capital ni ina yii pa, ajọ FIRS to n pawo wọle lorilẹede yii naa si fidi ẹ mulẹ nirọlẹ Ọjọru pe, mẹrin ninu awọn oṣiṣẹ oun ni ina ọhun pa.

Atẹjade ibanikẹdun ti ajọ yii fi sita, ṣalaye pe àjà kẹfa ati ikeje ile naa ni awọn oṣiṣẹ ẹka FIRS n lo fun ọfiisi.

Wọn ni nigba ti olobo ta awọn pe ina n jo nibẹ, kia ni awọn kan si ikọ alaabo ati ajọ panapana.