Ṣé lóòótọ́ ni Gómìnà Adeleke buwọ́lù N678m fún àtúnṣe Ojúbọ Sango-Timi nílùú Ede? Àlàyé rèé

Gomina Ademola Adeleke n buwọ lu iwe ni ọọfiisi rẹ

Oríṣun àwòrán, Gov Ademola Adeleke/X

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Iroyin to tẹ wa lọwọ lati ipinlẹ Osun ti sọ pe awọn eeyan ipinlẹ naa ti ke gbajare lori N678m ti wọn ni Gomina Ademola Adeleke buwọlu fun atukọ Ojubọ Sango-Timi to wa ni aafin Timi Agbale ilu Ede, Ọba Adesola Lawal.

Ọpọ ọmọbibi ipinlẹ Osun ti wọn bawọn akọroyin sọrọ ni wọn fẹsun kan Gomina Adeleke wi pe o n na owo ilu ni inakunaa.

Awọn mii tun sọ pe gomina n ṣegbe lẹyin ilu rẹ Ede pẹlu bi o ti buwọlu owo gọbọi fun atunṣe ojubọ Sango-Timi to wa ni aafin ọba ilu rẹ.

Awọn ọmọbibi ipinlẹ Osun mii ti wọn tun sọrọ lori itakun ayelujara fẹsun kan gomina wi pe lori ilu rẹ lo n na pupọ ninu owo ipinlẹ Osun si.

Oyewole Sakariyau ni tiẹ beere loju opo Facebook rẹ pe ki ni iwulo ojubọ gan an fawọn eeyan ipinlẹ Osun.

''Ijọba gbọdọ ṣalaye iwulo tabi anfaani to wa ninu ojubọ fun araalu, to ba jẹ pe loootọ ni gomina buwọlu owo gọbọi naa fun atunṣe Ojubọ Sango-Timi,'' Sakariyau lo sọ bẹẹ.

Omotoba Adaramaja ni tiẹ koro oju si igbesẹ naa, o ni nnkan to buru jai ni pe ọrọ ojubọ ṣe pataki si gomina ju igbayegbadun araalu lọ.

Adaramaja ni ''ki ni pataki atunṣe ojubọ nibi ti ebi ti n pa awọn eeyan ipinlẹ Osun, amọ ṣa, awọn eeyan n wo gbogbo nnkan ti ijọba n ṣe o.''

Ẹwẹ, Bash Adams, to jẹ ọmọbibi ilu Ede ti ojubọ naa wa ti sọ pe iyalẹnu lo jẹ wi pe gomina ipinlẹ Osun n nawo lori atunṣe ojubọ, nigba ti ọpọ nnkan to ṣe pataki wa nilẹ lai tii ṣe.

''Ọmọ ilu Ede ni mi, ṣugbọn mi o fọwọ si igbesẹ yii tori ọpọ nnkan lo wa nlẹ ti ijọba le nawo le lori ju ojubọ lọ,'' Adams lo sọ bẹẹ.

Iwadii BBC Yoruba fi han pe loootọ ni Gomina Adeleke buwọlu N678m fun atunṣe ojubọ Sango-Timi

Iwadii BBC Yoruba fi han pe loootọ ni ijọba ipinlẹ Ọsun ti iṣẹ atunṣe ojubọ Sango-Timi laafin Timi Agbale ilu Ede fun agbaṣẹṣe.

Gẹgẹ bí alaye to wa lori itakun ayelujara àjọ Osun e-GP to n ri si bi ìjọba ṣe n gbe awọn akanṣe iṣẹ ilu fawọn kọngila, ìjọba Gomina Adeleke ti gbe iṣẹ atunkọ ojubọ Sango-Timi naa fun agbaṣẹṣe loootọ.

Ọjọ kẹwaa oṣu Kẹta ọdún 2025 ni ijọba ti gbe iṣẹ naa fun kọngila lati ṣe.

Ileeṣẹ ìjọba to n ri si ọrọ aṣa ati irinajo afẹ lo ṣagbatẹru akanṣe iṣẹ naa ki ìjọba to gbe fun agbaṣẹṣe.

Kódà, orukọ ileeṣẹ to gba isẹ naa lati ṣe ni i ṣe Atomhans.

Alaye lori bi ijọba ipinlẹ Osun ṣe gbe iṣẹ atunṣe ojubọ Sango-Timi niluu Ede fun agbaṣẹṣe

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Alaye lori bi ijọba ipinlẹ Osun ṣe gbe iṣẹ atunṣe ojubọ Sango-Timi niluu Ede fun agbaṣẹṣe

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Iṣẹ atunṣe ojubọ Sango-Timi lo ni iṣẹ akanṣe ikẹfa ti Gomina Adeleke yóò gbe fun agbaṣẹṣe lọdun yii, gẹgẹ bii alaye to wa lori itakun ayelujara àjọ Osun e-GP.

Alaye tun wa lori ikanni ajọ Osun e-GP pe N678,843,462 ni owo ti ijọba buwọ́lù fun akanṣe iṣẹ naa.

Ki ni ijọba Osun sọ lori atunṣe ojubọ Sango-Timi ti yoo na ijọba ni N678m?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ijọba ipinlẹ Osun ti sọ pe idi ti Gomina Ademola Adeleke fi buwọlu N678m fun atunṣe ojubọ Sango-Timi ni pe ijọba n n ṣe atunṣe gbogbo ibi iṣẹmbaye to ni ṣe pẹlu aṣa ati ẹsin lati le fa oju awọn arinrinajo afẹ mọra.

Agbẹnusọ gomina ipinlẹ Osun, Rasheed Olawale, lo fidi ọrọ yii mulẹ fun BBC Yoruba.

Ọgbẹni Olawale ṣalaye pe ''lọdun 2023 ni ijọba bẹrẹ iṣẹ atunṣe yii pẹlu ojubọ Osun Osogbo.

Iṣẹ si n lọ lọwọ lori opopona to lọ si ojubọ Osun Osogbo, bakan naa ni ijọba tun n sẹ atunṣe lori omi Osun Osogbo to fi mawọn nnkan mii to nilo atunṣe lojubọ naa.''

Olawale ni irufẹ iṣẹ yii ni ijọba fẹ ṣe ni ojubọ Sango-Timi naa eyi to wa lara ibi iṣẹmbaye ti ajọ UNESCO buwọlu, nitori kaakiri agbaaye lawọn alejo ti maa n ṣabẹwo si ojubọ naa.

O ni gbogbo eto to yẹ ki ijọba ṣe ki o to gbe iṣẹ naa jade ni o ṣe, ati pe atunṣe ojubọ naa wa ninu eto iṣuna ipinlẹ Osun ti ọdun 2025 yii.

Olawale fikun ọrọ rẹ pe ọpọ iṣẹ to wa ninu eto iṣuna ipinlẹ Osun fọdun 2025 ni ijọba ko tii le nitori airowogba awọn ijọba ibilẹ l'Osun.

O ni iṣẹ atunṣe ojubọ Sango-Timi naa ko tiẹ tii bẹrẹ tori ijọba ko tii ri owo lati fi ṣe e.