Ta ni Aitana Bonmati tó gbàmì ẹ̀yẹ Ballon d'Or lẹ́ẹ̀mẹ́ta léra wọn lẹ́yìn tórí kó o yọ lọ́wọ́ àrùn yínrùn-yínrùn?

Oríṣun àwòrán, Reuters
Gbajugbaja agbabọọlu obinrin orilẹede Spain to n gba bọọlu fun Barcelona lo gbami ẹyẹ bọọlu Ballon d'Or ti ọdun 2025 yii.
Lalẹ ana ni wọ kede Bonmati gẹgẹ bi agbabọọlu obinrin to gbade Ballon d'Or tọdun yii niluu Paris.
Bonmati ni agbabọọlu obinrin akọkọ ti yoo gba ami ẹyẹ naa fun igba mẹta lera wọn.
Akẹgbẹ rẹ, Mariona Caldentey, to n gbabọọlu fun Arsenal lo ṣe ipo keji.
Nigba ti o n gba ami ẹyẹ naa lọwọ agbabọọlu Barcelona tẹlẹ, Andres Iniesta, Bonmati sọ pe bi oun ṣe gba ami ẹyẹ Ballon d'Or fun igba mẹta lera wọn dabi ala loju oun.
O ni oun gbagbọ pe o ṣee ṣe ki ami ẹyẹ naa bọ si agbabọọlu miran lọwọ yatọ soun.
Bonmati tun fi idunnu rẹ han lori bo ti jẹ pe Iniesta toun maa n wo bi awokọṣe nigba toun wa ni kekere lo gbe ami ẹyẹ naa le oun lọwọ.
Bonmati tori ibusun aisan gbami ẹyẹ Ballon d'Or fun igba kẹta
Ṣaaju idije Euro 2025 tawọn obinrin ni Bonmati wa lori idubulẹ aisan nigba to ni arun yinrun-yinrun.
Koda, oun gan an ko mọ pe oun yoo si lanfaani lati kopa ninu idije Euro mọ pẹlu aisan to da a gunlẹ.
Amọ, lẹyin ti Bonmati jade nile iwosan tan ni o gba goolu to gbe Spain wọ abala aṣekagba idije naa sawọn ninu ifẹsẹwọnsẹ ti wọn gba pẹlu Germany.
Bo tilẹ jẹ pe England fi pẹnariti lu wọn gbami ẹyẹ idije Euro 2025, Bonmati fakọyọ fun Spain ninu idije naa.
Agbabọọlu England tẹlẹ ri, Fara Williams, sọ fun BBC pe ti ẹgbẹ agbabọọlu Spain ba maa jawe olubori ninu ifẹsẹwọnsẹ kankan, Bonmati lo maa n ṣaba jẹ pe o maa fakọyọ to si maa jẹ ki Spain bori.
Ọpọ eeyan lo gba pẹlu Williams wi pe oootọ lọrọ to sọ pẹlu bi Bonmati ti gba ami ẹyẹ Ballon d'Or fun igba mẹta lera wọn bayii.
Ta a ni Aitana Bonmati?
Ọjọ kejidinlogun oṣu Kinni ọdun 1998 ni wọn bi Aitana Bonmati.
Agbabọọlu aarin gbungbun ni Bonmati jẹ fun ikọ agbabọọlu obinrin Spain ati fun ẹgbẹ agbabọọlu Barcelona.
Lẹyin to gba gbogbo ami ẹyẹ to lamilaaka ninu ere bọọlu eyi ti wọn fi kede rẹ gẹgẹ bi agbabọọlu obinrrin to pegede julọ ni Yuroopu lọdun 2023, ọpọ eeyan lagbo ere bọọlu lo n ri Bonmati gẹgẹ bii ọkan lara agbabọọlu obinrin to pegede julọ ninu itan.
Bonmati ti wa ni ẹgbẹ agbabọọlu Barcelona lati ọdun 2012, nibẹ naa lo ti ṣe igba ewe rẹ.
Ẹgbẹ agbabọọlu ọjẹwẹwẹ Barcelona ni Bonmati ti bẹrẹ irinajo bọọlu gbigba rẹ, ki o to darapọ mọ ẹgbẹ agbabọọlu agba Barcelona ni saa bọọlu 2016/2017.
O ti gba ami ẹyẹ liigi marun un, Copas de la Reina mẹfa, Supercopas marun un, ami ẹyẹ Copas Catalunyas mẹrin ati ife ẹyẹ UEFA Champions League awọn obinrin mẹta.
Lẹyin ti Bonmati gba ami ẹyẹ Ballon d'Or ati ami ẹyẹ FIFA Best lọdun 2023 ati 2024 ni o tun gba Ballon d'Or ti ọdun yii lalẹ ana ọjọ Aje ọjọ kejilelogun oṣu Kẹsan an.
Goli Super Falcons Chiamaka Nnadozie ṣe ipo kẹrin nibi ami ẹyẹ Ballon d'Or

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Aṣọle ẹgbẹ agbabọọlu Super Falcons, Chiamaka Nnadozie, lo gba ipo kẹrin ni isọri awọn aṣọle obinrin to pegede julọ lagbaaye nibi ayẹyẹ Ballon d'Or tọdun 2025.
Nnadozie ni aṣọle ọmọ ilẹ Afirika to pegede julọ bayii, bakan naa lo tun fakọyọ lagbo awọn goli lagbaaye pẹlu ipo kẹrin to gba.
Agbabọọlu Chelsea, Hannah Hampton, lo gba ami ẹyẹ Yashin Trophy naa eyi to jẹ akọkọ iru rẹ.
Ti ẹ o ba gbagbe, Hampton gba ami ẹyẹ Euro 2025 pélu England, bakan naa ni o tun gba ami ẹyẹ mẹta ọtọọtọ pẹlu Chelsea.
Ọpọ eeyan lo ti n gbe oṣuba rabandẹ fun Nnadozie lori aṣeyọri nla to ṣe yii.
Nnadozie to n gba bọọlu fun Brighton ni England gba ife ẹyẹ Wafcon pẹlu Super Falcons Naijiria lọdun 2025 yii.
Nibi idije bọọlu agbaye awọn obinrin – 2023 Women's World Cup – ni ọpọ eeyan ti mọ Nnadozie gẹgẹ bi aṣọle to pegede lẹyin to fakọyọ ninu idije naa fun Naijiria.
Dembele la Yamal mọlẹ gbami ẹyẹ Ballon d'Or

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ẹlẹsẹ ayo ẹgbẹ agbabọọlu PSG ati orilẹede France, Ousmane Dembele, lo gbami ẹyẹ Ballon d'Or awọn agbabọọlu ọkunrin fun ọdun 2025.
Ami ẹyẹ mẹta ọtọọtọ ni Dembele gba ni saa bọọlu 2024/2025 ti o fi la Lamine Yamal agbabọọlu Barcelona mọlẹ gba ami ẹyẹ Ballon d'Or tọdun yii.
Goolu marundinlogoji ni Dembele gba sawọn ninu ifẹsẹwọnsẹ mẹtalelaadọta to kopa ninu rẹ.
Ni ṣe ni omije n da poro poro loju Dembele nigba ti wọn pe e wi pe oun lo gba ami ẹyẹ naa.
Meji ni agbabọọlu ilẹ Afirika to wa ninu awọn agbabọọlu to ṣe ipo kinni si ikẹwaa
1. Ousmane Dembélé
2. Lamine Yamal
3. Vitinha
4. Mohamed Salah
5. Raphinha
6. Achraf Hakimi
7. Kylian Mbappé
8. Cole Palmer
9. Gianluigi Donnarumma
10. Nuno Mendes















