Wo ọ̀nà tí oru àmújù fi ń pa DNA rẹ lára tó sì ń mú ọ tètè di arúgbó

Oríṣun àwòrán, AFP via Getty Images
- Author, Angela Henshall
- Role, BBC World Service
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5
Suleyman Hammudan ti dagba si ilu ti oru amuju ti maa n mu, oru naa si ti mọ lara.
O n ṣisẹ pẹlu ileeṣẹ to n ta ohun elo ayara bii aṣa ni United Arab Emirates nibi ti oru ti maa n mu ni nnkan bii iwọn 45C laarin oṣu Kẹfa si oṣu Kẹsan an ọdun.
O ni "Ti o ba wa ni ita ni ọsangangan niṣe lo maa da bii igba ti o wa ni aarin aṣalẹ.
"Ile ni mo ti maa n ṣiṣẹ lọpọ igba. Ti mo ba jade sita o maa n to nnkan bii aago meje alẹ nigba ti oorun ti wọ nitori oru to maa n mu ko ṣe e farada.
Iwọnba eeyan perete lo n jade lasiko ooru, o ni "fun idi eyii, irin mi ko ju lati ile sinu ọkọ mi, lati inu ọkọ mi si ibiṣẹ.
"Gbogbo ibi ni ẹrọ amuletutu wa, paapaa lawọn ile itaja igbalode ti awọn eeyan fẹran lati maa duro lọsan. Ile wa keji ni ile itaja igbalode!"
Gẹgẹ bii ọpọ ninu wa, Suleyman ti n farada igebaye rẹ tuntun yii bo tilẹ jẹ pe ooru naa ṣoro lati farada.
Awọn onimọ sayẹnsi n ṣe iwadii ohun to maa n ṣẹlẹ ninu agọ ara ti ara eeyan ba n foriko irufẹ ooru bayii leralera.
Iwadii kan ti fasiti Southern California nilẹ Amẹrika, USC, ṣe wo ẹgbẹgbẹrun ọmọ ilẹ naa to n gbe ni oruru ipinlẹ ti oju ọjọ wọn yatọ si ara wọn nibi ti iye iwọn oju ọjọ ti le ni 32C tabi 90
Lẹyin ti wọn gba ẹjẹ awọn eeyan 3,600 lati wo ọjọ ori wọn si bi wọn ṣe gbo to.
Ẹni to ṣagbatẹru iwadii ọhun, Eunyoung Choi sọ pe awọn to wọn n koju oru n tete gbo ṣaaju awọn ti ko fi bẹẹ koju oru.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ṣe oru le akoba ayeraye fun agọ ara rẹ?
Awọn onimọ sayẹnsi ti mọ pe oru le ṣakoba fun ọkan, kidinrin atawọn nnkan mii ni agọ ara ẹda.
Ẹwẹ, akọsilẹ fasiti USC fi han pe ti eeyan ba n wa ninu ooru pupọ ju le ṣa atunto DNA eeyan, eyii ni wọn n pe 'methylation.'
Jeff Goodell, to kọ iwe "The Heat Will Kill You First - Life and Death on a Scorched Planet" sọ pe bi oru ṣe n mu eeyan ni awọn ọra to yi awọn sẹẹli ara ẹni naa yoo maa ku.
O ni "awọn ohun to gbe sẹeli naa duro yoo maa tuka, nnkan to maa n ṣelẹ niyi ti eeyan ba n se ẹyin."

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ki ni wọn n pe ni 'epigenetic ageing?'
Bawo ni a ṣe n tete se awọn sẹeli agọ ara wa si?
Ọmọwe Choi lati USC ni lootọ ni pe awọn kan maa n tete gbo ju awọn mii lọ, amọ nkankan wa ti wọn n pe ni 'epigenetic ageing.'
Epigenetic ageing yii ni awọn onimọ fi n ṣe odinwọn bi eeyan ṣe n dagba si.
O maa n sọ bi agọ ara eeyan ṣe maa n ṣiṣẹ ninu sẹeli.
Ọmọwe Choi sọ pe lati igba ti eeyan ba ti n fagba ninu oyun ni DNA rẹ ti maa n korajọ amọ methylation le ṣe ayipda rẹ.
Ayẹwo ẹjẹ ni wọn fi n mọ bi ayipada ṣe n waye ninu DNA ati ninu DNA methylation (DNAm).
"DNA ni bi a ṣe ri ni ibẹrẹpẹpẹ, nigba ti methylation jẹ ohun to maa n ṣe ayipada si
"Ohun to ṣe pataki ni pe ki a mọ bi nnkan yii ṣe n waye ati pe awọn ohun to yi wa ka bii wahala to pọ ju, idọti inu afẹfẹ.. ati ni bayii, oru naa le ṣatunṣe si nnkan wọnyii."
Choi sọ pe esi ayẹwo rẹ fi han pe ipa to tobi ni oru amuju n ni ninu agọ ara wa.
O ni "A le fi ipa yii we ipa ti siga mimu ati ọti amuju maa n ni lara ẹda.
Bo tilẹ jẹ pe ipa yii le kere loju, amọ diẹ diẹ ni oru maa n ni ipa lara ẹda.
Eyii n tumọ si pe eeyan le tete ni awọn aisan to maa n waye lọjọ ogbo bii itọ ṣuga, aisan ọkan, ati bẹẹ bẹẹ lọ latari ipa ti oru n ni ninu ara.
Bawo ni irun funfu ati hinhunjọ?
Ni bayii, ṣe ti eeyan ba n gbe nibomii tabi ibi ti ko ni oru to pọju le mu iyatọ ba bi eeyan ṣe ri?
Suleyman ni ohun ti oun ṣakiyesi ni pe oun n tete dagba si ni Dubai latari bi awọn ila tuntun ṣe n fara han loju oun.
O ni "Lọdun ti kọja, mo lọ ba dokita ni ijiroro lori bi oorun ṣe jo oju mi lara.
"Awọ ara mi jona gidi, ni bayii mo ti n ri apa lara mi."
Gẹgẹ bo ṣe sọ, nibi ti ọrọ naa de duro bayii, o ṣeeṣe ki oun lọ maa gbe niluu London.
O sọrọ lati mọ boya oru maa n mu ki irun eeyan tete funfun.
Eroja 'melanocytes' lo maa n mu ki irun eeyan funfun ṣugbọn.
Ohun ti a mọ ni pe oniruru nnkan lo n ṣẹlẹ ninu agọ ara eeyan latari oru apọju yii.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ta lo nilo aabo to pọju lọ lọwọ oru?
Ninu iwadii kan lọdun 2023 ni Germany, Ọmọwe Wenli Ni sọ pe ṣe lootọ ni oru maa n jẹ ki awọn sẹeli ara eeyan tete gbo.
O sọ pe ti eyii ba n waye, o le yọri si awọn aisan kan bii itọ ṣuga, aisan ọkan ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Amọ ṣa, iwadii naa ko sọ ni pato sẹeli gan to maa tete darugbo julọ latari oru.
Ikọ Choi ti sọ pe awọn yoo ṣe iwadii mii lati mọ boya awọn sẹeli ọpọlọ tabi sẹeli ọkan ni ipalaa naa maa n
pọ ju fun julọ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images














