Ní Isanlu Isin ní ìpínlẹ̀ Kwara, àwọn ajínigbé fòkúta fọ́ orí ọlọ́dẹ, ọdẹ míran dàwátì, orí kó 16 yọ
Ipenija ọrọ abo ni ilu Isanlu Isin kii ṣe eyi to ṣe ajeji mọ pẹlu bi iroyin ọṣẹ tawọn ajinigbe n ṣe lagbegbe naa ti kan kaakiri bayii.
Laipẹ yii ni awọn ọdọ agbegbe naa fọn si oju popo lati ṣe ifẹhonuhan tako bi ijinigbe ṣe n di lemọlemọ ni agbegbe naa.
Nigba ti BBC News Yoruba tun kan si ibẹ la tun wa gbọ pe nigba ti awọn ọlọdẹ agbegbe naa kẹfin ibi tawọn oniṣẹ ibi naa n fi ṣe ibuba wọn ti wọn si ṣigun lọ sibẹ, wọn rii pe awọn ajinigbe naa ni ibuba kan ti wọn n lo.

Oluọdẹ ilu Isanlu Isin Ọgbẹni Sunday Awoẹyọ ṣalaye pe awọn ajinigbe naa ṣina ibọn bolẹ wọn ti awọn ọlọdẹ naa si tun daa pada.
Nibi ti wọn ti n sare lati yẹra fun awọn ibọn atamatase ti awọn ajinigbe naa nlo lawọn meji ninu awọn ọdẹ naa ti sọnu.
Ọgbẹni Awoẹyọ ṣalaye pe nigba ti wọn pada wa awọn meji naa lọ, wọn ba oku ọkan nibi ti wọn ti fi okuta fọ ori rẹ, ṣugbọn wọn ko tii ri ẹni keji.
Awọn mọlẹbi awọn ọdẹ mejeeji yii ni wọn ti n kegbajare si ijọba pe ki wọn wa wọrọkọ fi ṣada lori ọrọ naa.





