Ballon d'Or 2025: Gbogbo ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa àmì ẹ̀yẹ náà àtàwọn tó ń díje

Dembele, Mbape ati Yamal lasiko ti wọn n gba bọọlu fun ikọ agbabọọlu wọn

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ọdun 1956 ni wọn bẹrẹ si n ṣe ami ẹyẹ Ballon d'Or lọdọdun, lati igba naa wa ni awọn agbabọọlu to dantọ ti n fakọyọ ninu rẹ
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Oni ọjọ Aje, ọjọ kejilelogun, oṣu Kesan an, ọdun 2025 ni ami ẹyẹ bọọlu agbaye, Ballon d'Or yoo waye.

Asiko ayẹyẹ naa ni wọn maa n kede awọn agbabọọlu to lamilaaka julọ lagbaye ni ẹka bọọlu afẹsẹgba awọn ọkunrin ati obinrin.

Inu gbagede héâtre du Châtelet to wa niluu Paris, lorilẹede France ni ayẹyẹ naa yoo ti waye lalẹ oni.

Itan nipa ami ẹyẹ Ballon d'Or

Ọdun 1956 ni wọn bẹrẹ si n ṣe ami ẹyẹ Ballon d'Or lọdọdun, lati igba naa wa ni awọn agbabọọlu to dantọ ti n fakọyọ ninu rẹ.

Stanley Matthews lo gba ami ẹyẹ ọhun fun igba akọkọ lẹyin ti iwe iroyin bọọlu afẹsẹgba France sọ ọ di gbajumọ ni nnkan bii ọgọrin ọdun ṣeyin.

Lọdun 2018, wọn bẹrẹ ami ẹyẹ naa ni ẹka bọọlu afẹsẹgba ti awọn obinrin.

Lọdun 2022 ati 2023, agbabọọlu obinrin ọmọ Naijiria Asisat Oshoala wa lara awọn ti wọn fa kalẹ fun ami ẹyẹ ọhun amo ko pegede.

Bawo ni wọn ṣe n yan ẹni ti yoo gba ami ẹyẹ naa?

Ki wọn to mọ ẹni ti yoo gba ami ẹyẹ naa, wọn yoo kọkọ ko orukọ agbabọọlu ọgbọn kalẹ.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Awọn ti yoo fa orukọ ọgbọn eeyan ọhun kalẹ ni awọn ọga akọroyin iwe iroyin France Footbal, iwe iroyin L'Equipe atawọn aṣoju ajọ UEFA.

Amuyẹ ti wọn yoo lo lati fi fa eeyan kalẹ ni bi wọn ṣe dantọ to laarin ọjọ kinni, oṣu Kẹjọ, ọdun 2024 si ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Keje, ọdun 2025.

Awọn agbabọọlu ti wọn si maa n fa kalẹ ni awọn to n kopa ninu liigi ilẹ Yuroopu atawọn agbabọọlu FIFA Club World Cup.

Lẹyin naa, akọroyin kọọkan lati orilẹede ọgọrun to n lewaju ninu iwe FIFA yoo fa mẹwaa kalẹ ninu awọn orukọ ọgbọn to wa nilẹ tẹlẹ fun ami ẹyẹ ọhun.

Fun ipele ti awọn obinrin, awọn akọroyin lati orilẹede aadọta to n lewaju ninu iwe FIFA ni yoo fa orukọ kalẹ.

O ni iye maaki ti wọn maa la kalẹ fun nọmba ti orukọ agbabọọlu ba wa; fun apẹrẹ, agbabọọlu ti orukọ rẹ ba wa ni nọmba akọkọ yoo gba maaki marundinlogun, nigba ti agbabọọlu ti orukọ rẹ ba wa ni nọmba kẹwaa to gbẹyin yoo gba maaki kan ṣoṣo.

Agbabọọlu ti maaki rẹ pọ julọ lẹyinorẹyin ni yoo gba ami ẹyẹ ọhun.

Agbabọọlu to ṣeeṣe ko gba ami ẹyẹ naa lọdun yii

Iwọnyi ni awọn agbabọọlu to ṣeeṣe ko gba ami ẹyẹ naa lọdun yii ati ẹgbẹ agbabọọlu ti wọn wa.

  • Ousmane Dembele (PSG)
  • Harry Kane (Bayern Munich)
  • Kylian Mbappe (Real Madrid)
  • Raphinha (Barcelona)
  • Mohamed Salah (Liverpool)
  • Lamine Yamal (Barcelona)

Iwọnyii ni awọn to ti gba ami ẹyẹ naa lati ọdun 1956 titi di ọdun 2024

Ballon d'Or ipele ọkunri

  • 1956 – Stanley Matthews
  • 1957, 1959 – Alfredo Di Stéfano
  • 1958 – Raymond Kopa
  • 1960 – Luis Suárez
  • 1961 – Omar Sivori
  • 1962 – Josef Masopust
  • 1963 – Lev Yashin
  • 1964 – Denis Law
  • 1965 – Eusébio
  • 1966 – Bobby Charlton
  • 1967 – Flórián Albert
  • 1968 – George Best
  • 1969 – Gianni Rivera
  • 1970 – Gerd Müller
  • 1971 – Johan Cruyff
  • 1972 – Franz Beckenbauer
  • 1973, 1974 – Johan Cruyff
  • 1975 – Oleh Blokhin
  • 1976 – Franz Beckenbauer
  • 1977 – Allan Simonsen
  • 1978, 1979 – Kevin Keegan
  • 1980, 1981 – Karl-Heinz Rummenigge
  • 1982 – Paolo Rossi
  • 1983, 1984, 1985 – Michel Platini
  • 1986 – Ihor Belanov
  • 1987 – Ruud Gullit
  • 1988, 1989 – Marco van Basten
  • 1990 – Lothar Matthäus
  • 1991 – Jean-Pierre Papin
  • 1992 – Marco van Basten
  • 1993 – Roberto Baggio
  • 1994 – Hristo Stoichkov
  • 1995 – George Weah
  • 1996 – Matthias Sammer
  • 1997 – Ronaldo
  • 1998 – Zinédine Zidane
  • 1999 – Rivaldo
  • 2000 – Luís Figo
  • 2001 – Michael Owen
  • 2002 – Ronaldo
  • 2003 – Pavel Nedvěd
  • 2004 – Andriy Shevchenko
  • 2005 – Ronaldinho
  • 2006 – Fabio Cannavaro
  • 2007 – Kaká
  • 2008 – Cristiano Ronaldo
  • 2009, 2010, 2011, 2012 – Lionel Messi
  • 2013, 2014 – Cristiano Ronaldo
  • 2015 – Lionel Messi
  • 2016, 2017 – Cristiano Ronaldo
  • 2018 – Luka Modrić
  • 2019 – Lionel Messi
  • 2020 – Ami ẹyẹ naa ko waye nitori Covid-19
  • 2021 – Lionel Messi
  • 2022 – Karim Benzema
  • 2023 – Lionel Messi
  • 2024 – Rodri

Ballon d'Or ipele awọn obinrin

  • 2018 – Ada Hegerberg
  • 2019 – Megan Rapinoe
  • 2021 – Alexia Putellas
  • 2022 – Alexia Putellas
  • 2023 – Aitana Bonmatí
  • 2024 – Aitana Bonmatí