Agbégbọn kọlu Benue, agbófinró mẹ́wàá pàdánù ẹmi wọn

Awọn agbebọn ti wọn fi aṣọ bo oju wọn

Oríṣun àwòrán, Sahara Reporters

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Nnkan bii agbofinro mẹwaa lo ti padanu ẹmi wọn ti ọpọ si di awati lẹyin ikọlu kan ni ipinlẹ Benue.

Iroyin ni awọn afurasi Fulani darandaran lo wa nidi ikọlu naa.

A gbọ pe asiko ti awọn agbofinro ọhun n ṣe ayẹwo ayika ni wọn ko si koto ti awọn agbebọn naa dẹ sile de wọn lọjọ kọkandinlogun, oṣu yii.

Gẹge bii ohun ti alaga agbegbe Katsina-Ala, Shaku Justice sọ, awọn agbebọn, janduku, Fulani darandaran atawọn agbebọn mii lati ipinlẹ Taraba lo pawọpọ ṣe ikọlu naa.

Gẹgẹ bii ohun ti a gbọ, awọn agbebọn ọhun lo oniruru ohun ija oloro nla bii RPG atawọn ohun ija mii fun ikọlu ọhun.

Fun ọpọ wakati ni ija naa fi waye laarin ikọ mejeji ki ọwọ wọn to tẹ agbofinro kan ti orukọ rẹ n jẹ Danzaru, ti awọn mii si padanu ẹmi wọn.

Ibọn ba ọkan lara awọn agbofinro naa lọwọ nigba ti ọlọpaa kan ati fijilante meji ku lẹsẹkẹsẹ.

Ni bayii, awọn ọmọ ogun ti lọ si agbegbe naa lati wa oku awọn akẹgbẹ wọn to ṣubu loju ija.