Trump buwọ́lu òfin tuntun físà H-1B tí yóò mú kí àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ máa san $100,000 lọ́dọọdún

Aarẹ Donald Trump lẹyin to buwọlu aṣẹ tan ni ọọfisi rẹ nile ijọba niluu Washington

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Awọn to fọwọ si ofin tuntun yii, bii ọrẹ Trump timọ-timọ, Elon Musk, sọ pe igbesẹ naa n tumọ si pe awọn ogidi akọṣẹmọṣẹ nikan ni yoo maa wọ Amẹrika
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Aarẹ Amẹrika Donald Trump ti buwọlu aṣẹ kan ti yoo sọ ọ di dandan fun awọn to ba fẹ gba fisa H-1B ti wọn fi n ṣiṣẹ nilẹ naa lati maa san $100,000.

Fisa H-1B yii lo wa fun awọn akọṣẹmọṣe to fẹ lọ silẹ Amẹrika lati lọ ṣiṣẹ.

Trump sọ pe aṣẹ yii ṣe pataki latari bi awọn eeyan kan ṣe n lo fisa naa ni ilokulo lati ẹyin wa, ẹni to ba si kọ lati san owo yii ko ni lanfaani lati wọ Amẹrika.

Ọdọọdun ni awọn to ba ni fisa yii yoo maa san owo ọhun.

Ṣaaju ni awọn araalu kan ti kọkọ n sọ pe fisa naa ko jẹ ki awọn ọmọ oniluu ri iṣẹ ṣe l'Amẹrika.

Awọn to fọwọ si ofin tuntun yii, bii ọrẹ Trump timọ-timọ, Elon Musk, sọ pe igbesẹ naa n tumọ si pe awọn ogidi akọṣẹmọṣẹ nikan ni yoo maa wọ Amẹrika.

Ninu aṣẹ mii, Trump buwọlu lilo kaadi wura kan 'Gold Card' ti yoo jẹ ki fisa awọn eeyan kan ya kankan amọ ẹni to ba fẹ gba kaadi naa gbọdọ ni owo ti iye rẹ jẹ miliọnu kan dọla lati ko fun ijọba Amẹrika.

Ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹsan an, ọdun 2025 yii ni aṣẹ naa yoo bẹrẹ iṣẹ.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Akọwe eto iṣuna ilẹ Amẹrika, Howard Lutnick sọ pe awọn to ba ṣẹṣẹ fẹ gba fisa tuntun ni ọrọ naa kan gbọngbọn amọ awọn ileeṣẹ yoo san iye owo kan naa fun awọn oṣiṣẹ wọn kọọkan fun ọdun mẹfa.

Lutnick ni "Ileeṣẹ ọhun yoo ni lati pinnu… boya oṣiṣẹ naa ṣe pataki to bẹẹ lati maa san $100,000 fun ijọba lori ẹni naa tabi ki wọn pada si orilẹede wọn ki wọn si gba ọmọ ilẹ Amẹrika mii fun iṣẹ ọhun."

O fi kun pe gbogbo awọn ileeṣẹ nlanla to wa nilẹ naa lo ti fara mọ igbesẹ yii.

Ṣaaju asiko yii, gbogbo awọn owo ti awọn eeyan n san lori fisa H-1B ko ju $1,500 lọ.

Agbẹjọro Tahmina Watson, to jẹ oludasilẹ ileeṣẹ Watson Immigration Law sọ fun BBC pe ofin tuntun yii yoo ṣe akoba nla fun ileeṣẹ atawọn oṣiṣẹ oun.

Alaye lati ajọ US Citizenship and Immigration Services (USCIS) fi han pe, nnkan bii 359,000 eeyan lo ti n gbaradi lati gba fisa naa lọdun to n bọ.

Gẹgẹ bii ohun ti wọn sọ, lara ileeṣẹ to janfaani awọn fisa naa sẹyin julọ ni Amazon, atawọn ileeṣẹ imọ ẹrọ igbalode bii Tata, Microsoft, Meta, Apple ati Google.

Jorge Lopez, to jẹ alaṣẹ ajọ Littler Mendelson PC sọ pe, igbesẹ naa yoo fa ọwọ aago awọn ileeṣẹ imọ ẹrọ igbalode ati ọwọ ọpọlọpọ ileeṣẹ mii sẹyin nilẹ Amẹrika.