Àdó olóró láti ojú òfúrufú ṣekúpa èèyàn 78 lásìkò ìrun nínú mọ́ṣáláṣí

Oríṣun àwòrán, X
O le ni aadọrin eeyan to padanu ẹmi wọn lẹyin ti ado oloro lati oju ofurufu kọlu mọṣalaṣi kan ni Darfur, lorilẹede Sudan.
Iṣẹlẹ naa to waye niluu el-Fasher ni wọn ti di ẹbi rẹ ru ẹgbẹ ọmọ ogun Rapid Support Forces (RSF), amọ ẹgbẹ naa ko tii sọ boya awọn lo wa nidi ikọlu ọhun.
Lati nnkan bii ọdun meji sẹyin ni ọmọ ogun Sudan atawọn ọmọ ogun RSF ti n kọju ija si ara wọn.
RSF n bori ogun naa bi wọn ṣe n gba ọpọ ilẹ ni el-Fasher – eyi to jẹ ibi ti ọpọ ologun wa ti araalu ti iye wọn le ni 300,000 ti ha si bayii latari ija naa.
Ọkan lara awọn olugbe agbegbe ọhun sọ pe asiko irun afẹmọju ni ado oloro naa balẹ.
Awọn oṣiṣẹ eto ilera jabọ pe eeyan mejidinlaadọrin lo jade laye nigba ti ogun eeyan mii farapa yanna-yanna, amọ wọn ṣi n ko awọn eeyan jade labẹ ile to dawo le wọn lori.
Ikọ oluwadii BBC, BBC Verify fidi fidio kan mulẹ to ṣafihan oku eeyan ọgbọn ti wọn fi aṣọ we lẹba mọṣalaṣi ti ikọlu naa ti waye.
Laarin ọsẹ yii ni RSF bẹrẹ ikọlu tuntun siluu El Fasher, eyii ti wọn ti n gbogun ti lati ọdun kan sẹyin.
Lara awọn agbegbe ti ikọ ologun naa kọlu ni Abu Shouk, to jẹ ibi ti awọn akanda ẹda pọ si.
Ajọ Yale University's Humanitarian Research Lab (HRL), to n bojuto ogun naa ni awọn aworan lati oju ofurufu ṣafihan pe RSF ti n gba ọpọ ilẹ nibẹ.
Wọn ni ọmọ ogun RSF ti wọ olu ọọfisi Joint Forces to jẹ ibi ti awọn ọmọ ogun orilẹede Sudan n n ṣakoso ṣaaju.
Ọọfisi naa lo wa ninu ọgba ti ajọ UN atawọn ẹgbẹ ọmọ ogun mii ti wọn wa lẹyin ọmọ ogun Sudan n lo tẹlẹ .
BBC Verify fidi rẹ mulẹ pe RSF ti wa ninu ọgba naa amọ a ko le sọ boya wọn ti gba iṣakoso ọgba ọhun yanyan.
Aṣeyọri RSF yii n tumọ si pe yoo rọrun fun lati kọlu papakọ ofurufu el-Fasher ati ibudo ologun to wa ninu ilu naa.
Ti ọwọ RSF ba le tẹ gbogbo ilu ọhun, o n tumọ si pe awọn ni yoo maa ṣakoso gbogbo agbegbe iwọ oorun Sudan nigba ti ọmọ ogun orilẹede naa yoo maa ṣakoso iha Ariwa.
Wayi o, awọn onimọ kan ti sọ pe o ṣeeṣe ki wọn kọju ija si awọn araalu ti ko le daabo bo ara wọn.
Ajọ UN sọ ninu atẹjade kan pe ẹgbẹ ọmọ ọhun n ṣekupa ọgọrọ eeyan ti kii ṣe ẹya Arab amọ RSF ni ko si ohun to jọ bẹẹ.















