Ṣé lóòótọ́ ni pé Chef Dammy fẹ́ se ìkòkò ẹ̀wà tó tóbi júlọ ní àgbáyé?

Oríṣun àwòrán, Chef Dammy
Damilola Adeparusi, ti ọpọ mọ si Chef Dammy, ti sọ pe irọ ni gbogbo iroyin to n lọ lori ayelujara pe oun fẹ se ikoko ẹwa to tobi julọ lagbaye.
Chef Dammy lo fi ọrọ naa lede ninu fidio kan to fi soju opo Instagram lọjọbọ.
Ọdọbinrin naa kọkọ ki Hilda Baci ku oriire fun aṣeyọri rẹ ninu sise ikoko irẹsi jọlọọfu to tobi julọ lagbaye.
Lẹyin naa lo ki ileeṣẹ Gino, to ṣe agbatẹru igbiyanju naa ku oriire fun aṣeyọri ọhun.
Chef Dammy sọ pe "Mo ki Hilda Baci ku oriire fun aṣeyọri rẹ bo ṣe se ikoko irẹsi jọlọọfu to tobi julọ... eyii to fi bọ ẹgbẹgbẹrun eeyan.
"Aṣeyọri naa jẹ ti gbogbo ọmọ Naijiria nitori ko rọrun lati ṣe irufẹ nnkan bẹẹ."

Oríṣun àwòrán, Chef Dammy
"Mi o sẹ ikoko ẹwa to tobi julọ, ko si ohun to jẹ bẹẹ"
Damilola tẹsiwaju pe "Mo n ṣe fidio yii nitori awọn eeyan ti n bere lọwọ mi pe ṣe mo tun fẹ se ounjẹ lẹẹkan si ni.
"Inu yara idana ni mo wa ti awọn akẹgbẹ mi nile ẹkọ bẹrẹ si n beere lọwọ mi pe, Chef Dammy, ṣe o fẹ se ẹwa loootọ ni?
"Irọ ni o. Ki lo de ti mo fi maa ṣe bẹẹ!"
Lẹyin naa lo dupẹ lọwọ gbogbo awọn ololufẹ rẹ fun atilẹyin wọn, paapaa awọn to n ṣegbe lẹyin rẹ lori ayelujara.
Awọn wo lo n sọ pe Dammy fẹ se ikoko ẹwa to tobi julọ?
Lọsẹ to kọja ni Hilda Baci to jẹ gbajumọ alase, se ikoko irẹsi to tobi julọ lagbaye ti ọpọ araalu si jẹ ninu irẹsi naa lagbegbe Eko Hotel, niluu Eko.
Lẹyin aṣeyọri ọhun ni ọpọ eeyan bẹrẹ si n ki Baci ku oriire, amọ bi awọn kan ṣe n kan saara si Baci ni awọn mii n bu ẹnu atẹ lu Dammy.
Gẹgẹ bii ohun ti wọn n sọ, Dammy n jowu aṣeyọri Baci, o si ṣeeṣe ki oun naa fẹ gbiyanju ohun ti Baci ṣe laipẹ ọjọ.
Ṣaaju lẹyin ti Baci se ounjẹ fun ọpọ wakati lai sinmi lọdun 2023 naa ni Chef Dammy gbiyanju rẹ.
Bo tilẹ jẹ pe Baci gba ami ẹyẹ agbaye, Guinness World Record lọdun naa, Dammy ko gba ami ẹyẹ ọhun.
Lati akoko naa wa ni awọn eeyan kan ti n sọrọ abuku si Daamy pe gbogbo nnkan ti Baci ba ti ṣe ni oun naa fẹ maa dan wo.
Amọ Dammy ti sọ pe ko si ohun to jọ bẹẹ nitori oun ko figagbaga pẹlu Baci tabi ẹnikẹni.















