Darandaran dóòlà ọmọ ọwọ́ tí wọ́n sin láàyè

Oríṣun àwòrán, Anoop Mishra
- Author, Geeta Pandey
- Role, BBC News, Delhi
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4
Wọ́n ti ṣàwárí ọmọ kan tí ọjọ́ orí rẹ̀ kò ju ogúnjọ́ lọ níbi tí wọ́n sin ín sí láàyè, tó sì ń jà fún ẹ̀mí ara à rẹ báyìí gẹ́gẹ́ bí àwọn aláṣẹ ilé ìwòsàn tí wọ́n ti ń tọ́jú rẹ̀ ṣe sọ.
Darandaran kan tó ń da àwọn ewúrẹ́ láti lọ wá oúnjẹ fún wọn ló gbọ́ ohùn ọmọ náà níbi tó ti ń ké.
Nígbà tí darandaran náà súnmọ́ ibi tó ti ń gbọ́ ohùn ọmọ ọ̀hún ló ri pé, abẹ́ ilẹ̀ ni ọmọ náà ti ń sunkún, tó sì ri tí ọwọ́ rẹ̀ ń yọ láti abẹ́ ilẹ̀.
Èyí ló mu kó kàn sí àwọn èèyàn inú ìlú náà, tí wọ́n sì pe àwọn ọlọ́pàá tó hú ọmọ náà kúrò lábẹ́ ilẹ̀ náà.
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá kò ì tíì sọ àwọn tí wọ́n fura sí lórí sínsin ọmọ náà láàyè.
Ní ìlú Uttar Pradesh, ẹkùn àríwá India ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé.
Ẹ̀wẹ̀, irúfẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ fífẹ́ gba ẹ̀mí lọ́rùn àwọn ọmọ obìnrin tàbí láti má yà sí wọn wọ́pọ̀ ní orílẹ̀ èdè India látàrí àṣà wọn, tí wọ́n máa ń pọ́n ọmókùnrin lé ju obìnrin tí èyí sì wà lára ohun tó ń fa ìdí táwọn ọkùnrin àti obìnrin tó wà ní orílẹ̀ èdè náà kò ṣe ṣe déédéé.
Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí tó ti ń fa awuyewuye ní ẹkùn Shahjahanpur tó jẹ́ ẹkùn tí èrò pọ̀ sí jùlọ ní India.
Wọ́n ti gbé ọmọ náà lọ sí ilé ìwòsàn níbi tó ti ń gba ìtọ́jú ní ilé ìwòsàn ìjọba kan.
Ọ̀gá àgbà ilé ìwòsàn náà, Dókítà Rajesh Kumar sọ fún BBC pé ní ọjọ́ díẹ̀ sẹ́yìn ni wọ́n gbé ọmo náà wá sí ilé ìwòsàn pẹ̀lú àwọn ìdọ̀tí tó ti kó si ní imú àti ẹnu.
"Ó wà ní ipò tó lágbára gan, ó ń ṣe àfihàn àìsàn hypoxia tàbí pé èémí kò tó nǹkan lára rẹ̀ mọ́. Àwọn kòkòrò àti ẹranko kan ti jẹ ẹ́ lára," Dókítà Kumar sọ.
Dókítà náà fi kun pé àwọn rí ìyàtọ̀ lára ọmọ ọ̀hún lẹ́yìn ọjọ́ kan tó ti ń gba ìtọ́jú àmọ́ tó jẹ́ pé ọmọ náà tin í àwọn àìsàn kan.
Ó ní òun gbàgbọ́ pé kò pẹ́ tí wọ́n sin ọmó náà ti darandaran náà ṣe àwárí rẹ̀ nítorí àwọn egbò tó wà lára rẹ̀ kò ì tíì pẹ́ rárá.
Ó fi kun pé àwọn dókítà tó fi mọ́ àwọn tí wọ́n máa ń ṣe àtúnṣe ara ti ń ṣiṣẹ́ lórí ọmọ náà láti ri pé ó padà sípò.
Dókítà Kumar ní ìlera ọmọ náà kò dára rárá àmọ́ àwọn ń gbìyànjú láti dá ẹ̀mí rẹ̀ sí.
Kí ni iléeṣẹ́ ọlọ́pàá sọ?
Ọlọ́pàá kan sọ pé gbogbo ìgbìyànjú àwọn láti ṣe àwárí àwọn òbí ọmọ náà ni kò ì tíì so èso rere.
Ó ní àwọn tó wà ní ẹ̀ka ọmọdé ní ìpínlẹ̀ náà ni wọ́n ti mọ̀ nípa ọ̀rọ̀ ọmọ ọ̀hún.
Ìgbà àkọ́kọ́ kọ́ nìyíì tí wọ́n ń fi àwọn ọmọbìnrin sílẹ̀ láti pawọ́n ní Shahjahanpur, India.
Lọ́dún 2019, BBC kọ ìròyìn nípa ọmọ ọwọ́ kan tí wọ́n sin láàyè sínú ìkòkò kan. Lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ díẹ̀ nílé ìwòsàn, àwọn dókítà ní ọmọ náà yè.
India wà lára àwọn orílẹ̀ èdè tí àwọn obìnrin ti máa ń kojú ìdẹ́yẹsí jùlọ ní àgbáyé, nítorí bí wọ́n ṣe máa ń rí àwọn ọmọ obìnrin bíi èyí tó máa ń gba owó lọ pàápàá láàárín àwọn tálákà.
Àwọn tó ń pè fún àyípadà bí wọ́n ṣe máa ń gbé ọmọkùnrin gẹ̀gẹ̀ ju obìnrin lọ túmọ̀ sí pé ọ̀pọ̀ ọmọbìnrin ni kìí ju oyún inú lọ tàbí kí wọ́n wà ní ọmọdé kí wọ́n tó jáde láyé.











