Ìdí tí àwọn obìnrin fi má n ní ààrùn UTI ju ọkùnrin lọ, àti bí wọ́n ṣe le dènà rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Getty Images
- Author, Rebecca Thorn
- Role, Global Health
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5
Njẹ o ti ṣe ọ ri, ti o gbiyanju lati ṣe tọ, amọ ti nnkankan ko jade? Tabi oju ara ma n ta ọ ti o ba tọ? O ṣe e ṣe ki awọn nnkan to n ṣẹlẹ jẹ apẹẹrẹ aarun ti wọn n pe ni Urinary Tract Infection (UTI).
Ni agbaye, o to irinwo miliọnu eeyan ti yoo ni UTI lọdọọdun.
Bo tilẹ jẹ pe tọkunrin-tobinrin, ati ọmọde ni aarun naa ma n mu, o wọpọ laaarin awọn obinrin. Ilaji awọn obinrin to wa l'aye ni yoo ni iriri UTI lasiko kan ninu igbeaye wọn.
Lootọ lo jẹ ọkan lara awọn aarun to gbajumọ ju l'agbaye, ṣugbọn ibeere ti ọpọ n beere ni pe, bawo la ṣe le ri i daju pe iwosan to peye wa fun UTI, paapaa lasiko yii ti awọn ailera kan n kọ oogun.
A ba awọn onimọ nipa ilera sọrọ lati wadii awọn nnkan to yẹ ki o mọ nipa aarun yii, ati bi o ṣe le dena rẹ.
Ki lo n fa UTI?
UTI jẹ aarun to m an ba ọpa to n gbe itọ jade ninu ara eniyan, urethra, tabi ile itọ funra rẹ, to fi mọ kindinrin, ja.
Kokoro aifojuri ti wọn n pe ni bacteria lo ma n fa a . Eyi ma n waye nigba ti kokoro aifojuri naa ba gba inu urethra wọ ibi ti itọ ti n jade. Ni ọpọ igba, kokoro yii - fun apẹẹrẹ, eyi ti wọn n pe ni E.coli - ma n jẹyọ lati ara ile igbẹ tabi tosi rẹ ninu ara.
Awọn agbalagba obinrin ati ọmọdebinrin tun ma n wa ninu ewu lati ni aarun yii, lasiko ti eroja omoonu oestrogen ba dinku lara wọn.
Omoonu yii lo ma n ṣe akoso ilera pipeye fun oju ara, eyi to tumọ si pe ti adinku ba de ba a, iru ẹni naa wa ninu ewu aarun.
Awọn apẹẹrẹ aarun UTI
Apẹẹrẹ ti UTI ma n mu jade ma n yatọ lati ara ẹnikan si ikeji, ṣugbọn eyi to wọpọ lara wọn gẹgẹ ni ileeṣẹ ilera orilẹede United Kingdom, NHS, ṣe sọ re e:
- irora tabi ki oju ara ma a ta ni lasiko ti a ba n tọ (dysuria)
- ki eeyan o ma a tọ leralera ju bo ṣe yẹ
- itọ ti irisi rẹ ṣu bi kurukuru
- ẹjẹ ninu itọ
- inu rirun nisalẹ ikun tabi irora nibi egungun ẹgbẹ
- ara gbigbona, otutu tabi ki ara o ma a gbọn
- aarẹ ara
Awọn arugbo to ba ni UTI le tun ṣakiyesi pe ihuwasi wọn yatọ, bi i ikanra tabi oju to n ṣu. Eebi tabi ki ọmọ ma a tọ sile tun le jẹ apẹẹrẹ aarun UTI.
Njẹ UTI le lọ lai lo oogun kankan si i?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Fun awọn obinrin kan, wọn o nilo lati lo oogun kankan fun itọju UTI, ara wọn yoo ṣe iwosan ara rẹ. Fun awọn obinrin mii, wọn yoo nilo oogun apakokoro. Eyi ni ohun ti Dokita Rajvinder Khasriya, to jẹ dokita agba ninu imọ nipa ilera awọn obinrin ni Whittington Hospital niluu London, sọ.
Idi ti eyi fi ribẹẹ ko ye ẹnikẹni, paapaa bi UTI ṣe jẹ ọkan lara awọn aarun ti awọn eeyan n lo antibiotics fun ju lọ.
Dokita Katherine Keenan ti ṣe iwadii ijinlẹ nipa irufẹ UTI ti oogun apakokoro kii wosan ni Ila oorun Africa, ninu eyi ti Tanzania, Kenya ati Uganda, wa.
Ilaji awọn eeyan ti wọn fi ọrọ wa lẹnu wo fun itọju, lo ni ẹda aarun ti ko gboogun, bo tilẹ jẹ pe wọn lọ sile iwosan.
Itiju ati eewọ tun le mu ki awọn obinrin o ma le ba awọn ọrẹ wọn jiroro nipa nnkan to n ṣe wọn tabi wa ọna abayọ.
Dokita Keenan sọ pe "Pupọ wọn ma n ṣe eyi nitori igbagbọ wọn ni pe, aarun ibalopọ ni UTI, tabi pe boya ololufẹ wọn lo ko o ran wọn nipa irinkurin to n rin."
O le ni ida aadọta alaisan UTI to ti la iporuru ọkan kọja bi i ipaya ati aibalẹ ọkan, gẹgẹ bi akọsilẹ Global Burden of Disease Study ṣe sọ.
Ṣe UTI le ran ẹlomii?
Bo tilẹ jẹ pe aarun to le ran ni UTI, ko le ran nipasẹ ibalopọ.
Ṣugbọn ṣa, ibalopọ le mu ki ewu ni ni aarun naa pọ, nipa fifa kokoro aifojuri lati ile igbẹ wọ ile itọ.
Ajọ NHS sọ pe o dara ki eeyan o tọ ni kete to ba ni ibalopọ, lati le fọ awọn kokoro aifojuri to le ti wọle sinu ile itọ, jade.
Fun awọn ti aarun UTI wọn ba n pada wa, awọn dokita le fun ọ ni oogun apakokoro ti wa a lo nikete lẹyin ibalopọ.
Ayẹwo wo ni wọn fi n da UTI mọ?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ayẹwo gboogi lati mọ aarun UTI ni itọ. Wọn yoo gba itọ diẹ lara alaisan fun ayẹwo, nibi ti wọn o ti ri iru kokoro aifojuri bacteria to n jade latara itọ naa lori awo ayẹwo.
Esi ayẹwo ni yoo sọ iru oogun ti dokita yoo kọ fun alaisan.
Amọ ṣa o, awọn onimọ kan sọ pe iru ayẹwo yii ti di nnkan atijọ, ti wọn si n rọ awọn dokita lati lo apẹẹrẹ ti alaisan n ni ati awọn akọsilẹ atẹyinwa nipa ilera rẹ.
Ni nnkan bi ọdun 1950 ni onimọ sayẹnsi kan, Edward Kass, ṣe agbekalẹ ayẹwo ọhun nitori akọsilẹ to ri gba lati ọdọ awọn alaboyun to ni aarun kindinrin ti wọn n pe ni pyelonephritis.
Bawo ni mo ṣe le dena UTI to kọ ti ko lọ?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Akọsilẹ wa pe ida marundinlọgbọn obinrin to ti ni aarun UTI ri, ni yoo tun pada ni: o kere tan, ẹẹmeji laaarin oṣu mẹfa, tabi ọdun mẹta. Awọn mii ma n ni ju bẹẹ lọ.
Lootọ ni awọn ẹri kan fihan pe omi eso cranberry le dena lilọ-bibọ UTI lara awọn obinrin ti kii ṣe alaboyun, amọ awọn ẹri mii tun sọ pe ko ni anfaani kankan rara.
Lati dena UTI, ajọ NHS gba awọn eeyan niyanju pe:
fọ iho igbẹ lati iwaju lọ si ẹyin ti o ba yagbẹ tan
ri i daju pe oju ara rẹ mọ́, o si gbẹ
mu ọpọlọpọ omi, ki o le ma a tọ daadaa loju mọmọ
fọ awọ to wa ni ayika oju ara rẹ pẹlu omi ṣaaju ati lẹyin ibalopọ
tọ ni kete ti o ba pari ibalopọ
ma pata ti wọn fi owu 'cotton' ṣe
Ajọ National Institute for Health and Care Excellence (NICE) ni England sọ pe oogun apakokoro antibiotics niwọn lojumọ ni ki awọn obinrin lo, lati dena ki UTI tun pada wa
Ọna abayọ miran tun ni lilo oogun kan to ma n ṣiṣẹ apakokoro, methenamine hippurateninu itọ tabi oogun to n fun ni ni eroja oestrogen.












