Lẹ́yìn ẹ̀sùn lílo oògùn olóró, ilé-ẹjọ́ dín òfin ọdún mẹ́rin tó de agbábọ́ọ̀lù, Paul Pogba, kù sí ọdún kan ààbọ̀

Oríṣun àwòrán, Getty image
Ile-ẹjọ to n gbọ ẹsun to ba rọ mọ ere idaraya, Court of Arbitration for Sport (CAS), ti din ofin ọdun mẹrin ti wọn fi de agbabọọlu ọmọ Faranse nni, Paul Pogba, ku si ọdun kan ati oṣu mẹfa bayii.
Agbẹnusọ kan lati kootu naa lo fidi eyi mulẹ lọjọ Ẹti, ọjọ kẹrin, oṣu kẹwaa, ọdun 2024.
‘’Mo le fi idi adinku yii mulẹ, o ti dinku si ọdun kan aabọ bayii, bẹrẹ lati ọjọ kọkanla, oṣu Kẹsan-an ọdun 2023.’’
Bẹẹ ni agbẹnusọ CAS naa sọ fun AFP.
Tẹ o ba gbagbe, oṣu kẹjọ ọdun 2023 ni ayẹwo fi han pe Paul Pogba lo oogun oloro amarayagaga.
Eyi ṣẹlẹ ninu idije kan to waye laarin Juventus ati Udinese.
Oṣu kẹsan-an ọdun naa ni wọn fofin de e latari iṣẹlẹ yii.
Nigba to si di oṣu keji ọdun to tẹle e, igbimọ Italian National Anti-Doping Tribunal, fi ofin de Paul Pogba fun ọdun mẹrin.
Kí ló fa àdínkù òfin fun Pogba?
Gẹgẹ bi awọn aṣoju agbabọọlu yii ṣe sọ, wọn ni ki i ṣe pe o mọ ọn mọ lo oogun testosterone to han ninu ẹjẹ rẹ lẹyin ayẹwo naa.
Wọn ni dokita kan l’America lo fun un ni oogun to n ṣafikun ounjẹ lara eeyan, ati pe inu oogun naa ni egbogi ọhun ti wa.
Lẹyin ti wọn kede fifi ofin de e, Pogba kọ ọrọ kan si oju opo Instagram rẹ, nibi to ti sọ pe oun ko figba kankan lo oogun oloro ri.
’’ Inu mi bajẹ, o ya mi lẹnu o si ba mi lọkan jẹ, pe gbogbo ohun ti mo ko jọ lẹnu iṣẹ mi ni wọn ti gba lọwọ mi’’
Bayii ni Paul Pogba kọ lasiko idaamu rẹ naa.
Ṣugbọn ni bayii ti adinku ti ba akoko ti ofin de e, ko kọ ohunkohun si oju opo rẹ, bi ko ṣe aworan ẹsẹ meji to wọ bata agbabọọlu, ti wọn si kọ PP to bẹrẹ orukọ rẹ si.














