Òṣìṣẹ́ FIRS mẹ́rin àti àwọn èèyàn míràn kú nínú ìjàmbá iná ilé gogoro tó jó l'Ekoo

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Latari ina to jo nile alaja mẹjọ kan to wa lopopona Broad, Erekuṣu Eko, lọjọ Iṣẹgun ọsẹ yii, iroyin sọ pe ko din ni eeyan mẹwaa to ba iṣẹlẹ naa lọ.
Awọn to di oloogbe ninu ina to ṣẹyọ ni aja kẹta ati ikẹrin ile ti a mọ si Afriland Towers naa jẹ oṣiṣẹ ileeṣẹ United Capital to n ri si idokowo, ati ti ajọ Federal Inland Revenue Service (FIRS).
Bo tilẹ jẹ pe BBC ko le fidi iye eeyan to ku mulẹ, iroyin sọ pe eeyan mẹfa ti wọn jẹ oṣiṣẹ ileeṣẹ United Capital ni ina yii pa, ajọ FIRS to n pawo wọle lorilẹede yii naa si fidi ẹ mulẹ nirọlẹ Ọjọru pe, mẹrin ninu awọn oṣiṣẹ oun ni ina ọhun pa.
Atẹjade ibanikẹdun ti ajọ yii fi sita, ṣalaye pe àjà kẹfa ati ikeje ile naa ni awọn oṣiṣẹ ẹka FIRS n lo fun ọfiisi.
Wọn ni nigba ti olobo ta awọn pe ina n jo nibẹ, kia ni awọn kan si ikọ alaabo ati ajọ panapana.
Wọn fi kun un pe ṣugbọn nigba ti ikọ alaabo naa yoo fi debẹ, eefin ina ti gba gbogbo ile naa kan.
Awọn ileeṣẹ naa fi ibanujẹ ọkan wọn han, wọn si kẹdun iku awọn eeyan to pade iku ojiji nibi iṣẹ wọn.
FIRS kede pe oun yoo duro ti ẹbi awọn oṣiṣẹ to padanu ẹmi, awọn yoo si tun so okun aabo le ni gbogbo ẹka ileeṣẹ naa.
Àwọn panápaná dóòlà àwọn kan

Oríṣun àwòrán, @MUBARAK_YSHAU/X
Tẹ o ba gbagbe, nnkan bii aago kan ọsan ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹrindinlogun oṣu Kẹsan-an ni ina yii ṣẹyọ, ti eefin to n ru jade nibẹ si jẹ kawọn eeyan mọ pe ina ti n jo.
Ẹrọ amunawa Inverter ni a gbọ pe o fa ina ọhun, ninu yara ti ẹrọ naa wa ni isalẹ ile.
Bi ina ọhun ṣe n jo ni awọn eeyan kan n gbiyanju lati gba oju ferese jade, wọn n fo lati oke ferese ile giga naa si isalẹ.
Awọn oṣiṣẹ ajọ panapana ipinlẹ Eko ati awọn eleto pajawiri miran pada debẹ, wọn si ri eeyan mẹsan-an doola bi ina naa ṣe n jo lọwọ.
Atẹjade ti ajọ panapana ipinlẹ Eko fi sita lọjọ Iṣẹgun naa ṣalaye pe marun-un ninu awọn eeyan ti ijamba naa kan ji pada saye.
Wọn ni awọn mẹrin ko mira bi wọn ṣe gbiyanju lati ji wọn to lasiko naa.
"Eeyan mẹsan-an la doola, awọn marun-un ti ji pada saye, ọpọ lo si raaye jade lai fi ara pa, iyanju si n lọ lati ri i pe awọn mẹrin laju."
Bẹẹ ni atẹjade ajọ panapana ipinlẹ Eko kede lọjọ iṣẹlẹ naa.
Iléèfowópamọ́ kan náà pàdánù òṣìṣẹ́
Yatọ si awọn ileeṣẹ meji to kede pe awọn padanu oṣiṣẹ yii, awọn oṣiṣẹ ileefowopamọ UBA kan ni iroyin tun sọ pe wọn ku ninu iṣẹlẹ naa pẹlu.
Ọrọ ibanikẹdun ti Olori ileefowopamọ naa, Tony Elumelu, fi si oju opo X rẹ, fi han pe ileeṣẹ naa padanu oṣiṣẹ, bo tilẹ jẹ pe wọn ko sọ iye eeyan to ku.
Ijamba ina to ṣẹ lọsan-an gangan yii ti mu ọpọ eeyan maa sọ pe ewu wa ninu awọn ile nla alaja gogoro ti wọn fi n ṣe ọfiisi, paapaa nigba ti ko ba si eto fun iṣẹlẹ pajawiri bi eyi, to si n mu ẹmi alaiṣẹ lọ.














