Mọ̀ nípa aṣọ alárànbarà tí wọ́n ń rán ní Naijiria, ti America n rà wìtìwìtì
Ile ni adiẹ ko ti niyi.
Eyi lo ṣe rẹgi pẹlu bi oriṣi aṣọ kan ti wọn n ran lati orilẹede Naijiria nibi, ti wọn si n ko lọ si oke okun, paapaa ilẹ America, ṣe di ohun ti wọn tẹwọ gba gidi lorilẹede naa
Awọn aṣọ kaba alaranbara ti wọn n ran lọna igbalode naa ni a mọ si aṣọ ti wọn n wọ fun 'Prom' - eyi ni ayẹyẹ ọlọdọọdun lẹyin ipari saa ikẹkọọ jade fun awọn akẹkọọ.
Ọmọ orilẹede Naijiria kan to jẹ aranṣọ fun purọọmu, Shakirat Arigbabu, ṣalaye pe oun ran aṣọ naa lọpọ yanturu, wọn si ra a pupọ nibi ayẹyẹ purọọmu to kọja yii l'America.
Shakirat sọ pe o le ni ẹgbẹrun kan kaba ti awọn ran, o fẹrẹ to ẹgbẹrun kan ati ẹẹdẹgbẹta aṣọ kaba (1,500) ti awọn ran.
Ọmọbinrin naa sọ pe ida mejidinlọgọrun-un (98%) ninu aṣọ naa ni awọn fi ranṣẹ si ilẹ America ti wọn ti ra a.
O ni ọdọọdun ni iye ti awọn n ta soke okun n le si i. Ọpọ ọdọ lo ti yan aṣọ purọọmu Naijiria laayo bayii ju ti ibikibi lagbaaye lọ.
Ọkan lara awọn ọmọbinrin ilẹ America to ni anfaani lati ri aṣọ purọọmu tiẹ gba, Nian Fisher, ṣalaye pe ori oun wu pupọ lalẹ ọjọ ti oun wọ aṣọ naa, ti ọpọ eeyan si n sọ bi oun ṣe rẹwa to ninu rẹ, ti wọn n fi oun we ọmọbabinrin.
Tonya Haddly, iya to bi Nian, naa fidi rẹ mulẹ pe ojulowo ni aṣọ purọọmu to ti Naijiria wa, o ni nigba ti oun ti ri i bo ṣe rẹwa to si daa to l'oun ti mọ pe ki i ṣe ilẹ America ni wọn ti ran an.

Bakan naa ni Brianna LeDoux, ọmọbinrin ilẹ America kan ṣalaye pe, gbogbo bi oun ṣe maa n fẹ ki aṣọ purọọmu oun ri ni ti Naijiria ri, bẹrẹ lati ilẹkẹ ti wọn maa n to o mọ debi ilana ti wọn fi n ran kaba naa ati bo ṣe maa n ṣe rẹgi lara.
O ni ko si ibomiran ti iru aṣọ bẹẹ ti n wa ju Naijiria lọ.
Lati ran aṣọ purọọmu yii, ko si ṣọọbu kan ti wọn le ti ran an, afi bi wọn ba ri i loju opo ayelujara bii Tiktok tabi Instagram, nigba naa ni wọn yoo si beere ibi to ti wa, ti wọn yoo ri i pe Naijiria ni.
Lori idi ti wọn fi ranṣẹ lati ra aṣọ lati America, Arigbabu sọ pe wọn mọ pe awọn ọlọpọlọ pipe aranṣọ pọ ni Naijiria daadaa ni, won si nigbagbọ ninu wọn.





