Ọmọ Ilesa ni mi àmọ́ ahọ́n ẹ̀yà Igbo tí mo fi ń kọrin lórí Tiktok ni mo ṣe ń jẹ́ Sister Agnes - Agnes Bada
Gbajumọ alawada kan loju opo Tik Tok, arabinrin Agnes Bada, ẹni ti ọpọ eeyan mọ si Sister Agnes ti salaye nipa igbe aye rẹ.
Lasiko to n ba BBC sọrọ, Sister Agnes ni ori ayelujara lo sọ oun di gbajumọ bi o tilẹ jẹ pe oun ko ni lero bẹẹ.
O salaye lati kekere ati bi oun se n dagba ni oun fẹran lati maa kọrin pẹlu ahọn ẹya Igbo.
O wa sisọ loju rẹ pe ọmọ bibi ilu Ilesa ni oun jẹ to wa nilẹ Yoruba amọ ọpọ eeyan lo maa n ro pe ẹya Igbo ni oun.

"Ọdun 2020, mo gbe orin akọkọ "My daddy, my Valentine" sita, to si jẹ itẹwọgba fun ọpọlọpọ eeyan"
"Nigba t imo ba kọrin pẹlu ahọn ẹya Igbo, gbogbo eeyan yoo bu sẹrin, ti mama mi yoo si maa se iwuri fun mi pe ki n gbe orin naa sori ayelujara.
Mo kọkọ maa n yari fun wọn pe mo fẹ se bii obinrin to rẹwa, to si ni itiju nitori naa, n ko fẹ gbe ara mi sori ayelujara.
Amọ nigba to di ọdun 2020, mo gbe orin akọkọ "My daddy, my Valentine" sita, to si jẹ itẹwọgba fun ọpọlọpọ eeyan."
Sister Agnes ni lati igba naa ni awọn ohun ti oun n gbe sori ayelujara ti n di itẹwọgba, ti oun si di gbajumọ lori TikTok.
"Ohun to wu mi se lati ibẹrẹ aye mi kọ ni eleyi amọ bi mo se n gbe orin Igbo soju ayelujara ni awọn eeyan n kọ atẹjisẹ ransẹ si mi.
Wọn yoo ni orin mi mu idunnu wa fun awọn ti ọkan wọn ti daru, eyi si maa n mu inu mi dun, to si n se koriya fun mi lati tẹsiwaju."






