Ọlọ́run ló ní kí n má lọ ṣọ́ọ̀ṣì mọ́, mi ò sì le è dí ọmọ mi tó bá fẹ́ di mùsùlùmí lọ́wọ́ - Yemi Solade

Oríṣun àwòrán, realyemisolade/Instagram
Gbajugbaja oṣere Yoruba Nollywood, Yemi Solade, ti sọ pe oun ko lọ sile ijọsin mọ bo tilẹ jẹ pe Kristẹni ni oun i ṣe.
Ilumọọka oṣere ori itage naa sọrọ yii ninu ifọrọwanilẹnuwo to ṣe eyi to wa loju opo YouTube Glitch Africa Studios TV.
Ọgbẹni Solade ni oun dẹkun lilọ sile ijọsin lẹyin ọrọ ti Ọlọrun ba oun sọ.
"Pasitọ kan ni ki n ma sere ori itage mọ lọjọ isinmi, mo kọ eti ikun si ikilọ ọhun tori lara iṣẹ ti mo ba ṣe lọjọ ''Sunday'', ni mo ti n rowo san idamẹwa"
Yemi Solade tẹsiwaju pe ''Ọlọrun lo sọ fun mi pe ki n ma lọ si ṣọọṣi mọ fun anfaani ilera ati ibalẹ ọkan mi.''
Agba oṣere naa ṣalaye siwaju si pe pasitọ kan tun gba oun ni imọran wi pe, ki oun mase kopa ninu ere ori itage mọ lojọ isinmi, ti i ṣe ọjọ Ọluwa.
Amọ, Solade ni oun kọ eti ikun si ikilọ pasitọ ọhun tori lara iṣẹ toun ba ṣe lọjọ ''Sunday'', naa loun ti n rowo san idamẹwaa.
Solade ni ''wọn sọ fun mi pe ki n jẹ kawọn olootu ere mọ pe mi o ni ma ṣere itage mọ lọjọ ''Sunday''.
Amọ, mo da a pada fun pasitọ to sọrọ naa pe, lara iru iṣẹ ti mo n ṣe lọjọ isinmi ni mo ti n rowo san idamẹwa.''
Agba oṣere naa fikun ọrọ rẹ pe, Bibeli ko sọ pe kawọn onigbagbọ maa korajọ pọ ninu ṣoọṣi jọsin ni gbogbo ọjọ isinmi.
Ọrọ tọ sọ naa si ti di awuyewuye papaa julọ lori ayelujara eyi ti ọpọ eeyan n sọ ero wọn lori rẹ.
Mi o le di ọmọ mi to ba fẹ di musulumi lọwọ - Solade
Agba oṣere Solade tun sọ pe oun ko ni di ọmọ oun to ba fẹ di musulumi lọna lati ṣe bẹẹ.
O ni oun maa n fawọn ẹbi oun lanfaani lati sọ nnkan to wa lọkan wọn ati lati ṣe nnkan to ba wu wọn.
O ni iyawo oun naa ko lọ si ile ijọsin mọ.
Ọgbẹni Solade ni oriṣiiriṣii iyọlẹnu loun maa n ni nigba toun si maa n lọ ṣọọṣi gan an.
''Oniruuru ẹgbẹ ni mo maa n wa, bakan naa, ni wọn maa n pe mi si oriṣiiriṣii ipade.
Mo wa wo o gan an wi pe, nigba wo ni mo fẹ raye lati ṣiṣẹ oojọ mi nibi ti mo ti n rowo tọju ẹbi mi,'' Solade lo sọ bẹẹ.

Oríṣun àwòrán, realyemisolade/Instagram
Ta ni Yemi Solade?
Yẹmí Sóladé tí wọ́n bí ní Ọjọ́ kọkànlélọ̀gbọ̀n oṣù kìíní ọdún 1960, jẹ́ gbajúmọ̀ àti arẹwà ọmọkùnrin òṣèré sinimá àgbéléwò, to si jẹ́ ọmọ bíbí orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.
Wọ́n bí Yẹmí ṣóladé lọ́jọ́ kọkànlélọ̀gbọ̀n oṣù kìíní ọdún 1960 sí ìlú Èkó lorílẹ̀-èdè Nàìjíríà .
Nígbà èwe rẹ̀, ó kàwé ní St. Thomas Aquilla Primary School àti Birch Freeman Secondary school, ní Sùúrùlélrè, ní ìpínlẹ̀ Èkó.
Lẹ́yìn èyí, Yemi fò gẹ̀ẹ̀rẹ̀, ó dèrọ̀ ìlú Ọba níbi tí ó ti tẹ̀ síwájú nínú ẹ̀kọ́ rẹx,̀ tí ó sì gba ìwé ẹ̀rí A Level ni ilé-ìwé gíga Tyhill College ní ìlú Coventry lorílẹ̀ èdè Gẹ̀ẹ́sì.
Lẹ́yìn èyí, ó tún padà sí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, ó sì n tẹ̀ síwájú nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní Oyo State College of Arts and Science, OSCAS.
O tún kẹ́kọ̀ọ́ gboyè sí i nínú iṣẹ́ tíátà ní Obafemi Awolowo University (OAU), ní Ilé-Ifẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun.
O sinru ilu NYSC rẹ nipinlẹ Borno, o si sisẹ olukọ diẹ nipinlẹ Kaduna.
Nigba to pada wa sile lo bẹrẹ isẹ ere tiata pẹlu sinima kan ti wọn pe ni Oju inu (Insight),
Gbajumọ osere naa ti wa se ọpọ sinima lẹyin eyi, to si di gbajumọ osere tiata.
Lara awọn ere itage ati sinima to se ni Shadows, Thunderbolt, Lady in the forest, Madam Dearest, Mr. Gabriel, Super story ati bẹẹ bẹẹ lọ.















