"Boko Haram lé mi kúrò nílé, ọwọ́ ẹ̀kún omi ni mo bọ́ sí ní àjò, kò sí ilé tàbí dúkìá kankan mọ́"

Aworan awọn ile ati igi ti omi ti bo mọlẹ, omi to pọn fun idọti. Orule ile nikan lo ku ti eeyan n ri ninu aworan yii, ati awọn igi to ti wọmi.

Oríṣun àwòrán, Audu Marte/AFP/Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ajọ UN, ṣapejuwe ẹkun omi Borno naa bii eyi to buru ju ninu iru iṣẹlẹ bẹẹ to ti waye lọgbọn ọdun sẹyin.
    • Author, Chris Ewokor
    • Role, BBC Africa
    • Reporting from, Maiduguri
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 9

Iṣẹlẹ ẹkun omi tuntun tun ti n rugbo bọ bayii ni Maiduguri, ilu to wa ni apa Ariwa Ila-Oorun Naijiria, iyẹn lẹyin ọdun kan ti ojo rọ titi nibẹ ti ko si tete da, eyi to mu adagun odo (dam) kan kun akunfaya, ti omi si gba gbogbo agbegbe Maiduguri kan.

Inu ipaya ni ọpọ olugbe Maiduguri ti ko ti i bọ ninu idaamu ẹkun omi ọdun to kọja tun wa bayii, wọn n ro o pe o ṣee ṣe ki omi tun kun bii ti ọdun to lọ.

O kere tan, eeyan mẹtadinlogoji (37 ) lo ku ninu ẹkun omi to waye kọja naa, miliọnu meji eeyan lo si fi ile wọn silẹ lẹyin ti iparun de ba ile ati ọna titi kan okoowo, oko ti wọn ti n ṣe ọgbin ati gbogbo dukia ti wọn ni.

Ninu wahala naa ni obinrin kan, Sa'adatu Dahiru, ẹni ọdun mejilelogoji (42), padanu ọmọ rẹ ọkunrin ọmọ ọdun meji si.

"O ku latari ebi ati iba to ṣe e lasiko ẹkun omi naa. A ko ni ounjẹ gidi, ko si oogun lati lo, ko tun si ibugbe alaafia lati gbe."

Sa' adatu ṣalaye fun BBC nipa bi awọn ọmọ rẹ ṣe sare jade pẹlu omije loju laaarin oru, ti wọn ko si le ko ẹru pupọ ju aṣọ diẹ ti wọn ri ko lọ, gbogbo ohun to ku pata ni wọn fi silẹ lai le mu, wọn sa asala fun ẹmi wọn na.

Nipa owo iranwọ, obinrin yii sọ pe oun ri ẹgbẹrun mẹwaa naira gba gẹgẹ bii owo iranwọ nigba ti omiyale naa ṣẹlẹ.

Ṣugbọn ṣaa, Sa' adatu to bimọ mẹfa, sọ pe oun ko ri iranlọwọ kankan gba mọ lati ọdọ ijọba.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

"Latigba naa, ko si adehun kankan ti wọn muṣẹ fun wa mọ lati ọdọ ijọba. A ṣi n reti wọn nibi, a n jiya wa lọ."

Ninu alaye tirẹ, ijọba ipinlẹ Borno sọ pe oun nawọ iranwọ si awọn agbegbe ti omiyale koju naa.

O tọka awọn ibudo aanu, ipese ounjẹ ati owo to da silẹ lati ṣẹgun idaamu awọn eeyan naa.

Pataki julọ, ijọba ti bẹrẹ si i kọ adagun odo Alau to ya naa, to si fa omiyale ọhun, eyi to wa ni igberiko Maiduguri.

Ọdun 1986 ni wọn bẹrẹ si i kọ adagun odo naa, ajọ Chad Basin Development Authority (CBDA), ileeṣẹ ijọba Naijiria lo si n moju to o.

Ṣugbọn ikọlu Boko Haram to ti le lọdun mẹwaa to ti n waye lagbegbe naa ko jẹ ko rọrun fun ijọba lati mojuto dam ọhun, gẹgẹ bi Mohammed Shettima, olori lẹka imọ ẹrọ ileeṣẹ naa ṣe ṣalaye fun BBC.

"Ibi ẹnu ibode igbo Sambisa ni adagun odo naa wa, bii kilomita mẹrin si ibuba awọn ikọ alakatakiti ẹsin naa ni .

"Odo naa ti dibajẹ nitori ai si abojuto, nigba ti ojo nla rọ lọdun to kọja, ibudo adagun omi naa ya, o si n tu omi to lagbara jade si igboro ilu."

Bẹẹ ni Mohammed Shettima ṣalaye.

Loṣu Kẹjọ, wọn pa ṣọja meji si itosi adagun odo naa, ẹṣọ alaabo mẹrin ti wọn fura si pe awọn alakatakiti ẹlẹsin Islam naa lo pa wọn si padanu ẹmi wọn pẹlu.

Wọn kò fu wá lára rárá, wọ́n dé bíi olè lóru ni

Maryam Jidda ree, o jokoo, o ka ọwọ rẹ mejeeji sori ara wọn pẹlu aṣọ pupa to wọ, o n wo orere.

Oríṣun àwòrán, Gift Ufuoma / BBC

Àkọlé àwòrán, Iya yii, Maryam Jidda, ko ti i ni ibugbe kankan lati ọdun kan sẹyin ti iṣẹlẹ omiyale naa ti waye.

Ọkan lara awọn eeyan ti ẹkun omi da laamu, to si ni ọwọ awọn alakatakiti ẹsin Islam naa ninu ni iya agba kan, Maryam Jidda.

Niṣe lo sa kuro ni ilu abinibi rẹ ti i ṣe Damboa, pẹlu ọmọ rẹ obinrin ati ọmọ-ọmọ meji, nigba ti awọn Boko Haram de ba wọn lalejo lọdun mẹrin sẹyin.

"Wọn ko tiẹ kilọ fun wa rara, wọn de bii ole loru ni." Iya naa lo sọ bẹẹ fun BBC.

Lẹyin to sa de Maiduguri, ero ọkan rẹ ni pe oun ti de ibi aabo ati isadi alaafia. Nigba naa ni ikun omi tun de, to tun le Maryam Jidda ati idile rẹ jade lẹẹkeji.

Nigba to n ba ikọ iroyin BBC sọrọ, Maryam jokoo lori afọku okuta kan, eyi to ṣẹku lara ile rẹ ti omi bajẹ, O wọ aṣọ jẹlibaba pupa to bolẹ dẹdẹ.

Ibanujẹ han loju iya ẹni ọdun mejilelaadọrin (72) naa, o han pe oju rẹ ti ri to ninu aye.

"Mo duro laaarin omi to mu mi de ibadi, mo n sunkun." Jidda lo ṣalaye bẹẹ nigba to n sọ nipa alagbalugbu omi to wọ ile rẹ, to si sọ igbesi aye rẹ di ohun ti ko fẹ.

Ni bayii, ibi kan to kan n fi ori pamọ si lo n gbe, nibi ti ko si ounjẹ ati omi to ṣee lo.

Ki i ṣe pe Maryam padanu ile rẹ nikan kọ, bẹẹ lo padanu awọn aworan mọlẹbi ati dukia to fi le maa ranti ẹbi ọhun.

Sa'adatu Dahiru fi ara ti okuta kan to ṣẹku lara ile to dawo, o lo ibori alawọ elese aluko.

Oríṣun àwòrán, Gift Ufuoma / BBC

Àkọlé àwòrán, Sa'adatu Dahiru ree, o padanu ọmọ rẹ ọkunrin ọmọ ọdun meji sinu ẹkun omi naa.

''Mi ò rílé gbé, kò sí iṣẹ́, kò sí oúnjẹ''

Titi di asiko yii ti ọdun kan ti pe to si ti kọja lẹyin iṣẹlẹ yii, ọpọ olugbe agbegbe naa ni wọn ṣi n wọsun kiri lai ni ile gboogi ti wọn le pada si.

Bakan naa ni ẹkun omi yii daamu awọn ọdọ naa, ọpọ wọn ko le lọ sileewe mọ, awọn ti wọn n ṣiṣẹ tẹlẹ ko si ribi kankan lọ mọ bayii.

Ọkan lara wọn, Ali Kadau, ẹni ọdun mọkanlelogun, (21) sọ fun BBC pe ẹkun omi naa gba gbogbo nnkan pata lọwọ oun.

"Ki omiyale too ṣẹlẹ, mo n dọgbọn si ọrọ ara mi. Mi o kawe pupọ, ṣugbọn mo niṣẹ ọwọ diẹ, mo maa n ran wọn lọwọ ni ṣọọbu mẹkaniiki kan, bii ki n ba wọn ṣe taya, ki n ba wọn ra ohun ti wọn ba nilo."

Gbogbo eyi ni ko si mọ gẹgẹ bo ṣe wi lẹyin iṣẹlẹ omiyale naa bi Kadau ṣe ṣalaye lori aga to ti kan to jokoo le, to si n le ọpọ eṣinṣin to n kun un danu ninu oorun ganrin-ganrin to n mu ni Maiduguri.

O kuku ṣalaye pe ojo naa ko yatọ si bi ojo ṣe maa n bẹrẹ wẹrẹwẹrẹ, afi ti pe niṣe lo kó ti ko da. Nigba naa lo di pe omi bẹrẹ si i ya wọle, kawọn si too ṣẹju pẹẹ, agbegbe Gwange to n gbe ti wa labẹ omi.

"Ile tiwa to jẹ pe amọ ni wọn fi kọ ọ ko le gba omi naa duro. Awọn ogiri bẹrẹ si i wo.Omi n wọle, o n gbe gbogbo nnkan lọ. Aṣọ wa, ẹni, ounjẹ titi kan foonu mi ti mo n lo lati fi ba awọn onibaara mi sọrọ, gbogbo ẹ lo ba omi lọ" Bẹẹ ni Kadau fi ibanujẹ ṣalaye.

Ọjọ mẹta ni mọlebi rẹ fi sun sita gbangba ki wọn too ri ibi kan nitosi ileewe kan, ibẹ ni wọn sọ di ibugbe ti wọn n gbe. Ko si aṣiri wọn kan to bo, gbogbo oju lo n ri wọn pẹlu gbogbo ohun ti wọn ba n ṣe nita gbangba ti wọn n gbe, ko si idẹrun, kaluku wulẹ n dubulẹ kiri ibi ti wọn ba ri ni.

Ṣọọbu mẹkaniiki to ti ri nnkan jẹ tẹlẹ naa ti faragba wahala, omi ti ba awọn irinṣẹ ati ẹrọ wọn jẹ.

"Ni bayii, mo kan n jokoo kiri ni, ko si iṣẹ, ko si ileewe, ko sowo lati bẹrẹ ohunkohun. Nigba mi-in,mo maa ba wọn ti kẹkẹ (wheelbarrows) laaarin ọja ni ki n too le jẹun. Awọn ọjọ mi-in si wa ti ma a kan jokoo lasan, ti mi o ni i ri nnkan kan ṣe ju ki n maa ronu lọ."

Bẹẹ ni Ali Kadau wi.

Ìjọba Borno sọ̀rọ̀

Ninu ọrọ rẹ, Gomina ipinlẹ Borno; Babagana Umaru Zulum, ṣapejuwe ẹkun omi naa bii akọ iṣẹ, paapaa bi a ba wo idaamu ati ikọlu to n koju ipinlẹ yii lati ọdun mẹrindinlogun sẹyin.

"A gbe igbimọ kan kalẹ ti a ya iṣẹ fun lọtọ, wọn ṣiṣẹ takuntakun lati ri i pe awọn idile to kan ri iranlọwọ to tọ si wọn gba, titi kan ibugbe ati ounjẹ."

Gẹgẹ bi gomina ṣe wi, ko rọrun lati wa ibugbe fun eeyan miliọnu meji ni Maiduguri, ilu kan to ti gbalejo eeyan to le ni miliọnu kan ti ogun le de tẹlẹ, ogun awọn akatakiti ẹsin Islam ati awọn ikọlu mi-in ni Gomina Zulum pe e.

"Ohun to ṣe koko fun ijọba ni lati dẹkun omi to n ya layaju naa, eyi ti a sẹ ti gbogbo ilu ko fi ba omi lọ. A ri eyi ṣe nipasẹ lilana fun omi ti a si tun ṣe koto idaminu tuntun."

Gomina lo sọ bẹẹ.

Igbimọ to jabọ iṣẹlẹ naa ṣalaye pe owo ti iye rẹ jẹ 28.2bn naira ($18m; £13m) ni awọn ko jọ lati ọdọ ijọba ipinlẹ ati ijọba apapọ, pẹlu iranlọwọ lati ọdọ awọn ajọ alaanu bii UN, ẹka to n ri si ọrọ awọn alairilegbe, ati ajọ olounjẹ agbaye (World Food Programme).

Ijọba Borno sọ pe oun pin owo to nilaari fun idile to ju 101,330, pẹlu ounjẹ ati awọn nnkan mi-in.

Wọn fi kun un pe awọn ran awọn oniṣowo to le ni ẹgbẹrun meje ( 7,000) lọwọ, bẹẹ lawọn si ṣe fun awọn ile ijọsin ati awọn ileewe aladaani.

Aworan yii ṣafihan ilẹ to tobi gbayawu, nibi ti adagun odo to ya naa wa tẹlẹ.

Oríṣun àwòrán, Gift Ufuoma / BBC

Àkọlé àwòrán, Nibi yii ni adagun odo naa wa tẹlẹ.

''A ṣì nílò 61bn sí i''

Lojuna ati ṣe atunṣe awọn ibi to bajẹ gẹgẹ bi wọn ṣe wi, ijọba Borno n beere fun alekun owo iranwọ ti i ṣe 61bn naira, lati kọ awọn nnkan amayedẹrun to ti bajẹ. Awọn bii afara, oju ọna, eto ibaraẹnisọrọ ati ileewosan.

Ṣugbọn ṣaa, ewu n bẹ loko Longẹ. Ibẹru wa lọkan awọn naa, pe boya wọn ko ni i buwọ lu owo nla yii, afi bi idaamu nla mi-in ba tun waye.

Wọn wulẹ ti buwọ lu awọn owo kan tẹlẹ fun atunṣe ati igbedide awọn kanga igbalode ti a mọ si 'borehole', kaakiri Maiduguri ati agbegbe rẹ, lati ṣẹgun iṣoro ai si omi mọ ti ẹkun omi naa da silẹ.

Bakan naa, bi asiko ojo ṣe n kasẹ nilẹ loṣu Kẹsan-an yii, ibeere ti awọn eeyan bii Abilekọ Dahiru n beere ni pe: "Bawo ni mo ṣe fẹẹ bẹrẹ pada nigba ti mi o ni nnkan kan?"

Iya agba, Maryam Jidda ṣi wa ninu ibanujẹ. Ọmọ mẹwaa lo bi, mẹta pere lo ṣẹku.

"Ko sohun to ṣẹku mọ, iranti wọn ati ibanujẹ nikan ni."

Bẹẹ ni iya naa wi lai ni ireti.