Ìtàkùn iná mọ̀nàmọ́ná Nàìjíríà tún dákú lójijì, kí ló fà á?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ina ọna tun ku pii mọ awọn ọmọ Naijiria lori lọjọru lẹyin ti itakun ina mọnamọna apapọ tun kọ'ṣẹ silẹ.
Nnkan bii agogo mọkanla owurọ ni itakun ina mọnamọna naa daku, gẹgẹ bi awọn ileeṣẹ mọnamọna lorilẹede Naijiria ṣe sọ.
Ileesẹ apinna mọnamọna Eko Electricity Company ati ti Abuja Electricity Distribution company ṣalaye ọrọ yii loju opo ayelujara X wọn.
AEDC ṣalaye pe idakẹjẹ itakun ina mọnamọna naa waye l'awọn agbegbe kan nilu Abuja ni nnkan bii agogo mejila ku iṣẹju mẹrindinlọgbọn Ọjọru.
Ileeṣẹ mọnamọna naa sọ pe awọn ti n ṣiṣẹ lati rii pe ina mọnamọna pada.
"Ẹ jọwọ, idakureku ina mọnamọna to waye lọwọ yii ṣẹlẹ nitori aisi ina mọnamọna lati ori itakun ina mọnamọna apapọ ni nnkan bii agogo mọkanla kọja iṣẹju mẹtalelogun owurọ oni, eyi si ṣakoba fun ipese ina mọnamọna kaakuri agbegbe wa" ni alaye ti wọn ṣe sinu atẹjade ti wọn fi sita.
O wa fi da awọn onibara rẹ loju pe "iṣẹ nlọ ni ifọwọsowọpọ pẹlu awọn to yẹ lati da ina pada lẹyẹ o ṣọka ti itakun ina mọnamọna naa ba ti pada ṣiṣẹ".
Ileeṣẹ apinna EKEDC ni tirẹ sọ pe awọn ko tii le sọ pato ohun gan to fa a bi itakun apapô ina mọnamọna naa ṣe tun ku pii.
Opoigba ni itakun ina mọnamọna apapọ ni Naijiria ti daku laarin odun sẹyìn to si sọ awọn ọmọ Naijiria sinu okunkun, bi o tilẹ jẹ wi pe awọn alaṣẹ n sọ pe awọn n sa ipa lati koju rẹ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post














