Iná mọ̀námọ̀ná tún paná pii jákèjádò Nàìjíríà

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ina mọnamọna kaakiri Naijiria tun pana pii lọjọ Aiku pẹlu bi oju opo ipinna jakejado Naijiria ti wọn n pe ni ‘National Grid tun ṣe kọ iṣẹ silẹ.
Ni nnkan bii agogo mọkanla kọja iṣẹju mọkanlelogun lowurọ ọjọ Aiku, ọjọ kẹrin oṣu keji ọdun 2024 ni oju opo ina mọnamọna apapọ naa tun daku.
Eyi lo ṣokunfa bi ibudo ipinna ogun jakejado Naijiria ṣe pana pii.

Oríṣun àwòrán, Screencapture
Ileeṣẹ apinata Abuja Electricity Distribution fi idi eyi mulẹ ninu atẹjade kan to fi si oju opo ayelujara rẹ pe awọn irinṣẹ oju opo ipinna apapọ Naijiria, to da iṣẹ silẹ lo ṣokunfa ina mọnamọna to pana pii naa.
O ni awọn ti n ṣe iṣẹ pẹlu awọn akọṣẹmọṣẹ to yẹ lati yanju rẹ.










