Èmi ni Fẹla tuntun àsìkò yìí – Portable

Aworan Portable

Oríṣun àwòrán, Portablebaeby/Instagram

Gbajugbaja olorin takasufee nni, Habeeb Okikiọla ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si Portable ati Zazu ti sọ pe oun ni Fẹla Anikulapo-Kuti asiko yii ti aye n pokiki rẹ lọwọ.

Portable ni kii ṣe pe oun loun n deede bẹrẹ sii pe ara oun ni orukọ naa, bi ko ṣe pe awọn ololufẹ ti wọn fẹran oun ni wọn n pe oun ni Fẹla asiko yii

Ilu-mọ-ọn-ka olorin naa ti wọn tun n pe ni Ọmọlalọmi lo sọrọ yii nibi ifọrọwerọ to ṣe lori eto Bae U Barbi to pe ni Curiosity Made Me Ask.

Portable, nigba to n sọrọ, ṣalaye pe “Emi kọ ni mo fun ara mi ni orukọ ‘Ọmọ tuntun Fẹla’ yii. Awọn ololufẹ mi lo fun mi lorukọ naa.

“Ṣe ẹ mọ pe mo ni ọpọ awọn ololufẹ, awọn ololufẹ mi lo si gbe mi de ipo ti mo wa loni.

“Eeyan ni lati ni igboya, nitori pe kiniun kii bẹru lati da rin laginju.”

Bakan naa ni Portable tun sọ pe ọpọ igba loun ti sọ fawọn eeyan lati yee pe oun ni olorin takasufee to ṣẹsẹ n dide bọ, o loun ti gbajumọ.

O sọ pe igba wo loun fẹẹ dide nigba ti wọn ba n fi ojoojumọ pe oun olorin to ṣẹṣẹ n dide bọ pẹlu orukọ toun ti ni kaakiri agbaye.

Ninu ọrọ rẹ, o ni “Olorin wo lẹyin mọ to ga ju mi lọ lorileede? Emi ni ẹni ti wọn n sọrọ nipa ẹ lasiko yii. Olorin to n tan kaakiri.

“Ọrọ mi n lọ kaakiri, awọn aṣa mi n tan kaakiri, irin ati igbesẹ mi n tan kaakiri, bẹẹ ni imura mi n tan kaakiri.

“Lọdun to kọja, mo jẹ olorin to ṣẹṣẹ n dide bọ, mo tun n dide bọ lọdun yii. Mo ma maa dide lojoojumọ naa ni.

“Ojoojumọ ni ogo mi ma maa tan sii. Fẹla tuntun. Gbogbo ọdun ni ọdun temi.”