Ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ sọ àgádágodo sí ẹnu ọ̀nà àbáwọlé ṣọ́ọ̀ṣì,ìdí rèé

Aworan Gomina Seyi Makinde

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde/Facebook

Ijọba ipinlẹ Ọyọ labẹ iṣakoso Gomina Ṣeyi Makinde ti kede wi pe awọn ti ti ṣọọṣi kan, Christ Life Church to wa lagbegbe Golden Estate, Oluyọle, ijọba ibilẹ Guusu-Iwọ-Oorun Ibadan pa.

Kọmiṣanna fọrọ eto ayika ati agbegbe, Abdulmojeed Mogbọnjubọla lo fi iroyin yii lede l’ọjọ Ẹti niluu Ibadan.

Mogbọnjubọla sọ pe awọn ara adugbo ti ṣọọṣi ọhun wa ni wọn kọwe ẹsun si ijọba nipa ariwo ti awọn alakoso ati ọmọ ijọ naa n pa ni gbogbo igba.

Ile ijọsin keti ikun si ikilọ ka to pada ti ṣọọṣi wọn pa

O ni gẹgẹ bi ijọba, awọn gbe igbesẹ lati ran awọn aṣoju lọ sibẹ lati ṣe iwadii nipa otitọ, to si ni awọn aṣoju ṣe fọnran fidio to ṣafihan bi ṣọọṣi naa ṣe n fi ariwo di awọn eeyan lọwọ.

Bakan naa lo fi kun ọrọ rẹ pe awọn ti kọ iwe si awọn alakoso ṣọọṣi yii nipa iwe ẹsun ti wọn ri gba nipa wọn.

Mogbọnjubọla tẹsiwaju pe yatọ si pe awọn kọ iwe si awọn alakoso ṣọọṣi naa, o l’awọn tun pe awọn agbaagba adugbo naa pẹlu awọn alakoso ṣọọṣi yii papọ lati ba wọn sọrọ nipa atunṣe.

Ju gbogbo rẹ lọ, Mogbọnjubọla sọ pe awọn alakoso naa kọ eti ikun si gbogbo ẹbẹ ati arọwa ti ijọba pa fun wọn, ti wọn si tẹsiwaju lati maa fi ariwo di awọn araalu lọwọ.

Kọmiṣanna naa ni awọn ko ni igbesẹ miran lati gbe ju ki wọn ti ṣọọṣi naa pa niwọn igba ti awọn alakoso ko ṣetan lati dẹkun fifi ariwo ijọsin di awọn araalu lọwọ.

O ni ẹsun ti wọn fi kan ṣọọṣi ọhun tako iwe ofin ati ilana to de ayika ati agbegbe ti ọdun 2023, iyẹn Extant Environmental Regulations ni abala kejidinlọgọta, ipin keji.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ninu ọrọ rẹ, Mogbọnjubọla ni “Ko tun si ohun ti ijọba tun le ṣe mọ ju ki wọn ti ṣọọṣi yii pa lati le dẹkun wahala to ṣeeṣe ko waye nitori ariwo ti wọn n pa di araadugbo leti.

“Ikọ ti a ran lọ lati ṣe iwadii ka ohun ṣọọṣi naa silẹ lasiko ijọsin ni ọpọ igba, eyi si fihan pe lootọ ni ẹsun ti wọn fi kan ile ijọsin naa ri. Lati ori orin titi de awọn ẹsin miran ti wọn n ṣe, ariwo ni.''

“A pe ipade lati yanju aawọ yii laarin ara adugbo ati awọn alakoso ijọ l'Ọjọ Kẹsan, oṣu Kọkanla, ọdun 2023, nibi ti awọn alakoso yii ti kọ lati tọwọ bọwe adehun.''

“Wọn lawọn nilo lati gba aṣẹ lọwọ awọn alakoso olu ileeṣẹ ijọ wọn ko to di pe wọn tọwọ bọwe adehun kankan, ati pe awọn yoo jabọ lọjọ kẹrin, oṣu Kejila, ọdun 2023.

Ile ijọsin naa ko ti fesi yala loju opo ayelujara tabi ninu atẹjade kankan lati sọ ero wọn lori igbesẹ ijọba yi.

Ọrọ ariwo jẹ ohun fakinfa laarin awọn araalu ati awọn ile ijọsin ni paapa nibi ti ile ijọsin naa ba sunmọ tabi to wa laarin ile igbe.

Botilẹ jẹ wi pe awọn ẹka ijọba to n mojuto ariwo layika maa n gbiyanju lati pẹtu saawọ to ba niṣe pẹlu ariwo pipa, ọpọ ni kii ka ọrọ yi kun ti wọn a si tun tẹsiwaju lati maa fa inira fraalu pẹlu ijọsin wọn.

Ati ẹlẹsin musulumi ati Kristẹni ni aje ọrọ yi ṣẹ mọ lori.