Wo iye tí àjọ NAHCON kéde pé àwọn tó fẹ́ lọ fún Hajj 2024 yóò san

Aworan awọn arinrinajo Hajj

Oríṣun àwòrán, @NIGERIAJJCOM

Ajọ to n ṣe amojuto irinajo Hajj ni Naijiria, NAHCON ti kede síta iye owo ti awọn to ba fẹ irin irinajo lọ sí Hajj ọdun 2024 yoo san.

NAHCON ni milọnu marun un din ni ọgọrun un (4.9m) ni awọn eeyan to ba fẹ irin irinajo Hajj yoo san.

Saaju ninu oṣu kẹwaa ni ọdun 2023 ni NAHCON ti kọkọ kede iye owo irinajo naa, eyi to jẹ 4.5 milọnu naira sugbọn wọn jẹ ko di mimọ laipẹ yii pe bi kudiẹ kudiẹ se ba owo dọla si owo naira lasiko irinajo ti jẹ ki owo naa le si nipa ti iye ti owo ile, owo ọkọ, owo oúnjẹ ati awọn nnkan mii yoo jẹ.

Ninu atẹjade tí Agbẹnusọ ajọ naa, Fatima Usara fi lede fun awọn akọroyin, o ni ajọ NAHCON gbiyanju lati jẹ ki owo irinajo naa jẹ 4.5m sugbọn wọn ní lati ṣe atunṣe si iye owo naa lẹyin ti owo dọla gbẹnu soke.

Usara fikun pe alaga ajọ NAHCON, Jalal Arabi ti ṣe dinadura iye owo pẹlu awọn eeyan ni orile-ede Saudi lati mu adikun ba iye owo ti wọn kọkọ gbe kalẹ, eyi to jẹ milọnu mẹfa naira.

"Bẹẹ ba gbagbe, alaga ajọ to n ṣe amojuto irinajo Hajj ni Naijiria, Malam Jalal Ahmad Arabi ti kọkọ kede iye owo irinajo Hajj 2024 oe yoo jẹ 4.5m sugbọn ọrọ yí pada nigba ti kudiẹkudiẹ de ba owo Naira ninu ọsẹ to kọja.

"Ohun ba ni lọkan jẹ pẹlu bi kudiẹkudiẹ ba owo dọla si owo Naira lo fa atunṣe si iye owo irinajo naa.”

Ajọ NAHCON wa fi da awọn ọmọ Naijiria loju pe awọn ko ni yabara kuro ni igbiyanju wọn lati ri pe awọn to n irin ajo naa se aseyọri ninu irinajo lai wo bi kudiẹkudiẹ owo dọla eyi to n se ọpọlọpọ akoba.