Lẹ́tà Oluwo sí Ààrẹ Tinubu lórí ètò ààbò Nàìjíríà tó mẹ́hẹ: kókó pàtàkì mẹ́rin réè nínú rẹ̀

Aworan aarẹ Tinubu ati Oluwo ilu Iwo

Oluwo ilu Iwo Oba Adewale Akanbi ti kesi aarẹ Bola Ahmed Tinuu lati foju oro han awọn ajinigbe nipa agbekalẹ ofin ti yoo faaye gba pipa awọn ti ọwọ ofin ba tẹ to n ji eeyan gbe.

Kabiyesi ilẹ Yoruba yi sọrọ yi di mimọ ninu lẹta kan to fi ṣọwọ si aarẹ nibi to ti mẹnu ba ọrọ to niṣe pẹlu eto aabo Naijiria to mẹhẹ.

Oba Abdulrasheed ni ‘’Ẹ jẹ ki meji, mẹta tabi mẹrin ninu awọn ti ọwọ ba tẹ fi iku ṣe ifa jẹ nigba naa laa to le ri imu mi daada.’’

Kabiyesi sọ pe iyipada ọna ti ijọba ṣe n koju ọrọ aabo ni Naijiria nilo lasiko yi.

Lẹnu ọjọ mẹta yii ni Naijiria ọrọ aabo ti peleke debi pe awọn ajinigbe ati ọdaran ko fi mọ ni ti araalu nikan mọ.

Bi wọn ṣe n tọ awọn olowo lọ ni wọn n ṣeku pa awọn oriade paapa ni ilẹ Yoruba.

O kere tan awọn Kabiyesi mẹta ni ajinigbe ti ṣeku pa laarin ọjọ mẹwaa sẹyin ni ipinlẹ Ekiti ati Kwara.

Lẹta ti Kabiyesi Oluwo ilu Iwo kọ yi tun mẹnu ba awọn nkan mii lọna ati wa ojutu si aabo to mẹhẹ ni Naijiria.

Diẹ ree ninu wọn:

A ni lati faaye gba ọlọpaa abẹle

Ninu lẹta rẹ si aarẹ Tinubu Tela Kini sọ pe ṣiṣe igbalaye fun ọlọpaa abẹle yoo jẹ ọna kan gbogi lati le fi dẹkun ipenija aabo ti Naijiria n koju.

Kabiyesi ni wọn ni lati ṣeto agbekalẹ awọn ọlọpaa adugbo yi ki eto aabo baa le gunrege.

‘’A ko le fagbara fun eto aabo wa lae ṣe pe tolori tẹlẹmu la ko jọ sinu rẹ.

Mo ni igbagbọ orileede ti yoo de ibi giga.O ku si ọwọ wa, gbogbo wa’’

Ipese eto ẹkọ fawọn Fulani

Kabiyesi Oluwo sọ ninu ọrọ rẹ pe agbegbe toun jẹ ọba le lori wa lara ibi tawọn Fulani pọ si julọ.

Labẹ eyi o ni oun mọ pataki ṣiṣe eto ẹkọ fawọn ọmọ Fulani ki wọn baa le dagba jẹ eeyan nla lawujọ.

O ni bi ijọba ko ba ṣe iranwọ eto ẹkọ fawọn ọmọ Fulani, awọn alaburu ninu wọn ko ni jawọ ninu iwa ijingbe tawọn eeyan n fura si wi pe awọn lo wa nidi rẹ.

Lilo imọ ẹrọ tẹkinọlọji lati sẹto aabo

Nipa eto aabo, Oluwo mu aba wa pe ki awọn alaṣẹ ri pe imọ tẹkinọlọji jẹ nkan ti wọn ṣamulo nipa ipese aabo.

O ni eleyi le waye nipa sisọ kaadi idanimọ di nkan to di dandan ki awọn eleto aabo baa le beere rẹ loore koore to ba di dandan.

O ni pẹlu kaadi idanimọ ẹlẹrọ kọmputa yi, awọn alaṣẹ to wa nidi aabo yoo le tọ pinpin afurasi kankan ti wọn ba gburo lawujọ.